Idiroko Border Reopening: Àwọn èèyàn Idiroko ń fẹ́ kí iṣẹ́ tètè bẹ̀rẹ̀

Ìjọba àpapọ̀ kéde ṣíṣí ibodè mẹ́rin mìíràn, èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
Àwọn ènìyàn ìlú Idiroko ní ìjọba ìbílẹ̀ Ipokia, ìpínlẹ̀ Ogun tí fi ìkọnilóminú hàn sí bí ìjọba àpapọ̀ ṣe gbé àwọn ẹnu ibodè kan tì pa.
Ẹnubodè Idiroko tó pa ààlà sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti orílẹ̀ èdè Olómìnira Benin jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹnubodè tí ìjọba àpapọ̀ kéde rẹ̀ wí pé kí wọ́n ṣí láti ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹrin, ọdún 2022.
- Mo ti 'ùnfollow' ẹ lórí 'social media'; Ọlọ́run a ṣe idajọ fún ẹyin méjèèjì- Iyawo Yul-Edochie
- Ìgbẹ́jọ́ Ilànà Ọmọ oodua àti Náìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ nílé ẹjọ́ ní Ekiti
- Látàri ìjà Russia àti Ukraine, Bí a ṣe fẹ́ dènà ìyàn oúnjẹ ní Naijiria rè é- Buhari
- NDLEA sàmì sí ilé Abba Kyari mẹ́fà àti ilé ìtàjà tó ní ṣọ́ọ̀bù 100 ní Maiduguri fún ìwádìí
- Ọlọ́pàá Eko kéde orúkọ ọlọ́pàá tó ṣíná ìbọn bolẹ̀ nílé ọtí, téèyàn méjì fi kú
- Bí o bá san owó fún ìtúsílẹ̀ ẹnikẹ́ni láhámọ́ ajínigbé, ẹ̀wọ̀n ọdún 15 wà níkàlẹ̀ fún ọ
- Látàri ìjà Russia àti Ukraine, Bí a ṣe fẹ́ dènà ìyàn oúnjẹ ní Naijiria rè é- Buhari
Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí àwọn ènìyàn ìlú láti mọ ohun tí ojú wọn rí láàárín ọdún mẹ́ta tí ẹnubodè náà wà ní títì pá, wọ́n ṣàlàyé pé ohun tí ojú àwọn rí kọjá sísọ.
Lára àwọn tó ń ta oúnjẹ àti èso nínú ọgbà ẹnubodè Idiroko ní fún ọdún mẹ́ta tí ẹnubodè náà fi wà ní títì pá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ni kò rí nǹkankan ṣe tí ayé kò sì dẹrùn fún àwọn.
Wón ní àwọn kò rí ibi kankan gba lọ dé bi tí àwọn yóò rí ọwọ́ họrí tí gbogbo ìlú sì dá páropáro.
Wọ́n fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àwọn dùn sí pé ìjọba àpapọ̀ tì ṣí ẹnubodè náà, gbogbo nǹkan kò ì tíì bọ̀ sípò fún àwọn nítorí iṣẹ́ kò ì tí bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu.
Agbẹnusọ àwọn ọ̀dọ́ Ipokia sọ̀rọ̀:
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Agbẹnusọ àwọn ọ̀dọ́ ní ìjoba ìbílẹ̀ Ipokia ní ó ṣe àwọn láàánú wí pé púpọ̀ nínú àwọn ló ti jẹ́ Ọlọ́run ní pè nítorí àkóbá tí ìṣẹ̀lẹ̀ títi ẹnubodè náà kó bá àwọn.
Ó ṣàlàyé pé kò dín ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀fà àwọn ọ̀dọ́ ló ń ṣiṣẹ́ nínú ọgbà náà kí wọ́n tó tìí pa.
Ó fi kun pé lẹ́yìn tí wọ́n ti ibodè náà ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni kò rí okoòwò kan tí wọ́n sì di nnkan mìíràn sínú ìlú.
Ó tẹ̀síwájú wí pé gbogbo ètò ọrọ̀ ajé ìlú náà ló ti dẹnu kọlẹ̀ ti ohun gbogbo kò si lọ létòletò mọ nítorí pé àwọn tó ń kó ọjà wọlé jáde ló ń mú ètò ajé ìlú náà gbèrú.
