Babagana Umara Zulum: Nínú òṣìṣẹ́ ìlera 29 ta gbà sílé ìwòsàn náà, ẹyọ kan ṣoṣo ló wá láti tọ̀jú aláìsàn

Gomina Zulum atawọn osisẹ eleto ilera

Oríṣun àwòrán, The Governor of Borno State/Facebook

Iroyin ko to afojuba lọjọ ti gomina ipinlẹ Borno, Ọjọgbọn Babagana Umara Zulum, dibọn lai mura bii gomina lọ se abẹwo airotẹlẹ lọ sibudo ilera kan to jẹ tijọba lọjọbọ.

Gomina naa ko ko awọn ẹsọ tabi ọkọ afọnfere rẹ dani nigba to lọ sile iwosan naa.

Lasiko abẹwo rẹ naa, gomina ri awọn osisẹ ilera lorisirisi ti wọn n gba owo to to ẹgbẹrun mẹjọ si mẹwa naira lọwọ awọn alaisan fun itọju to yẹ ko jẹ ọfẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to jẹ pe ọjọ ta ba ri ibi, ni ibi n wọlẹ, kia mọsa ni gomina Zulum ransẹ pe Kọmisana feto ilera, Arabinrin Juliana Bitrus, pe ko wa tẹle oun ninu ọkọ alaisan onijoko mẹwa ti wọn maa n lo ni papakọ ofurufu.

Deede aago kan abọ ọsan ọjọbọ ni gomina Zulum kuro nile ijọba lai fọn mọto fere yafunyafun eyi to ya ọpọ awọn amugbalẹgbẹ rẹ lẹnu.

Gomina Zulum atawọn osisẹ eleto ilera

Oríṣun àwòrán, The Governor of Borno State/Facebook

Koda, kọmisana feto ilera gan ko mọ idi to fi se bẹẹ, o sa n wo gomina ni.

Ni kete ti Zulum gunlẹ sile iwosan naa, lo lọ si ibudo ilera Gwange II ti wọn sẹsẹ kọ silu Maiduguri, tijọba si pese awọn ohun eelo ilera igbalode si.

Sugbọn se ni jẹbẹtẹ gbe ọmọ le gomina lọwọ nigba to ri awọn osisẹ peleto ilera to n gba owo riba to wa laarin ẹgbẹrun mẹjọ si mẹwa naira ki wọn to se ayẹwo tabi itọju alaisan to ni arun iba lasan

Gomina ni "Awọn osisẹ to wa nile iwosan yii, Gwange II sọ pe ki awọn to le wo arun iba, awọn maa n gba to ẹgbẹrun mẹjọ si mẹwa naira lọwọ awọn alaisan.

Koda wọn ti sọ ibudo ilera ti ijsba kọ di ile iwosan aladani eyi to mu ki ọpọ araalu ti agbara wọn ko ka owo naa lati san, pa ile iwosan naa ti.

Se ni awọn osisẹ ilera to wa nibẹ n gba owo naa, ti wsn si n da si apo ara wọn lai boju wẹyin."

Gomina Zulum ti wa pasẹ fun ajọ to wa feto ilera alabọde nipinlẹ Borno lati tu isu de isalẹ koko nipa awọn osisẹ ile iwosan naa, ko si tete mọ awọn ọbayejẹ ẹda to wa nidi gbigba abẹtẹlẹ naa.

Gomina Zulum atawọn osisẹ eleto ilera

Oríṣun àwòrán, The Governor of Borno State/Facebook

Bakan naa lo ni gbogbo awọn osisẹ ti aje iwa ibajẹ naa ba si mọ lori ni ko fi iya to yẹ jẹ labẹ ofin.

Zulum ni ọkan rẹ wa bajẹ pe bi o tilẹ jẹ pe awọn akọsẹmọsẹ osisẹ ilera mọkandinlọgbọn nijọba n san owo osu fun nile iwosan naa, sibẹ, osisẹ ilera kan soso lo wa nibẹ, to n da awọn alaisan lohun.

Isẹlẹ yii lo tun mu gomina Zulum dibọn lọ sile iwosan ijọba miran, Gwange 1, amọ se lo ba ohun gbogbo to n lọ leto leto, bo se yẹ nibẹ, eyi to mu inu rẹ dun.

Se ni awọn osisẹ ilera to yẹ wa nikalẹ lati da alaidsan lohun lai gba owo riba kankan lọwọ wọn.

Àkọlé fídíò, Mesach Oyediran: Ọba ni Dafidi tó ń lu dùùrù, tó sì kọ sáàmù, ta ni èmi tí kò ní le yin