Anambra Election: IPOB ní òun kò ní kópa nínú ìbò gómìnà Anambra

Oríṣun àwòrán, AFP
Ẹgbẹ ajijagbara IPOB to n pe fun idasilẹ orilẹ-ede Biafra, ti fagile ofin konle o gbele ọlọsẹ kan to kede ṣaaju eto idibo gomina ipinlẹ Anambra ọjọ Abamẹta.
Akọwe iroyin ẹgbẹ naa, Emma Powerful lo kede igbesẹ yii ninu atẹjade kan to fi sita ni irọlẹ Ọjọbọ.
Oni ọjọ karun ùn oṣu kọkanla ọdun 2021 yii lo yẹ ki ofin konle o gbele naa bẹrẹ titi di ọjọ kẹwaa oṣu yii eleyii ti ko ba ṣakoba fun eto idibo gomina ipinlẹ Anambra ọjọ Abamẹta.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kókó méjìlá nípa ìgbé ayé Femi Osibona
- "Amẹ́ríkà ni Wale Bob-Oseni ń lọ, ìpè fóònù tó gbà, ló gbe lọ síbi ilé tó dà wó"
- "Ọ̀rẹ́kùnrin tá a fẹ́ra fún ọdún marùn ún fi ọta ìbọn yí kádàrá mi padà"
- Ọwọ́ tẹ oníṣègùn níbi tó ti ń sin ọmọ tuntun láàyè pẹ̀lú ọfọ̀ àti àyájọ́
- Buhari, dẹ̀yìn lẹ́yìn Sunday Igboho, Akintoye àti Kanu- Ẹgbẹ́ ọmọ Yorùbá kìlọ̀
- Ẹ̀kùn Àríwá pahùndà, ó fẹ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yà míì láti yan ààrẹ
- "Pásítọ̀ onímọ̀ ẹ̀rọ kan àti lébìrà 18 tó kó wá láti Ibafo sì wà lábẹ́ ilé Ikoyi "
Bakan naa ni IPOB sọ pe oun ko ni kopa ninu eto idibo ọhun.
Emma ṣalaye ninu atẹjade naa pe, awọn wọgile ofin konle o gbele tawọn kede tẹlẹ lẹyin tawọn eekan ilu at'awọn lọba lọba nilẹ Igbo parọwa s'awọn pe káwọn jẹ kí ibo gomina Anambra waye ni alaafia.
"Ki ẹnikẹni ma ṣe ro pe a gbe igbesẹ yii nitori bi awọn ẹṣọ eleto abo ṣe lu ipinlẹ Anambra ati ilẹ Igbo pa lo jẹ kí a gbé igbesẹ yii.
Awọn agbaagba to ba wa sọrọ ti fi da wa loju pe awọn yoo sa gbogbo agbara awọn lati ri pe ijọba apapọ tu olori IPOB, Nnamdi Kanu silẹ ni ahamọ ijọba.
Awọn eeyan lanfaani lati jade lọ dibo fun ẹnikẹni to ba wu wọn.
Ẹtọ awọn eeyan ni lati kopa ninu eto idibo, ati pe eyi tun túmọ sí pe ẹgbẹ IPOB ni igbagbọ ninu eto ijọba awaarawa," aburo Kanu lo sọ bẹẹ.
A ti gbọ pe ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS n gbero lati lo awọn janduku lati da rogbodiyan silẹ nibi eto idibo gomina ipinlẹ Anambra.
A si gbọ pe DSS ṣetan lati sọ pe ẹgbẹ IPOB lo ṣagbatèru ipaniyan ati rogbodiyan to ba waye ninu eto idibo naa.
Ẹgbẹ IPOB kii ṣe ẹgbẹ adaluru, a n rọ awọn eeyan ipinlẹ Anambra lati dibo ki wọn si duro ti ibo wọn.
Ko gbọdọ si ibo rira tabi eeru ninu eto idibo Anambra.
A ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ IPOB ati awọn eeyan orile-ede Biafra kaakiri agbaye fun atilẹyin wọn," Emma lo sọ bẹẹ ninu atẹjade to fi sita.
INEC ni idibo Anambra yoo waye:
Ẹwẹ, ajọ eleto idibo INEC ti sọ tẹlẹ pe eto idibo gomina Anambra yoo tẹsiwaju lai fọta pe.
Hajiya Zainab Aminu Abubakar to jẹ oṣiṣẹ INEC sọ pe gbogbo eto lo ti to bayii fun eto ibo naa lati gberasọ.
Ọgọọrọ awọn ọmogun, ọlọpaa at'awọn ẹṣọ eleto aabo mii lo ti wa ni ipinlẹ Anambra lati ri pe eto idibo naa kẹsẹ jari lọjọ Abamẹta.
Ko si ẹni to mọ bi nkan yoo ṣe ri nipinlẹ Anambra lọjọ Abamẹta lori bi eto abo ti mẹhẹ nibẹ.
Amọ, ohun kan to daju ni pe ajọ INEC ti ṣetan, bẹẹ ni awọn ẹṣọ eleto abo naa ti gbaradi lati pese abo to peye fawọn eeyan lasiko eto idibo gomina ipinlẹ Anambra.