Bákan náà ló pàrọwà sí ìjọba bí wọ́n ṣe ṣí ẹnubodè náà láti jọ̀ ọ́ jàre báwọn dá ètò ṣíṣe ìwé orí ọkọ̀ padà sí ẹnubodè náà nítorí ohun ni iṣẹ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ìlú náà fi ń jẹun.
Ó ní láti bí ọdún mẹ́fà sẹ́yìn ni ìjọba àpapọ̀ ti da dúró ṣaájú kí wọ́n tó gbé ẹnubodè náà tì pa pátápátá lọ́dún mẹ́ta sẹ́yìn
- 'Ètò ayẹ́yẹ́ ìsìnkú Oba Lamidi Adeyemi kòí tíì wáyé, àfọ̀mọ́ Aàfin ń lọ lọ́wọ́'
- Mo ti gbà báyìí pé ohun gbogbo tó n dán kọ́ ni wúrà - Olori Badirat Adeyemi
- Wo ohun tó yẹ kó mọ nípa Baràá ibùgbé ìkẹyìn Aláàfin Olayiwola Adeyemi
- Irú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo
- Ẹ yé fi ìpapòdà àwọn lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ Oyo kọmi lọ́rùn - Gómìnà Seyi Makinde
- Wo Alàáfin 43 tó jẹ́ láti ìgbà ìwásẹ̀ ṣáajú Lamidi Adeyemi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wàjà
- Ẹ yé fi ìpapòdà àwọn lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ Oyo kọmi lọ́rùn - Gómìnà Seyi Makinde
- Wo Alàáfin 43 tó jẹ́ láti ìgbà ìwásẹ̀ ṣáajú Lamidi Adeyemi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wàjà
Àwọn awakọ̀ náà fi ẹ̀hónú wọn hàn
Nígbà tí wọ́n ń bá ikọ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ní àwọn awakọ̀ ní ìlú Idiroko ní ojú àwọn rí tó lásìkò tí ìjọba fi gbé ẹnubodè Idiroko tì pa.
Wọ́n ṣàlàyé pé ní àwọn kìí rí epo bẹntiróòlù rà nítorí ilé epo Conoil kan ṣoṣo tó wà ní ìlú Idiroko tí kógbá sílé nítorí ẹnubodè tí wọ́n tì pa.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Bákan náà ni wọ́n kọminú pé ọ̀dúnrún náírà ni àwọn ń ra jálá epo bẹntiróòlù kan lọ́wọ́ àwọn tó ń lọ ra epo bẹntiróòlù ní ìlú mìíràn wá tà á fún àwọn.
Wọ́n ní àkóbá ńlá ni títì tí ìjọba ti ẹnubodè náà jẹ́ fún àwọn tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ wọn nígbà tí wọ́n jóná kú níbi tí wọ́n ti ń gbé epo bẹntiróòlù gun orí ọ̀kadà.
Bẹ́ẹ̀, wọ́n fi ìrètí hàn wí pé tí ètò ọrọ̀ ajé bá bẹ̀rẹ̀ ní ẹnubodè náà, nǹkan yóò yípadà sí rere fún àwọn ènìyàn ìlú náà.

Ìjọba àpapọ̀ ṣí ẹnubodè Idiroko àti àwọn mẹ́ta mìíràn, wo ohun tí BBC bá bọ̀ níbẹ̀
Ìjọba àpapọ̀ ṣí ẹnubodè Idiroko àti àwọn mẹ́ta mìíràn
Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kejìlélógún, oṣù kẹrin, ọdún 2022 ni ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kéde ṣíṣí àwọn ẹnubodè mẹ́rin.
Àwọn náà ni ẹnu ibodè Idiroko ní ìpínlẹ̀ Ogun, Jibiya ní ìpínlẹ̀ Katsina, Kamba ní Kebbi àti Ikom ní ìpínlẹ̀ Cross River.
