Sleeping with Dogs: Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Naijiria ń wá àwọn obìnrin tó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ajá, àtàwọn tó ni ajá náà

Oríṣun àwòrán, @JPorkchop
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria tun ti sọ ohun tuntun mii nipa awọn eeyan kan ti wọn sọ pe awọn n ba aja ni ibalopọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa ni Naijiria, Muyiwa Adejobi sọ fun awọn akọroyin niluu Abuja pe yatọ si awọn to n ba aja lopọ, awọn yoo tun fi ṣikun ofin mu awọn to ni aja to n ba awọn eeyan naa lopọ.
O ni "A oo ṣe ọfintoto awọn ti aja wọn n ba eeyan lopọ, wọn si jiya to tọ labẹ ofin."
- Ọmọ orílẹ̀èdè Lebanon tó gba 'One way' l'Eko fi ọkọ̀ fọ́ ẹsẹ̀ obìrin kan
- Gueterres, Ìrìn asán ni ìrìn rẹ, tó o bá bẹ àwọn ibi tí Fulani ti n ṣe ọṣẹ́ ní Nàìjíríà- Akintoye
- Ọlọ́run mi ló ní kí n bèèrè fún N310,000 lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ mi láti kó wọn lọ sí ọ̀run - Pásítọ̀ Noah Abraham
- Fayemi ní òun ṣetán láti gbéná wojú àwọn alágbára tí kò jẹ́ kí Nàìjíríà tẹ̀síwájú
- Àwọn òníṣòwọ àti ìjọba yóò má a san owó kí wọn ó tó le lo Twitter - Elon Musk
- Bí wọ́n ṣe pa Sójà méjì tó ń lọ fún ìgbéyàwó ara wọn ní ìlú
- Leke Adeboye àti ọ̀pọ̀ ọmọ ìjọ RCCG ń ṣèrántí ikú Dare Adeboye lẹ́yìn ọdún kan
- Ìgbà mélòó ló yẹ ko máa pàrọ̀ ‘bedsheet’ rẹ?
- Amotekun Ondo fi ṣìkùn òfin mú afurasí 37 lórí ẹ̀esùn ìjínigbé, ìdigunjalè àtàwọn ẹ̀sùn míì
- Àwọn afurasí apààyàn pa 'Atiku' ní Ibarapa!
"Awọn to aja to n ba obinrin lopọ ni lati wa sọ tẹnu wọn ni agọ wa."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
"Biba ẹranko ni ibalopọ jẹ ẹṣẹ to ni ijiya labẹ ofin, a ko si fọwọ si irufẹ iwa bẹẹ."
"Laipẹ, lai jina, a oo fi ṣikun ofin mu awọn obinrin atawọn mii to n ba aja tabi awọn ẹranko mii lopọ."
Eremọde lasan ni, mi o ba aja lopọ
Ti ẹ ko ba gbagbẹ, ṣaaju ni fidio kan ti kọkọ gbode loju opo Twitter, nibi ti obinrin kan ti n ba aja lopọ, eyii to mu ọpọ eeyan maa sọrọ nipa iṣẹlẹ naa pẹlu ami #doggy lori ikanni ọhun.
Lẹyin ọjọ bii meji si asiko naa ni ọdọbinrin kan sọ loju opo TikTck rẹ pe lootọ ni oun ba aja lopọ amọ kii ṣe nnkan bababara nitori aye n ṣeruẹ.
Amọ lẹyin wakati diẹ ti fidio naa milẹ titi ni ọdọbinrin naa tun yi ohun pada, to si sọ pe oun ko ba aja lopọ, ati pe oun ko fọwọ si irufẹ iwa bẹẹ.
O ni eremọde lasan ni oun fi ọrọ naa ṣe, koda, o ni ọrẹkunrin oun ti kọ oun silẹ nitori apara ọhun.
Lẹyin naa ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn n wa ọdọbirin naa lati wa sọ tẹnu rẹ, yala apara lasan lo n ṣe tabi bẹẹ kọ.
Wayi o, ọlọpaa ti wa ni ati obirin to n ba aja lopọ ati ẹni to ni aja naa ni wọn yoo jọ foju wina ofin bayii.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
À ń wá àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ajá, ẹ kàn sí wa tí ẹ bá mọ̀ wọ́n - ọlọ́pàá Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria ti ni ẹnikẹni to ba mọ awọn obinrin to n ba aja lopọ, ki wọn kan si awọn.
Eyi ko ṣẹyin awuyewuye to ṣuyọ lẹyin fidio to n ja ranyin lori ayelujara nibi ti awọn obinrin ti n ba aja lopọ.
Bi o tilẹ jẹpe ọkan lara awọn obinrin to ni oun ba aja sun, tun jade pe ọrọ ko ri bẹẹ mọ nitori ere ni oun ṣe.
Amọ, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Muyiwa Adejobi ni iru ihuwasi yii ko tọ ni awujọ eniyan.
''Iwa ti ko tọ si awọn ọmọ eniyan ni awọn obinrin yin n wu, ti wọn si n fi si ori ẹrọ ayelujara''.
''Nitori naa a n rọ awọn eniyan lati fi iroyin lede ti wọn ba mọ nipa awọn obinrin yii''.
''A gbọdọ wa wọn jade, ki wọn si fi oju wina ofin.''
Bakan naa ni awọn eniyan n fi ero wọn han lori ẹrọ ayelujara lori iṣẹlẹ yii.
Oogun owo ni wọn n fi awọn obinrin to ba aja sun ṣe - Kemi Olounloyo
Ọkan lara awọn to fi ero rẹ han ni Kemi Olounloyo to ni awọn obinrin ti wọn n ba aja lọpọ ko mo ̣wi pe awọn ọlọla wọn yii n lọ wọn fun oogun owo.
Ninu atẹjade loju opo Facebook, ni kii ṣe fun fiimu ibalopọ ni awọn eniyan ṣe n ba aja lọpọ, amọ o ni awọn olowo ati ọlọla yii ma n fun wọn ni miliọnu meji Naira lati ba aja lo fun oogun owo.
''Lẹyin naa Wọn ma pa aja yii, ti eyi yoo si jẹ ki wọn ni owo si ju tẹlẹ lọ''
''Bakan naa ni awọn obinrin yoo tun ko aimọ ara wọn ba awọn ọkunrin yii.''
''Praise Aniekwe ni yii ti ọpọlọpọ ọkunrin ko ni ilọsiwaju mo nitori awọn ti wọn ti ba lọpọ.''
''O parọwa si awọn ọkunrin lati ṣọ ara wọn ni asiko yii, ki wọn si jẹ ki nkan ti wọn ni tẹ wọn lọrun.''
Grace Taigbenu ni aye yi ti wọ si ẹgbẹ kan o nitori o buru jai pe iru nkan bayii n waye lorilẹede Naijiria.


















