Soludo: Agbẹnusọ gómìnà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ léyìn tó gba iṣẹ́ ìjọba

Aworan Anatune

Oríṣun àwòrán, Facebook/AnambraGovt

Joe Anatune to jẹ agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Anambra, Chukwuma Soludo ti dagbere faye.

Anatune lo jẹ adari ẹka to n risi ọrọ iroyin nipa gomina naa saaju idibo sipọ rẹ ni ọdun to kọja.

Anatune lo dagbere fun aye ni Ọjọ Satide lẹyin ọjọ diẹ to ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ to ti pe ẹni ọdun mejilelọgọta.

Ọṣẹ kan ṣẹyin ni gomina Soludo yan an si ipo lẹyin to ṣiṣẹ takuntakun lasiko idibo to gbe gomina naa wọle.

Gomina Charles Soludo yan an gẹgẹ bi ọga agba ileeṣẹ ijọba to n risi ọrọ ipolongo ni ipinlẹ naa.

Ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ, gomina fi aidunnu rẹ han ati pe iroyin iku rẹ ba oun lojiji.

O ṣapejuwe Joe Anatune gẹgẹ bi ọkan gboogi lara awọn eniyan to duro ti oun, ti o si gbagbọ ninu ipe ọun pẹlu akitiyan lati ri pe oun ṣe aṣeyọri.

''Ifarajin Joe lasiko idibo naa kọja afẹnusọ, ti o si jẹ moriya fun mi.''

''Fun ọdun meji lo fi ko ajọ Soludo Promoters Forum jọ, ki o to wa fi ọrọ oṣelu lọ wọn paapaa idibo si ipo mi.''

''Ijọba ati gbogbo eniyan ipinlẹ Anambra lo n ṣe idaro rẹ, ti wọn yoo si mọ ni ara bi o ṣe papoda.''

Bakan naa lo ba iyawo ati mọlẹbi kẹdun iku naa ati ilu Awa nibi ti arakunrin naa ti ṣẹwa.