Okùnrin tó so àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀ bíi ewúrẹ́, tó sì nà wọ́n rí ẹ̀wọ̀n ogún ọdún he

Sun Shujun

Oríṣun àwòrán, Social media

Ile ẹjọ kan ni Rwanda ti ṣedajọ ọmọ orilẹ-ede China kan lẹyin ti fidio ibi to ti so awọn ọmọ orilẹ-ede naa mọ igi to si n na wọn fa ori ayelujara ya.

Ile ẹjọ naa ni ki Sun Shujun lọ ṣẹwọn ogun ọdun.

Bẹẹ naa ni ile ẹjọ yii kan naa tun sọ ọmọ orilẹ-ede Rwanda to jẹ oṣiṣẹ ọmọ ilẹ China yii si ẹwọn ọdun mejila fun ipa to ko ninu bi wọn ṣe da bantẹ iya fun awọn eeyan rẹ.

Iroyin ni ẹsun ole jija ni Shujun fi kan awọn eeyan ọhun ti wọn jẹ oṣiṣẹ rẹ nibi ti wọn ti n wakusa lagbegbe Rutsiro.

Shujun ni oun ti kilọ fun awọn ole naa ṣaaju iṣẹlẹ ọhun lẹyin ti wọn ji oun lẹru ko amọ wọn kọ eti ikun si ikilọ oun.

Inu oṣu Kẹjọ, ọdun 2021 ni fidio ifiyajẹni naa fa ori ayelujara ya, eyii to mu awọn ọlọpaa fi ṣikun ofin mu Shujun, amọ wọn gba beeli rẹ lẹyin naa.

Àkọlé fídíò, Alaafin Oyo's burial: Oba Lamidi Adeymi darapọ̀ mọ́ àwọn àgbà ìṣáájú, ọ̀pọ̀ ń dárò Kábíèsí

Awọn oṣiṣẹ Shujun lo ya fidio ọhun, ti wọn si gbe jade loju opo ikansiraẹni lori ayelujara lọna ati fẹhonuhan.

Awọn oṣojumikoro sọ nile ẹjọ pe Shujun ri opo kan mọlẹ, nibi to maa n so awọn to ba jalẹ mọ lati fi iya jẹ wọn.

Ẹwẹ, ileeṣẹ iroyin abẹle kan sọ pe ọọfisi ijọba orilẹ-ede China ti bu ẹnu atẹ lu fidio naa ati iwa ti okunrin naa wu.