Polygamy: Ẹ wo pásítọ̀ tó fẹ́ omidan mẹ́rin lẹ́ẹ̀kàn náà! Ó ní kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Bíbéli mi ló sọ pé kí n fẹ́ ìyàwó omidan márùn ún, kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀- Pásítọ̀
Pasitọ kan lorilẹede Congo ti ṣe ohun ti ẹnikan ko ṣe ri, o fẹ iyawo mẹrin ni ẹẹkan naa, lẹyin to ti ni ẹyọkan si ilẹ tẹlẹ.
Pasitọ Zagabe Chiluza lati orilẹede Congo ni awọn eniyan n sọrọ nipa rẹ lori ayelujara lẹyin to ṣe iyawo alarede fun obinrin mẹrin lẹẹkan naa.
- Mo ti 'ùnfollow' ẹ lórí 'social media'; Ọlọ́run a ṣe idajọ fún ẹyin méjèèjì- Iyawo Yul-Edochie
- Ìgbẹ́jọ́ Ilànà Ọmọ oodua àti Náìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ nílé ẹjọ́ ní Ekiti
- Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló kú ikú àìtọ́jọ́ nítorí ẹnubodè tíjọba àpapọ̀ tì pa- Àwọn ènìyàn ìlú Idiroko tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ ọ̀rọ̀
- Wo ohun tí o kò mọ̀ nípa Morenikeji Lasisi, olórí ẹrú tó ti bá Aláàfin mẹ́ta ṣiṣẹ́
- Germany gbé ìgbésẹ̀ láti fi ọkọ̀ ogun sọwọ́ sí Ukraine láti kojú Russia
- Indonesia fòfin de títa epo pupa rẹ̀ sílẹ̀ òkèèrè, wo ipa tí yóò ní lára Naijiria àti Africa lápapọ̀
Pasitọ Chiluza lo kọkọ ni iyawo ẹyọkan ki o to wa pa ero rẹ da to si fẹ omidan ti wọn ko i tii ja abale rẹ mẹrin, pẹlu idaniloju pe inu Bibeli ni oun ti ri ero naa.
Pasitọ naa rọ awọn ọmọlẹyin Kristi lati ṣe bi oun, ki wọn si di alaya pupo nitori awọn omidan ti wọn ko i tii ja abale wọn ni awọn ọkunrin ni ile ijọsin oun ma n fẹ.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin AfriMax English ṣe gbe jade, pasitọ naa fi apẹrẹ han lati inu Bibeli to fihan pe kii ṣe ẹṣẹ fun awọn eniyan lati fẹ ju iyawo kan lọ.
Ni ọjọ igbeyawo rẹ ni pasitọ naa sọ wi pe 'Mo ti ni iyawo kan tẹlẹ amọ ma a fẹ awọn mẹrin yii loni, ti wọn yoo si darapọ mọ iyawo akọkọ to wa ni ile.''
O fikun un pe fifẹ iyawo pupo wa lati inu ẹsẹ Bibeli.
'Jacob ni iyawo pupọ to fi mọ Leah ati Rachel, Bilha ati zilpa... iyawo mẹrin fun ọkunrin kan.''
Kini iriri Zagabe?
Zagabe ni ọdun 1986 ni oun fi aye oun fun Jesu ti oun si sọ fun awọn alejo pe inu oun dun lati ni iyawo marun un.
Iroyin fikun un pe omidan ti ko mọ ọkunrin ri ni awọn omidan mẹrin ti pasitọ fẹ ni ẹẹkan naa.
- Ìgbẹ́jọ́ Ilànà Ọmọ oodua àti Náìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ nílé ẹjọ́ ní Ekiti
- Ọmọ Ọba Charles kàn sí BBC lórí àjọ̀dún ọdún 90 tí BBC bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìròyín, Oríadé sọ̀rọ̀ pé..
- Indonesia fòfin de títa epo pupa rẹ̀ sílẹ̀ òkèèrè, wo ipa tí yóò ní lára Naijiria àti Africa lápapọ̀
- Iléẹjọ́ sún ìdájọ́ Abba Kyari síwájú, ìgbà wo ni wọ́n n gbée lọ jẹ́jọ́ Hushpuppi ní America ní ọ̀pọ̀ ń béèrè
- Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ́ Ajé àti ọjọ́ Ìṣẹ́gun fún ìsinmi ọdún àti àyájọ́ ọjọ́ Òṣìṣẹ́
- Ohun tó yẹ kó mọ nípa ìyípadà òfin tó dé ijinigbe ní Nàìjíríà rèé
- Wo bí ètò Orò Ìje Oba Lamidi Adeyemi to wàjà ṣe lọ ní Oyo















