Ọmọ ọdún mẹ́rin tó wa ọkọ̀ ìyá rẹ̀, kọlu ọkọ̀ méjì míì

Oríṣun àwòrán, police_utrechtnorth
Ọmọ ọdun mẹrin kan ti fi ori ọkọ iya rẹ sọ ọkọ meji mii lẹyin to wa ọkọ naa lorilẹ-ede Netherlands.
Awọn ọlọpaa ni aringbungbun Utrecht sọ pe ọmọ naa sa kuro nibi ti ijamba naa ti ṣẹlẹ pẹlu aṣọ awọsun rẹ, amọ ko farapa.
Awọn eeyan to wa lagbegbe naa lo ke si ileeṣẹ ọlọpaa lẹyin ti wọn ri ọmọde naa to n wa ọkọ.
- Kìnìhún nìkan kọ́ ló burú, àwọn ajá mẹ́wàá yìí náà kò fararọ!
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi ṣìkún òfin mú "Paracetamol" ní ìpínlẹ̀ Ogun
- Dídi ọlọ́là nínú eré Tíátà kò jọ ọ́ fún àwa kan, ìdí rèé - Kunle Afod
- Èèyàn méjì ti kú, ọ̀pọ̀ àwọn míì dèrò ilé ìwòsàn níbi ilé alájà mẹ́ta tó dàwó ní Ebute-meta
- Ìrọ̀rùn dé l'Edo- A óò bẹ̀rẹ̀ sí san 40,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù lóṣù yìí-Obaseki
- Owó ńlá ti fẹ́ ṣe mí léṣe ní London o! Ẹ wá wo bí mo ṣe ń jayé orí mi bíi skódà - Portable
- Òṣìṣẹ́ ìjọba pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn ọjọ díẹ̀ tó gba iṣẹ́
- Omoyele Sowore gúnlẹ̀ sí Ondo láti lọ gba ìmọ̀ràn
- Russia na ìka àlébù sí Ukraine,o ní àwọn ló n ṣekú pa aráàlú wọn ní Kherson
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọmọ naa tabi ẹnikẹni ko farapa nibi ijamba ọhun.
Gẹgẹ bii atẹjade ileeṣẹ ọlọpaa, ọmọ naa ji laarọ ọjọ kutu, o si mu kọkọrọ ọkọ iya rẹ lasiko ti baba rẹ ko sinle lati wa ọkọ ọhun.
Nigba ti ọlọpaa de agbegbe ibi ti ijamba naa ti waye, wọn ni ayẹwo awọn fi han lootọ ọkọ iya ọmọ naa ni.
Awọn ọlọpaa fun ọmọ naa ni suiti ni agọ wọn, ki wọn to ke si iya rẹ lati wa mu pada sile.
Amọ nigba ti iya rẹ de agọ ọlọpaa ni wọn awọn mejeji lọ si ibi ti ijamba naa ti ṣẹle, ti obinrin naa si ni ki ọmọ ọhun ṣalaye bo ṣe wa ọkọ naa fun oun.
Ọlọpa ni loju wọn nibẹ ni ọmọ ọhun ṣe wọ inu ọkọ naa, to ṣina si, to si tun wa.
Ẹwẹ, awọn ọlọpaa ni Netherlands ti wa rọ awọn obin lati maa fi kọkọrọ ọkọ wọn pamọ si ibi ti oju awọn ọmọ wọn ko ti ni to lọna ati dẹkun irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.
















