bedsheet and your health: Ẹ wo ewu tó wà nínú lílo ‘’bedsheet’’ fún ìgbà pípẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ẹlomiran ro wipe eleyii kii ṣe ohun ti o yẹ ki a maa sọ ni gbangba amọ igba melo ni o ma n fọ aṣọ ibusun rẹ?
Iwadi ti fihan wipe ọpọ eniyan ni Ilẹ Gẹẹsi ni ko panupọ tabi ni adehun lori ọrọ yii.
Ọpọlọpọ awọn ọdọkunrin ti ko tii ni iyawo sọ wipe igba kan laarin oṣu mẹrin ni awọn ma n fọ aṣọ ibusun wọn.
Awọn miran tilẹ sọ wipe awọn kii ranti rara lati fọ ọ, amọ onimọ nipa ọrọ ilera ati ihuwasi eniyan, Lindsay Browning sọ fun BBC Radio 1 Newsbeat pe eyi ko bojumu rara.
Awọn obinrin tilẹ ma n fọ aṣọ bẹẹdi wọn loorekoore ti ida mejilelọgọta ninu wọn si n fọ ọ lọsẹ meji meji.
Awọn lọkọlaya ni ẹẹkan laarin ọsẹ mẹta ni awọn maa n fọ aṣọ ori ibusun wọn.
Kini idi ti a fi gbọdọ paarọ aṣọ ibusun wa loorekoore?
Dokita Browning ni ki a ma fa ọrọ gun,ọsọọsẹ ni o yẹ ki a maa fọ aṣọ ibusun wa, abi o pe tan ẹẹkan laarin ọsẹ meji.
Idi ni wipe imọtoto ṣe koko paapaa nitori ilaagun to n bọ lara eniyan.
Eni ti o ba sun ninu ooru ni yio mọ bi o ti n ri, nitori ilaagun ara ti o ma n mu ori ibusun run, ti o si ma n di oju iho aṣọ ibusun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Onimọ nipa eto ilera ni a gbọdọ jẹ ki atẹgun fẹ si ara daadaa ni igba ti a ba n sun ki oorun naa le wọ ara.
Yatọ si ilaagun,a tun le wo bi sẹẹli ara ti ko dara ṣe n jade ni ara ni asiko ti eniyan ba n sun.
Ibusun ti o ba dọti yoo di oju ara "ti o ko ba fọ aṣọ ibusun rẹ daadaa,awọn sẹẹli ara ti o ti bajẹ yoo ma parapọ si ori bẹẹdi"
Eleyi si tun mọ si wi pe awọn kokoro kekeeke ti o fimọ idun yoo ma wọ inu ara, ti o si le fa kokoro aifojuri ati aisan si agọ ara.
Kini igba ati akoko oju ọjọ niise pẹlu ibusun rẹ?
Ni asiko otutu, o le fọ aṣọ ibusun rẹ ni ẹẹkan laarin ọṣẹ mẹji, sugbọn ẹẹkan laarin ọsẹ lo dara julọ.
Ti o ba ti kọja ọsẹ meji, ohun wa wahala si agọ ara rẹ niyẹn.
Bi o tilẹ jẹ wipe eniyan ki ilaagun pupọ lasiko òjò, ara si ma n ṣi si ori ibusun.
Asiko ooru lo buru ju nitori pe awọn kokoro ma n pọ ni asiko yii.
Nitori naa o ṣe pataki ki o fọ aṣọ ibusun rẹ ni orekoore fun imọtoto ara.
Jẹ ki ibi ibusun rẹ jẹ ibi iyasọtọ nitori ti o ba mọ,inu rẹ yoo dun lati sun si ori rẹ,sugbọn bi o ba dọti, o ṣeeṣe ki o fa ailera, o si le mu ki eniyan ma le e sun daadaa,eleyii ti awọn oloyinbo n pe ni 'insomnia.'
















