APC 2023 Fayemi: Ka nípa ohun tí Fayemi lóun yóò ṣe fawọn tí kò jẹ́ kí Nàìjíríà tẹ́síwájú

Aworan Kayode Fayemi

Oríṣun àwòrán, Facebook/Kayode Fayemi

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, Káyọ̀dé Fayẹmi ni oun ṣetán láti gbéná woju àwọn alágbára ńlá tí ó fẹ́ dènà ìlọsíwájú orílẹ̀-ede Nàìjíríà bi òun bá di Ààrẹ lodun 2023.

Fayemi, tó jẹ́ alága ẹgbẹ àwọn gómìnà ní Nàìjíríà ti dára pò mọ àwọn oludije méje tí ó kede erongba láti dije dupo Ààrẹ ni odun to ń bọ̀."Mo ṣetán láti rí pé àwọn alágbára tí wọ́n lè fe déna ìlọsíwájú orilẹ-ede Naijiria kó ní laanfani lati ṣe bẹ tí àwọn ọmọ Naijiria bá gbemi de ipo aarẹ."

"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó pé ará wọn ní alágbára ló ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjàmbá fún àwọn ọdọ tí a sì gbọ́dọ̀ rí pé iru eyi kò wáyé mọ"

Kayode Fayemi

Oríṣun àwòrán, Kayode Fayemi

Fayemi wa so ni ipari pe idibo abele ni o ba ofin ẹgbẹ oselu All Progressive Congress,APC mu.

O fesi yi ni idahun si ibeere pe irufẹ ilana eto idibo lati yan oludije lo nifẹ si lati fi yan ẹni ti yoo dije labẹ asia ẹgbẹ.

Fayemi, sọ pe eto ìdìbò abẹle ẹgbẹ oselu APC gbọ́dọ̀ wáyé ní ìlànà òfin ẹgbẹ oselu náà.

Tori naa o ni oun yoo faramọ ti wọn ba j ki awọn ọmọ ẹgbẹ dibo yan ẹniti yoo ṣoju ẹgbẹ naa ninuidibo to n bọ lọna."Tí ẹ ba wo ìwé òfin àti ìlànà ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ọna méjì ni a lè fi yan aṣojú ẹgbẹ ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ mu ọkàn láti yan ọmọ òye tí a sójú wá pẹlu eto ìdìbò abele."

Aworan ayẹyẹ ti Fayemi ti kede erongba rẹ lati du ipo aarẹ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Facebook/Kayode Fayemi

Kayode Fayemi ṣetán láti kéde èróngbà rẹ̀ láti díje du ipò Ààrẹ

Gomina ipinlẹ Ekiti, to tun jẹ alaga ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria, Kayode Fayemi yoo kede erongba rẹ lati dije du ipo Aarẹ Naijiria ninu eto idibo sipo Aarẹ ọdun to n bọ.

Agbẹnusọ Fayemi, Yinka Oyebode lo fi ọrọ na lede ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Iṣẹgun.

Gẹgẹ bi ohun to sọ, oni Ọjọru ni Fayemi yoo sọrọ soke lẹyin ti ọpọ eeyan ti n woye boya yoo dije du ipo Aarẹ Naijiria tabi ko ni ṣe bẹẹ.

Oyebode sọ pe Fayemi ti ba Aarẹ Muhammadu Buhari sọrọ, to fi mọ awọn ọba alade atawọn agba ọjẹ ninu oṣelu sọrọ lori erongba rẹ lati du ipo Aarẹ lọdun 2023.

Atẹjade naa ni "Ọmọwe Fayemi ti ba awọn oloṣelu atawọn ori ade jiroro, to fi mọ awọn gomina akẹgbẹ rẹ, paapaa awọn to wa ninu ẹgbẹ oṣelu APC."

"Lọwọ yii, iye awọn to ti ba sọrọ ko din ni ogun ninu awọn gomina APC mejilelogun, yoo si tun maa ba awọn eeyan mii sọrọ titi di igba ti ẹgbẹ naa yoo ṣe eto idibo abẹnu wọn ninu oṣu yii."

Alaga awọn gomina naa sọ pe ipade oun pẹlu awọn lọbalọba atawọn oloṣelu ti jẹ ki oun mọ bi oun yoo ṣe tan iṣoro Naijiria.

Àkọlé fídíò, Ó gbé owó fún mi, ó tún ra fóònù ńlá fún mi - Bàbá Onílù Ibadan sọ bó ṣe pàde Àgùnbánirọ̀ tó dáa lọ́lá

Ta ni Kayode Fayemi

Wọn bi Kayode Fayemi lọjọ kẹsan an, oṣu keji, ọdun 1965.

Oun ni alaga igbimọ apapọ ẹgbẹ oṣelu APC to gbe Muhammadu Buhari jade gẹgẹ bii oludije sipe Aarẹ ninu ẹgbẹ naa ninu eto idibo ọdun 2015.

Kayode Fayemi

Oríṣun àwòrán, Kayode Fayemi

Fayemi ni gomina ipinlẹ Ekiti lati ọdun 2010 si 2014 ko to tun pada wa lọdun 2018.

O ṣiṣẹ gẹgẹ bii minisita iwakusa lati ọdun 2015 si 2018.

Àkọlé fídíò, Babalawo, Ọ̀pẹ̀lẹ̀ ni wọ́n fi ń yan Ọba fún wa, kí ló dé tẹ́ẹ fẹ́ wo owó yan Soun fún wa? - Ọmọ ìdílé òyè l'Ogbomoso

Awọn ti Fayemi yoo maa figa-gbaga pẹlu

Ni kete ti Fayemi ba ti kede erongba rẹ lati dije du ipo Aarẹ, yoo ni lati figa-gbaga pẹlu igbakeji Aarẹ, Yemi Osinbajo, minisita feto irinna, Rotimi Amaechi, atawọn eeyan mii bii Chris Ngige, Dave Umahi, Yahaya Bello, Rochas Okorocha, Orji Kalu, ati gomina ipinlẹ ogun tẹlẹ, Ibikunle Amosun, ti gbogbo wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Fayemi yoo tun maa koju awọn eeyan mii ninu ẹgbẹ oṣelu PDP bii gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayodele Fayose, atawọn eeyan mii bii Peter Obi, Dele Momodu, Pius Anyim, Bukola Saraki, Atiku Abubakar, Aminu Tambuwal, ati Bala Mohammed.

Àkọlé fídíò, Idiroko border open:Àwọn Egun ló yẹ k'Ọ́lọ́pàá máà gba owó ibodè lọ́wọ́ wọn àmọ́...