France Presidential Election: Emmanuel Macron wọlé ìbò ààrẹ France lẹ́ẹ̀kejì pẹ̀lú àfojúsùn ìbò tó wọlé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Esi idibo sipo aarẹ lorilẹede France ti n wọle, Aarẹ to wa nipo bayii, Emmanuel Macron ti ọpọ ti n foju wo pe yoo wọle ti wọle fun saa keji bayii pẹlu ida mejidinlọgọta ibo gẹgẹ bi afojusun ibo naa ṣe n gbe e jade.
Eto idibo ti pari lẹyin ti awn oludibo dibo yan ẹni ti yoo jẹ aarẹ laarin Emmanuel Macron ati Marine Le Pen.
- Àṣírí ńlá tó ń bẹ láàrín Alaafin àtàwọn onílù rẹ̀ rèé
- Ta ni Yorùbá ń pè ní Abọ́bakú?
- Nínú àwòràn, wo ìgbà ayé Aláafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta tó lọ bá àwọn Baba Ńlá rẹ̀
- Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀
- Aláàfin àti Ọba ilẹ̀ Yorùbá márùn-ún mìí tó wàjà láàrin oṣù márùn-ùn péré
- Wo àwọn ǹkan tí o kò mọ̀ nípa Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tó wàjà
- Kéte ti Baba dákẹ́ ni àṣà àti ìṣẹ̀ṣe ti bẹ̀rẹ̀ l'Áàfin - Ẹ wo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Aafin Oyo
- Ààrẹ Buhari, Ooni Ile Ife, Obasanjo kẹ́dùn Alaafin Oyo tó wàjà
Bí ètò ìdìbò ṣe ń lọ ní orílẹ̀-èdè France nìyí
Òní lòní ń jẹ́ lórí ètò ìdìbò sípò Ààrẹ tó ń wáyé ní orílẹ̀ èdè France.
Lónìí ni àwọn olùdìbò ní orílẹ̀ èdè France yóò máa dìbò yan ẹni tó wù wó nínú Ààrẹ Emmanuel Macron tàbí Marine Le Pen láti darí wọn fún ọdun márùn-ún mìíràn.

Ní ago mẹ́jọ òwúrọ̀ (06:00 GMT) ni ètò ìdìbò ti bẹ̀rẹ̀ níbi tí mílíọ̀nù méjìdínláàdọ́ta ènìyàn ní àǹfàní láti kópa.
Ní ago mẹ́jọ alẹ́ ní èsì àkọ́kọ́ nípa ẹni tí yóò gbégbá orékè yóò jáde.
Kí ẹnikẹ́ni tó le borí nínú àwọn méjéjèjì, wọ́n nílò àwọn olùdìbò tó dìbò fún àwọn olùdíje mìíràn níbi ìpele ètò ìdìbò àkọ́kọ́.

Ohun tó ṣókùnkùn ni wí pé ṣé àwọn ènìyàn yóò dìbò fún àwọn méjéèjì yìí tàbí wọn kò ní jáde rárá nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn France wà ní ìsinmi tí èyí sì lè mú kí àwọn ènìyàn má jáde dìbò.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpolongo ètò ìdìbò náà kò pọ̀ púpọ̀, ohun tó dájú ni pé ẹnìkan nínú Macron àti Le Pen ni yóò jámọ́ lọ́wọ́.
Kíni àwọn ènìyàn ń sọ nípa Macron àti Le Pen?
Àwọn tí kò gba ti Macron ń fẹ̀sùn kàn án wí pé àwọn olówó nìkan ni ìjọba rẹ̀ gbè, tí àwọn mìíràn sì ń bu ẹnu àtẹ́ lu Le Pen wí pé ó ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ààrẹ orílẹ̀ èdè Russia, Vladimir Putin.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ṣe ń sọ, nítorí ìlérí wí pé òun yóò mú àyípadà ọ̀tun bá orílẹ̀ èdè náà ni àwọn ènìyàn ṣe dìbò fún Macron ní sáà àkọ́kọ́ ṣùgbọ́n àwọn kò rí àyípadà kankan.
Onírúurú ìpèníjà ní ìjọba rẹ̀ kojú bíi ìfẹ̀hónúhàn, àìsàn Covid 19 àti ohun gbogbo ṣe gbówó lórí.
Ọ̀wọ́n gógó tó ń bá orílẹ̀ èdè France fínra ni Le Pen ti ṣèlérí wí pé òun yóò kojú ní kété tí òun bá gorí àléfà gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ìlú kéréje tí ètò ọrọ̀ ajé wọn ti dẹnu kọlẹ̀ lásìkò Macron ló ti ṣèlérí wí pé àwọn yóò dìbò fún Le Pen nítorí sáà Macron kò gbè wọ́n.
Lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn ẹ̀wẹ̀, ominú ń kọ wọ́n lórí ogun tó ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine tí wọn kò sì mọ òun tí Le Pen le ṣe tó bá di Ààrẹ nítorí ìbáṣepọ̀ tó ní pẹ̀lú Putin.
Ìrètí wà pé ẹni tó bá rí àtìlẹyìn àwọn tó dìbò fún Jean-Luc Melenchon ni yóò borí níbi ètò ìdìbò yìí.
- Àlè kun abilékọ bíi ẹran ọ̀yà láti fi ṣe òògùn owó, ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ
- Ọwọ́ ọlọ́pàá Ogun tẹ ọkùnrin ọgbọ̀n ọdún tó fi ipá ba obìnrin lò nínú ṣọ́ọ̀ṣì
- Ẹ wo ọ̀pọ̀ ìgbà tí àwọn òṣèré fíìmù Yorùbá ti gbé àwọn olólùfẹ́ wọn ní ‘handicap'
- Láì tíì pé ọ̀sẹ̀ kan tó kéde akọ́nimọ̀ọ́gbá tuntun, Man U tún jẹ àjẹranjú ìyà lọ́wọ́ Arsenal pẹ̀lú góòlù Mẹ́ta sí ẹyọkan




