Ohun ti BBC Yoruba ba bọ ni Idi Iroko lo wa ninu fọnran yii
- 'Ẹran ẹtu ni mo yìnbọn sí, àmọ́ òkú ìmáàmù ni mo bá nígbà tí mo fẹ́ gbe e'
- Látàri ìjà Russia àti Ukraine, Bí a ṣe fẹ́ dènà ìyàn oúnjẹ ní Naijiria rè é- Buhari
- NDLEA sàmì sí ilé Abba Kyari mẹ́fà àti ilé ìtàjà tó ní ṣọ́ọ̀bù 100 ní Maiduguri fún ìwádìí
- Kìí ṣe nǹkan abàmì bí Alaafin, Soun àti Olubadan ṣe papòdà lèralèra - Elebuibon
- Mọ̀ nípa Baṣọ̀run ìlú Oyo, Oloye Yusuf Akinade Ayoola tí yóò delé de Aláàfin tuntun
- Kò sí Ilana Omo Oodua mọ́ ní UK, a fẹ́ ṣe àtúnṣe - Ilana Ọmọ Oodua
- To bá fẹ́ dara pọ̀ mọ́ Yoruba Nation, ìgbésẹ́ tó gbé rèé - Ilana Oodua
- Ká má rí! Kò sí aàyè fún ìdìbò Gómìnà ní Osun àti Ekiti- Ilana Omo Oodua
Kini o ti ṣẹlẹ saaju?
Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ igbákejì ọ̀gá àgbà àjọ tó ń mójútó ẹnubodè, Custom, E. I. Edorhe ni ìjọba àpapọ̀ ti ṣe ìkéde náà tó sì wá rọ àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà láti ṣàmójútó àwọn ẹnu ibodè náà daadaa.
Ní oṣù kẹjọ, ọdún 2019 ni ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ pé kí gbogbo ibodè àti ẹnu ààlà ilẹ̀ tó wọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà di títì pa nítorí àti dènà kíkó àwọn oúnjẹ kan wọ orílẹ̀ èdè yìí.
Bákan náà ni ìjọba ní ìgbésẹ̀ náà yóò mú ìdàgbàsókè bá ìpèsè àwọn oúnjẹ kan bíi ìrẹsì lábẹ́nú.
Ẹ̀wẹ̀, ní oṣù kejìlá, ọdún 2020, ìjọba kéde pé kí wọ́n ṣí àwọn ibodè Seme, Ilela, Maigatari àti Ofong.
Láti ìgbà náà ni àwọn ènìyàn ti ń pòùngbẹ pé ìgbà wo ni ìjọba yóò ṣí àwọn yòókù kó tó di pé ìjọba kéde ṣíṣí rẹ̀ lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

Àwọn ènìyàn Nàìjíríà fi ìdùnnú hàn bí ìjọba ṣe ṣí àwọn ibodè mẹ́rin mìíràn
Àwọn olùgbé ẹnu ààlà ibodè orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ń fò fáyọ̀ bí ìjọba àpapọ̀ ṣe kéde ṣíṣí àwọn ibodè tó wọ orílẹ̀ èdè yìí kan lọ́jọ́ Ajé ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹrin, ọdún 2022.
Àjọ tó ń mójútó àwọn ẹnu ibode orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ọjọ́ Ẹti kéde pé ìjọba àpapọ̀ ti buwọ́lu ṣíṣí àwọn ibodè Idiroko ní ìpínlẹ̀ Ogun, Jibiya ní ìpínlẹ̀ Katsina, Kamba ní Kebbi àti Ikom ní ìpínlẹ̀ Cross River.
Nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ igbákejì ọ̀gá àgbà àjọ Custom, E. I. Edorhe wá rọ àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà láti ṣàmójútó àwọn ẹnu ibodè náà dada.
