Egbema Illegal Refinery Explosion: Wọ́n ti ṣe ìsìnkú àpapọ̀ fún èèyàn 50 lára àwọn tó jóná níbúdò ìfọpo tó gbiná ní Imo

Awọn ara agbegbe Abaezi ti sin eniyan aadọta ninu aadọfa eniyan to ku nibi ibugbamu to waye nijọba ibilẹ Ohaji /Egbema ni ipinlẹ Imo.
Awọn wọnyii kagbako ina ni agbegbe ti wọn ti n wa epo rọọbi lọna aitọ, to si gbina.Wọ́n ti ṣe ìsìnkú àpapọ̀ fún èèyàn 50 lára àwọn tó jóná níbúdò ìfọpo tó gbiná ní Imo
Awọn ara agbegbe naa sin awọn aadọta naa si igbo Abaezi ni ijọba ibilẹ Abacheke, ni Ohaji/Egbema nibi ti awọn ara agbegbe naa ti gbẹ iboji ti wọn sin wọn si.
- Adájọ́ sún ìgbẹ́jọ́ síwájú lẹ́yìn tí afurasí kan tó lọ́wọ́ nínú ikú Timothy Adegoke ṣubú nílé ẹjọ́
- Ìyànjẹ ni fún ọmọ Naijiria tí mi ò bá fẹ̀hìntì báyìí- Osinbajo
- Àwọn olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP túká, ìmọ̀ràn wọn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
- Njẹ́ o mọ̀ pé láàrín ìṣẹ́jú méjì, ọmọdé kan ń kú nítorí àìsàn ibà??
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ nípa ikú Baálẹ̀ àti èèyàn méjì tó kú l'Ondo táwọn ọ̀dọ́ ń so ikú wọn mọ́ agbófinró lọ́rùn
- Àjọ NDLEA nawọ́ gán ọkùnrin tó lọ́wọ́ nípa ẹ̀sùn N3bn egbògi Tramadol tí Abba Kyari ń kojú
- Okùnrin tó so àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀ bíi ewúrẹ́, tó sì nà wọ́n rí ẹ̀wọ̀n ogún ọdún he
- 'Mo dáríji ẹni tó pa mí lọ́kọ́, mò sì gbà kí àwọn ọmọ wa fẹ́ ara wọn'
- Emmanuel Macron borí Le Pen ní ìbò ààrẹ France

Lasiko ti wọn n sọ iye awọn eniyan ti wọn sin, Alaga ijọba ibilẹ naa, Marcel Amadioha ni awọn ẹṣọ alaabo to fi mọ ileeṣẹ pajawiri ni Naijiria, NEMA wa ni ibi isinku naa.
Amadioha sọ pe awọn ti wọn sin naa, ni awọn ti ina naa jo de ibi pe, ko si ẹni to da wọn mọ.
Ọkan lara awọn adari ọdọ ni agbegbe naa, Ben Marcus ni awọn ti wọn kagbako ina naa, ti awọn eniyan wọn si da wọn mọ, ni wọn fi silẹ fun mọlẹbi lati lọ sin wọn.

