Minimum wage: Obaseki kéde sísan 40,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù láti ìparí oṣù yìí

Gomina Obaseki nibi ayẹyẹ ayajọ oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook/Governor Godwin Obaseki

Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ti sọ pe awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa yoo bẹrẹ si ni gba ẹgbẹrun lọna ogoji Naira lowo to kere ju fun awọn oṣiṣẹ lati ipari oṣu yii.

Obaseki fi ọrọ naa lede nibi ayẹyẹ ayajọ ọjọ awọn oṣiṣẹ ti ọdun 2022 to waye ni olu ilu ipinlẹ naa Benin City.

Gomina Obaseki ṣalaye pe, ereedi ti ijọba rẹ ṣe fẹ san owo naa ni lati ṣe iwuri fun awọn oṣiṣẹ, paapaa julọ awọn lasiko yi ti nkan gbowo lori lọja.

Aworan awọn oṣiṣẹ Naijiria nibi iwọde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Governor Godwin Obaseki

Pẹlu ikede yi, owo oṣu to kere julọ ti Obaseki fi lelẹ yi ni eleyi ti o pọju lọ tawọn ijọba ipinlẹ n san ni Naijiria.

Bi a foju wo iye ti ijọba apapọ naa n san, o fẹ ẹ jọ pe owo yi ju ti ijọba apapọ Naijiria naa lọ.

Ṣaaju asiko yi, ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira ni owo oṣu to kere julọ ti ipinlẹ yi n san.

Ipinlẹ Eko labẹ akoso Gomina Babajide Sanwo-Olu lo n san owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ tii ṣe ẹgbẹrun marunlelọgbọn Naira.

Ọpọ awọn ipinlẹ ni Naijiria ni ko tilẹ san owo oṣu to kere julọ yi

toun ti pe wọn buwọlu adehun pẹlu ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ijọba apapọ lati san owo naa.

Ipenija owo ṣou yi jẹ nkan to n ba awọn oṣiṣẹ finra.

Naijriia nikan si kọ ni irufẹ aroye lori owo oṣu ti n waye.

Aworan awọn oṣiṣẹ Naijiria nibi iwọde

Oríṣun àwòrán, Nigeria Labour Congress HQ

Lọni tii ṣe ayajọ oṣiṣẹ aarẹ orileede Kenya Uhuru Kenyatta naa kede pe oun yoo bẹrẹ si san alekun ida mejila ninu ida ọgọrun gẹgẹ bi alekun owo oṣiṣ to kere julọ.

Awọn oṣiṣẹ to kede ọrọ yi fun ni o ṣee da ṣugbọn o kere si iye tawọn n beere nitori bi nkan ti ṣe wọn lọja.

Yatọ si Gomina Obaseki, a ko ti gbọ ki Gomina ipinlẹ Naijiria kankan kede alekun iye owo oṣu to kere julọ fawọn oṣiṣẹ wọn.