- Irú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo
- Wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn olòrì Alaafin Adeyemi àtàwọn tó bá fẹ́ fẹ́ wọn
- "Kòríkòsùn lèmi àti Alaafin ṣùgbọ́n kété táwọn kan kẹ́ẹ́fín pé èmi láàyò ni gbogbo nǹkan dojúrú." Badirat Ajoke, olorì tẹ́lẹ̀ kẹ́dùn Alaafin
- Wo àwọn òrékelẹ́wà tí yóò ṣe opó lẹ́yìn Aláàfin Oba Adeyemi tó papòdà
- Wo Alàáfin 43 tó jẹ́ láti ìgbà ìwásẹ̀ ṣáajú Lamidi Adeyemi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wàjà
- Aláàfin àti Ọba ilẹ̀ Yorùbá márùn-ún mìí tó wàjà láàrin oṣù márùn-ùn péré
Nígbà tí BBC ṣe àbẹ̀wò sí ẹnu ibodè Jibiya ní ìpínlẹ̀ Katsina, àwọn ènìyàn agbègbè náà ní ṣíṣí ẹnu ibodè náà yóò mú kí ètò ọrọ̀ ajé ní agbèegbè náà rú gọ́gọ́ si.
Alhaji Salisu Jibiya sọ fún BBC pé inú awọn dún nítorí pé ọdún mẹ́ta ní àwọn fi ń gbé nínú ìnira nítorí káràkátà kò wáyé ní agbègbè àwọn.
Jibiya ní àwọn ti le máa kó ẹ̀wà, áyá, làbídùn wọlé báyìí ṣùgbọ́n àwọn yóò san owo orí ọjà lórí wọn pẹ̀lú àṣẹ tuntun tí ìjọba àpapọ̀ pa yìí.
Ní ìpínlẹ̀ Kebbi bákan náà, ibodè Kamba náà ti jẹ́ ṣíṣí tí àwọn ènìyàn agbègbè náà sọ fún ikọ̀ BBC pé ohun tí àwọn ti ń pa òǹgbẹ rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́ ni.
Yahusa Sahabi ni ohun tí ṣíṣí ẹnu ibodè náà fi dùn mọ́ òun jùlọ ni wí pé gbogbo ọ̀wọ́n gógó tó bá oúnjẹ́ ni àdínkù yóò bá ní àsìkò yìí.
Ó ní ìnira tí bí ìjọba ṣe ti ibodè náà kó bá àwọn kò kéré rárá, tí àwọn yóò sì mí mímí àláfíà báyìí.
- Adájọ́ sún ìgbẹ́jọ́ síwájú lẹ́yìn tí afurasí kan tó lọ́wọ́ nínú ikú Timothy Adegoke ṣubú nílé ẹjọ́
- Ìyànjẹ ni fún ọmọ Naijiria tí mi ò bá fẹ̀hìntì báyìí- Osinbajo
- Àwọn olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP túká, ìmọ̀ràn wọn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
- Njẹ́ o mọ̀ pé láàrín ìṣẹ́jú méjì, ọmọdé kan ń kú nítorí àìsàn ibà??
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ nípa ikú Baálẹ̀ àti èèyàn méjì tó kú l'Ondo táwọn ọ̀dọ́ ń so ikú wọn mọ́ agbófinró lọ́rùn
- Àjọ NDLEA nawọ́ gán ọkùnrin tó lọ́wọ́ nípa ẹ̀sùn N3bn egbògi Tramadol tí Abba Kyari ń kojú
- Okùnrin tó so àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀ bíi ewúrẹ́, tó sì nà wọ́n rí ẹ̀wọ̀n ogún ọdún he
- 'Mo dáríji ẹni tó pa mí lọ́kọ́, mò sì gbà kí àwọn ọmọ wa fẹ́ ara wọn'
- Emmanuel Macron borí Le Pen ní ìbò ààrẹ France
Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?
Ní oṣù kẹjọ, ọdún 2019 ni ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ pé kí gbogbo ibodè àti ẹnu ààlà ilẹ̀ tó wọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà di títì pa nítorí àti dènà kíkó àwọn oúnjẹ kan wọ orílẹ̀ èdè yìí.
Bákan náà ni ìjọba ní ìgbésẹ̀ náà yóò mú ìdàgbàsókè bá ìpèsè àwọn oúnjẹ kan bíi ìrẹsì lábẹ́nú.
Ẹ̀wẹ̀, ní oṣù kejìlá, ọdún 2020, ìjọba kéde pé kí wọ́n ṣí àwọn ibodè Seme, Ilela, Maigatari àti Ofong.



