Buhari ti já kulẹ bí ìbò Anambra bá forí ṣánpọn - Onímọ òṣèlú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nibayi ti ipalẹmọ fun eto idibo gomina nipinlẹ Anambra ti doju ọgbagade, awọn onims kan ti n sekilọ fun aarẹ Muhammadu Buhari pe ko sa gbogbo ipa rẹ lati ri daju pe eto idibo naa yọri si rere.
Ọmọwe Abubakar Kari, tii se onimọ nipa ọrọ oselu lọgba fasiti Abuja lo gba aarẹ nimọran bẹẹ lasiko to n ba BBC sọrọ.
Kari ni itiju nla ni fun ijọba to ba fi kuna lati se aseyọri nidi eto idibo naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìjọba Ethiopia figbe ta pe ogun ń bọ, ó kéde ìlú kò fara rọ
- Mọ̀ sì nípa Femi Osibona tó ni ilé alájà 21 tó wó ní Ikoyi
- Àsìta ìbọn bá àkẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan, bí ọ̀rọ̀ ṣe wáyé rèé
- Mo fẹ́ dákú níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún mi - Salawa Abeni
- Ọwọ́ Amotekun tẹ ọ̀dọ́ 18 tó rìn gbéregbère wọ Akure láti òkè ọya
- Ó di dandan kí a wa iṣu dé ìṣàlẹ̀ kòkò l'órí ọ̀rọ̀ ilé tí ó wó ní Ikoyi-Tinubu
- Ọ̀gá báńkì rẹ́wọ̀n he torí ó fi N219m owó oníbàárà kọ́ ilé, ra ilẹ̀
- Èèyàn ogún ló ti sọ ẹ̀mí nù nínú ilé alájà 21 tó wó ni Ikoyi - NEMA
"Eto idibo to se iyebiye ree, a si le sọ pe o jẹ idanwo fun ijọba Naijiria nipa bo se kaato to lati seto idibo kaakiri gbogbo Naijiria, kii se nipinlẹ Anambra nikan."
Kari fikun pe "Ofin ilẹ wa se agbekalẹ iyipada lati ọwọ ijọba kan si omiran lọdun mẹrin mẹrin.

Oríṣun àwòrán, NDH
Amọ asiko yii la mọ boya ijọba lagbara lati fi tipa sọ fun ikọ kan pe ko se ohun ti oun n fẹ tabi boya isọri awọn eeyan kan lagbara lati se ohun to ba wu wọn."
O tẹsiwaju pe ti awọn ikọ to n pe fun iyapa yii, IPOB ba yege lati dena eto idibo naa gẹgẹ bo ti seleri a jẹ pe ijọba Naijiria ti kuna niyẹn.
O ni lakoko yii ati ni ọjọ iwaju, awọn eeyan miran tabi igun kan naa le dide nibikibi lati da ijọba lọwọkọ, ko ma le se ohun to ba fẹ se.
Ẹwẹ, Ijọba ilẹ Amẹrika ni oun n reti pe wọn yoo seto idibo gomina nipinlẹ Anambra naa, ti alaafia yoo si jọba nibẹ lasiko idibo.
Bakan naa nijọba ipinlẹ Anambra gan ti fun awọn osisẹ rẹ nisinmi, to si ti kede pe ki wọn ti awọn opopona to wọ inu ipinlẹ naa pa, lọna ati ri daju pe eto idibo ọhun kẹsẹ jari.
Nibayi naa, ẹgbẹlẹgbẹ awọn ọmọ ogun ilẹ wa, to fi mọ awọn ọlọpaa atawọn ileesẹ agbofinro miran lo ti fi awọn osisẹ wọn ransẹ si Anambra lati ri daju pe eto idibo ọhun lọ nirọwọ irọsẹ.


