''Pupo ninu awọn to kagbako ina naa wa lati ọna jinjin pẹlu awọn to wa lati ayika ninu wọn.''
''O daniloju pe eyi yoo jẹ ẹkọ fun awọn ti wọn n ṣe iru iṣẹ to lodi si ofin ijọba yii.''
Bakan naa lo rọ ijọba lati pese iṣẹ fun awọn ọdọ nitori ainiṣẹ lo mu wọn di ero ẹni to n ṣe iru iṣẹ bẹẹ.
Amọ ki wọn to sin awọn eniyan naa ni wọn ti n reti awọn eleto ilera lati wa si agbegbe naa, lẹyin ti wọn ṣe akojọ awọn to ku ni ibi ti ina ti jọ wọn, lasiko ti wọn n salọ.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn kan ni ìbẹ̀rù wà pé wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ilé ìfọpo rọ̀bì kan tó jẹ́ ayédèrú ṣe gbiná nínú igbó Abaezi ní ìjọba ìbílẹ̀ Ohaji-Egbema ní ìpínlẹ̀ Imo.
Ìròyìn ní ọkọ̀ mẹ́fà ló jónà ráúráú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná tó wáyé ní ìlú ọ̀hún tó pààlà pẹ̀lú ipínlẹ̀ Rivers.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Imo ní àwọn ilé ìfọpo rọ̀bì tó jẹ́ ayédèrú méjì tó súnmọ́ ara wọn ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti wáyé, tí àwọn àwòrán tó jáde láti ibẹ̀ ṣàfihàn àwọn òkú ènìyàn tó ti jóná kọjá mímọ̀.
- Wo Alàáfin 43 tó jẹ́ láti ìgbà ìwásẹ̀ ṣáajú Lamidi Adeyemi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wàjà
- Òrumọ́jú ní ara Oba Lamidi Adeyemi wọ káà ilẹ̀ lọ ní Ìbarà gẹ́gẹ́ bí ìṣe ìran Yorùbá ṣe làá kalẹ̀
- Nínú àwòràn, wo ìgbà ayé Aláafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta tó lọ bá àwọn Baba Ńlá rẹ̀
- Àṣírí ńlá tó ń bẹ láàrín Alaafin àtàwọn onílù rẹ̀ rèé
- Aláàfin àti Ọba ilẹ̀ Yorùbá márùn-ún mìí tó wàjà láàrin oṣù márùn-ùn péré
Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ohun tí ó fa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ó ṣojú mi kòró kan, Eze Ikedi tó bá àwọn akọ̀ròyìn Daily Post sọ̀rọ̀ ṣàlàyé wí pé ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀, tí àwọn ṣàadédé rí èéfí nínú igbó Abaezi.
Ikedi ní àwọn rí àwọn ènìyàn nínú ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ iná náà ti ń wáyé ṣùgbọ́n àwọn kò rí àtijáde wọn, ẹ̀rù sì ń ba àwọn láti súnmọ́ ibẹ̀.
"Nígbà tí a gbìyànjú láti súnmọ́ ibẹ̀, a ri wí pé àwọn ènìyàn tó ti jóná pátápátá ti lé ní ọgọ́rùn-ún, tí àwọn tó sì farapa sì pọ̀ gan."
"A gbé wọn lọ sí ilé ìwòsàn abọ́dé tó wà nínú ìlú àmọ́ wọn kò gba ọ̀pọ̀ nínú wọn."
Ìjọba ìpínlẹ̀ Imo kéde ẹni tó ni ilé ìfọpo náà bí ẹni tí wọ́n ń wá
Kọmíṣọ́nà fọ́rọ̀ èpò bẹntiróòlù ní ìpínlẹ̀ Imo, Goodluck Opiah nígbà tó ṣe àbẹ̀wò síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò le fi iye àwọn ènìyàn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ múlẹ̀ pàtó nítorí ọ̀pọ̀ mọ̀lẹ́bí ló ti wá gbé òkú àwọn ènìyàn wọn kúrò, ẹ̀mí ọ̀pọ̀ àwọn ló sùn síbi ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà.
Opiah wá kéde ẹni tó ni ilé ìfọpo náà, Okenze Onyewoke gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ìjọba ń wá láti fi póró òfin gbé e.
- Ààrẹ Buhari, Ooni Ile Ife, Obasanjo kẹ́dùn Alaafin Oyo tó wàjà
- Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀
- Kéte ti Baba dákẹ́ ni àṣà àti ìṣẹ̀ṣe ti bẹ̀rẹ̀ l'Áàfin - Ẹ wo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Aafin Oyo
- Wo àwọn ǹkan tí o kò mọ̀ nípa Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tó wàjà
- Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀
Opiah ní yàtọ̀ sí iṣẹ́ búburú tó ṣẹlẹ̀ yìí, gbogbo àwọn ẹranko inú omi tó wà nínú odò ilú náà ló ti parun tán nítorí púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ilú náà ló jẹ́ àgbẹ̀ àti apẹja.
Ó ní gbogbo èéfí tó ń jáde láti ibi ayédèrú ilé ìfọpo náà ló ti ń ṣe ọṣẹ́ burúkú sí inú ìlú náà.
Ó ṣàlàyé wí pé púpọ̀ nínú àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ láabi náà ló ń wá láti ìpínlẹ̀ Rivers, Bayelsa àti àwọn ìpínlẹ̀ tó sún mọ́ wọn.
Bákan náà ló pàrọwà sí àwọn ọ̀dọ́ láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà tó le da àláfíà ìlú rú.
- Àwọn ọlọ́pàá nawọ́ gán afurasí tó ń pèsè àdó olóró fún IPOB
- Ìdí tí Osinbajo fi ṣèbẹ̀wò sí Olubadan àti ohun tí wọ́n sọ rèé
- Bí ètò ìdìbò ṣe ń lọ ní orílẹ̀-èdè France nìyí
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ṣí gbogbo ẹ̀ka ilé ẹ̀kọ́ Chrisland padà
- Àlè kun abilékọ bíi ẹran ọ̀yà láti fi ṣe òògùn owó, ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ
- Ẹ wo ọ̀pọ̀ ìgbà tí àwọn òṣèré fíìmù Yorùbá ti gbé àwọn olólùfẹ́ wọn ní ‘handicap'
- Bí mo ṣe máa rí N100m tí mo fẹ́ fi gba fọ́ọ̀mù APC rèé...
- Ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ yóò wà ní Nàìjíríà, àtàwọn orílẹ̀èdè míràn wọ ọdún 2023 - IMF
- $5.39 ni INEC yóò ná lórí olùdìbò kọ̀ọ̀kan lọ́dún 2023
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí àwọn ayédèrú ìfọpo rọ̀bì yóò gbiná
Irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé láìpẹ́ yìí ní ìlú Rumuekpe ní ìjọba ìbílẹ̀ Emohua, ìpínlẹ̀ Rivers lọ́dùn 2021 níbi tí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ti sùn tí ọ̀pọ̀ oko sì bàjẹ́.
Bákan náà nínú oṣù kọkànlá, ọdùn 2021, ìjàmbá iná tún wáyé ní ilé ifọpo Bonny-Bille-Nembe tí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dùkíà sì bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.






















