Nigeria Security: Ọwọ́ Amotekun tẹ ọ̀dọ́kùnrin 18 tó rìn gbéregbère wọ Akure láti òkè ọya Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Amotekun
Awọn eeyan mejidinlogun lati apa ariwa orilẹede Naijiria lawọn oṣiṣẹ agbofinro Amọtẹkun ni ipinlẹ Ondo ti mu bayii.
Wọn ni wọn wọ ipinlẹ naa lai mọ ẹnikẹni tabi ni iṣẹ kan pato ti wọn fẹ wa ṣe nibẹ.
Ajọ agbofinro Amọtẹkun ni ipinlẹ Ondo ṣalaye pe ewu nla ni wọn jẹ fun eto abo ipinlẹ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àsìta ìbọn bá àkẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan, bí ọ̀rọ̀ ṣe wáyé rèé
- Mo fẹ́ dákú níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún mi - Salawa Abeni
- Ọ̀gá báńkì rẹ́wọ̀n he torí ó fi N219m owó oníbàárà kọ́ ilé, ra ilẹ̀
- Àwọn adarí iléẹ̀kọ́ wọ gàù fún gbígba owò lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà àìtọ́
- Àwọn agbébọn kọlu ilé adarí Ilana Omo Oodua Ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye l'Ado-Ekiti
- Èèyàn ogún ló ti sọ ẹ̀mí nù nínú ilé alájà 21 tó wó ni Ikoyi - NEMA
- Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Iree Poly pọ ẹ̀jẹ̀ àti itọ́ kó tó kú lẹ́yìn tó dé láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀
- Àṣírí ti tú,kà nípa bí ìyàwó ilé ṣe lẹ̀dí àpọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ jí ọkọ rẹ̀ gbé
- A gbọ́ ohùn bí àwọn ènìyàn tó há sí abẹ́ ìlé alájà 21 ṣe ń kérọrà fún ìrànwọ́ – NEMA
- Wòlíì kan fún òṣèré tíátà ní miliọnu mẹ́fà náírà láti fi tọ́jú àìsàn rẹ̀
- Ẹgbẹ́ TAMPAN ló mú kí ìjọba gbógun ti orísùn ọrọ̀ ajé mi - Yomi Fabiyi figbe ta
- Fulani darandaran kò ṣe lè ní Kwara, wọ́n pọ̀ ju ọmọ onílùú lọ
Agbegbe opopona marosẹ Ileṣa si Akurẹ ni wọn ti kọkọ kẹẹfin wọn ti wọn si fi ara wọn pamọ sẹyin awọn apo ẹwa ni inu ọkọ akẹru kan leyi ti awọn oṣiṣẹ Amọtẹkun si ts ipasẹ wọn de agbegbe Arakalẹ ni ilu Akurẹ.

Oríṣun àwòrán, dailypost
Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Oludari agba fajọ agbofinro Amọtẹkun ni ipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ ṣalaye pe nigba ti wọn fi ọrọ wa wọn lẹnuwo, awọn ọdọ naa ṣalaye pe eeyan kan lo fi awọn si ọkọ wa si ilu Akurẹ.
Wọn ni ẹni naa sọ fun awọn pe bi wọn ba ti de Akurẹ, wọn yoo ri ẹni ti wọn fẹ lọ ba, ti yoo si sọ nnkan ti wọn fẹ lọ ṣe fun awọn, eyi lo mu ki awọn tubọ fura si irinajo wọn.
Oloye Adeleẹyẹ fi kun pe Amọtẹkun ti fa wọn le awọn adari ẹgbẹ Miyetti Allah lọwọ wọn si ti da wọn pada si apa oke Ọya orilẹede Naijiria ti wọn ti wa.












