Abuja KerosineTanker Explosion:Àwọn ọmọdé àti ìsọ̀ jóná ráú-ráú nígbà tí táńkà kẹrosínìí jóná

Oríṣun àwòrán, Abubakar Usman/Facebook
Awọn eeyan ti ko si ẹnikẹni to le sọ iye wọn lo ti sọ ẹmi wọn nu ninu isẹlẹ ijamba ina kan to waye ni agbegbe Kubwa nilu Abuja.
Isẹlẹ ina ọhun to waye lalẹ ọjọ Ẹti ni awọn eeyan ti isẹlẹ naa soju wọn ni tanka epo Karosini to gbina lojiji lo sokunfa rẹ.
Ọwọja ina ọhun lo bẹrẹ si tan kalẹ bii ọwara ojo si awọn ọja adugbo miran to mule ti Kubwa, to si jo ọpọlọpọ sọọbu kanlẹ.
- "Ó dùn mí pé èmi ló bí Abubakar Shekau tó dá ayé lóró"
- Ìkúnlẹ̀ Abiyamọ oo! Ìyá ju ọmọ rẹ̀ méjì sí Kànga
- Ọ́dọ́kùnrin 18 láti òkè ọya pẹ̀lú ohun ìjà olóró dojú ìjà kọ Àmọ̀tẹ́kùn l'Ondo
- Gómínà díbọn lọ ilé ìwòsàn, òṣìṣẹ ìlera tó gba rìbá N10,000 wọ gàù
- Ìdìbò gómìnà Anambra gbérasọ, ìíú dá wáí-wáí, aráàlú ń sá kíjo kíjo
- Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ lónìí lórí ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha
- Kí ló so Yemi Osinbajo pọ̀ mọ́ ilé alájà púpọ̀ tó dà wó ní Eko?
- Kókó méjìlá nípa ìgbé ayé Femi Osibona
- "Amẹ́ríkà ni Wale Bob-Oseni ń lọ, ìpè fóònù tó gbà, ló gbe lọ síbi ilé tó dà wó"
Koda, ọpọ eeyan ti ina ọhun gba mu lo jo kanlẹ, ti wọn si dagbere faye nigba ti awọn eeyan miran fara pa yanna-yanna.
Awọn eeyan ti isẹlẹ ijamba ina naa soju ina wọn sọ fun BBC pe awọn ọmọde kan gan jona kọja sisọ lasiko ti ina naa mu wọn.
Oniruuru awọn eeyan lo n sọ iroyin to tako ara wọn nipa isẹlẹ ina ọhun, ti awọn kan si sọ pe ado oloro lo bu.
Amọ awọn ara adugbo ti isẹlẹ ijamba ina naa soju wọn salaye pe tanka kan ti epo Karosini wa ninu rẹ lo gbina.
Nibayii, awọn ọlọpaa, awọn osisẹ panapana atawọn osisẹ adoola ẹmi nibi isẹlẹ pajawiri lo ti de sibi isẹlẹ naa.
Bakan naa ni awọn osisẹ ọlọpaa ti ya agbegbe ti ijamba naa ti waye sọtọ kawọn osisẹ pajawiri le raye sawari awọn eeyan to fori sọta isẹlẹ naa.



















