Ilana Ọmọ Odua: Gueterres, Ìrìn asán ni ìrìn rẹ, tó o bá bẹ àwọn ibi tí Fulani ti n ṣe ọṣẹ́ ní Nàìjíríà

Olori ẹgbẹ́ to n ja fun idasilẹ orile-ede Oduduwa, Ọjọgbọn Banji Akintoye, ti kesi akọwe àjọ United Nations, Antonio Gueterres, lati la oju rẹ silẹ, ko ri awọn nkan to yẹ ko ri lẹ́nu abẹwo to wa ṣe ni Naijiria.
Ọjọ Iṣẹgun ni akọwe àjọ isọkan agbaye, UN, gunlẹ si Naijiria, to si ti bẹ ipinlẹ Borno wo. Ninu atẹjade to fi sita funra rẹ, Ọjọgbọn Akintoye sọ pe Ọgbẹni Gueterres gbọdọ joyè oju lalakan fi n sọri lasiko abẹwo naa dipo ko maa wo nkan ti isejọba Aarẹ Muhammadu Buhari ba fi han.
- Akọ̀wé Àjọ Iṣọ̀kan, Antonio Guterres ṣàbẹ̀wò sí Naijiria lórí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ̀
- Ọlọ́run mi ló ní kí n bèèrè fún N310,000 lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ mi láti kó wọn lọ sí ọ̀run - Pásítọ̀ Noah Abraham
- Bí wọ́n ṣe pa Sójà méjì tó ń lọ fún ìgbéyàwó ara wọn ní ìlú
- Amotekun Ondo fi ṣìkùn òfin mú afurasí 37 lórí ẹ̀esùn ìjínigbé, ìdigunjalè àtàwọn ẹ̀sùn míì
O ni o daju pe "isejọba Buhari ti bẹ̀rẹ̀ si ni parọ fun akọwe àjọ UN ọhun, nipa didena pe ko ṣe ipade pẹlu awọn eeyan to yẹ, ati lati de ibi to yẹ ko de, ko le ba a ri okodoro ibi ti nkan de duro ni Naijiria.
" Wọn ti n tàn-án ko ma ba ri awọn isẹ ibi ti isejọba Buhari n ṣe.''
''Eyi lo mu ki wọn o ṣe atunto pajawiri si awọn nkan to yẹ ki Gueterres ṣe, ki asiri ipaniyan, awọn Fulani agbesunmọmi, ati ajinigbe, ti isejọba Buhari n fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ wọn, ma ba tú si lọwọ."
Àwọn iwa to ni wọn n hu si àwọn eniyan ẹkùn aarin Middle Belt ati Gusu Naijiria.
O ni idi rèé ti awọn eeyan ẹ̀yà Yoruba fi pinnu pe àwọn fẹ kuro ni Naijiria, nigba ti ìjọba ko gbọ igbe ati ẹkùn wọn fun iranlọwọ.
Ọjọgbọn Banji Akintoye tun lo anfaani naa lati pe akiyesi Ọgbẹni Gueterres si bi awọn ṣe ti fi orúkọ silẹ lọdọ àjọ UNPO, ati igbesẹ wọn lati gba ara wọn kuro ni orile-ede Naijiria, lọ́nà to ba ofin mu.
"Kii ṣe nkan to pamọ fun ọ pe ojúṣe àjọ UN ni, lati ran wa lọwọ lori igbesẹ wa. O ti su wa pe ki wọn o ma a ṣe wa bi ẹrú, ati ẹni ti ko ja mọ nkankan, nilẹ baba wa."

"O ṣe pataki pe ki àjọ UN tete gbe igbesẹ, ni bayii ti akoko ṣi wa fun idunadura alaafia."
O wa a rọ pe ko ṣe ipade pẹ̀lú awọn eeyan bi òun, olori ẹgbẹ́ Afenifere, Ayo Adebanjo; Bishop Matthew Kukah, Gomina Samuel Ortom ti ipinlẹ Benue, ati awọn adari ẹgbẹ́ to n ja fun ominira nilẹ Igbo.
" Olu Falae nipinlẹ Ondo to ti lugbadi ikọlu ri lọwọ awọn Fulani darandaran, Reuben Fasoranti, ti awọn afurasi Fulani darandaran pa ọmọ rẹ obinrin."
O ni o ṣe koko pe ko bẹ ilẹ̀ Yoruba wo, to fi mọ Middle Belt, ipinlẹ Taraba, Niger, Ogun, Oyo, ati Kaduna, nibi ti ikọlu ti n waye leralera, lati fi oju ara rẹ ri nkan to n ṣẹlẹ̀.














