Ikoyi Buidling Collapse: NEMA ní ìgbìyànjú ń lọ lọ́wọ́ láti àwọn tó ṣì wà láàyé lábẹ́ ìlé tó wọ́!
Ileeṣẹ to n risi ọrọ pajawiri, NEMA ti ni awọn n sa gbogbo ipa awn lati doola ẹmi awọn to wa ni abẹ ile alaja mọkanlelogun to wo naa.
Oṣiṣẹ Ajọ NEMA ti wọn pe orukọ rẹ ni Arakunrin Ibrahim lo sọ bẹ fun awn oniroyin lasiko to n sọrọ lori igbeṣẹ wọn lati doola ẹmi awọn eniyan to wa labẹ ile alaja pupọ to wo naa.
Ibrahim ni awọn ti doola ẹmi eniyan mẹrin, ti marun si ti ba iṣẹlẹ naa lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹgbẹ́ TAMPAN ló mú kí ìjọba gbógun ti orísùn ọrọ̀ ajé mi - Yomi Fabiyi figbe ta
- EFCC gbé bàbá olówó Obi Cubana
- Fulani darandaran kò ṣe lè ní Kwara, wọ́n pọ̀ ju ọmọ onílùú lọ
- Bá wo ní ilé alájà 21 ṣe wó ní Ikòyí? Ẹ ṣèwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní kíákíá - Sanwo-Olu yarí
- Èèyàn tó há sí abẹ́ ilé tó wó kò sí ẹni tó lè sọ ṣùgbọ́n òkú mẹ́rin là ri-Ọlópàá
- Ẹ bá mi bẹ ọkọ mi Aláàfin kó gbà mí padà, mo ti ṣe àṣìṣe - Olorì Damilola
- Ìyà tó ń jẹ Ife lórí òpópónà tó bàjẹ́ kò tọ́, Buhari, Oyetola, ẹ wá nǹkan ṣe sí - Ooni
- Kí ló mú Lizzy Anjorin ṣe àyẹ̀wò DNA ọmọ rẹ̀?
- Ẹ wò àsọtẹlẹ tí Odumakin sọ nípa ìbejì tí ìyàwó rẹ̀ bí loṣù mẹ́fà tó jáde láyé
- Ọ̀pọ̀ ajìjàgbara Yorùbá Nation ló ń tan aráàlú jẹ láì sọ òtítọ́ - Seyi Makinde
Amọ iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ wi pe wọn tun ti ri eniyan meji miran gbe jade labẹ ile to wo naa.
Ajọ NEMA to ni awọn ṣiṣẹ fun akoko gbọọrọ ni alẹ ọjọ iṣẹlẹ naa ni awọn n gbọ ohun ni abẹ ile alaja to wo naa ni nkan bii aago mọkanla kọja diẹ ni alẹ patapata.

Bẹẹ si o fikun pe awọn ti da ala silẹ ni agbegbe ti awọn ti gbọ ohun naa, ti awọn si n gbiyanju lati ko awọn okuta ati irin nla nla to wa loke kuro , ki awọn le de ibi ti wọn wa.
''A n gbiyanju lati doola ẹmi wọn, ki a si de ibi ti wọn wa, ti a ti n gbọ ohun wọn''
Bakan naa ni o fikun pe awọn gba isinmi ranpẹ fun bii wakati kan si meji, ki awọn to pada si ẹnu iṣẹ idoola ẹmi awọn eniyan.
''Irọ ni LASEMA n pa, wọn ko ṣe iṣẹ kankan lati alẹ ana, wọn kan pariwo pẹlu ''siren'' lasan ni''

Amọ awọn mọlẹbi awọn ẹni to wa ni abẹ ile alaja to wo naa n fi apa janu gidigidi pe awọn oṣiṣẹ pajawiri ko gbiyanju to lati doola ẹmi awọn eniyan.
Ọkan lara awọn to fi ehonu rẹ han naa ni ariwo lasan ni awọn oṣiṣẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA n pa lati igba ti ilẹ ti mo nitori wn ko ṣe nkankan ni oru mọju.

''Ariwo lasan le n pa , ẹ ko ṣe iṣẹ kankan ni oru moju nitori kani ẹ ṣiṣẹ ni e o ti doola ẹmi awọn eniyan.''
''A fi siren nikan ni a n gbọ, aago meji ooru ni wọn ti kuro ni ibi iṣẹlẹ naa, wn kan n fun ipe kaakiri ni laiṣe nkankan.''

Omi inú ọ̀rá ní mo lọ rà, tí orí ṣe yọ mí níbi ilé tó dà wó - Ọlọ́pàá
Awọn eeyan to wa nibi ile alaja mọkanlelogun to wa ni opopona Gerrard, ni agbegbe Ikoyi, nipinlẹ Eko ko to wo lulẹ salaye bi ori ṣe ko wọn yọ.
O kere tan, awọn to wa nibi iṣẹlẹ naa ni eniyan ogoji lo wa ni inu ile alaja pupọ naa lasiko to wo.
Awọn to moribọ ninu iṣẹlẹ naa sọ ohun ti oju wọn ri lasiko ti ile naa sadede wọ to si da eeru.
Akọroyin BBC Yoruba to ṣabẹwo si ibi iṣẹlẹ naa jabo ohun ti awọn eniyan to jajabọ sọ.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
''Mọlẹbi mi to n mura lati lọ si oke okun wa ninu ile alaja to wo naa''
Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ọjọ Aje ni oun ati mọlẹbi oun wa si ile alaja pupọ naa nibi to ti wa ṣe ipade pẹlu awọn osisẹ to n sisẹ lọwọ.
Ibi ipade naa lo wa loke ile ọhun , ti ile naa fi sadede wo lulẹ, to si wa labẹ awoku ile naa.
Ọkunrin naa ni mọlẹbi oun naa lo n mura lati lọ si Ilẹ Gẹẹsi lasiko ti iṣẹlẹ naa waye, ti wọn si n woye bọya wọn le e doola ẹmi rẹ ni abẹ ile to ha si.

''Mopol ọlọpaa ṣa n sunkun ni pẹlu ibọn lọwọ''
Akọroyin BBC Yoruba ri ọlọpaa kan to duro amọ to n sun ẹkun kikan nibi iṣẹlẹ ile alaja pupọ to wo naa.
Amọ awọn eniyan to wa nibẹ lo sọ wi pe ori lo ko ọlọpaa naa yọ nitori awọn iyoku rẹ ti wọn jọ n ṣọ ibẹ, ti ha si abẹ ile to wo naa.
Wọn ni omi to fẹ mu ni ọlọ paa naa lọ ra, nigba ti yoo si fi de, ile ọhun ti da wo lulẹ, ti ọpọ awọn eeyan ti wọn dijọ n sọrọ tabi sere tẹlẹ, ti ha si abẹ ilẹ.
Ibanikẹdun awọn ekeji rẹ to ha sibẹ lo n gba omije ni oju rẹ, ti ko si le e dakẹ ẹkun, amọ ori ko oun yọ.

''Mo n ṣe ''german floor'' lọwọ ni ile naa bẹrẹ si ni wo, ti mo si tiraka yi kuro labẹ rẹ''
Ọkan lara awọn alagbaṣẹṣe to wa nibẹ lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni ori lo ko oun yọ nitori abẹ ile alaja pupọ naa ni oun wa, nigba ti o bẹrẹ si ni wo.
Oṣiṣẹ naa ni bi ile naa ṣe n wo bọ lati oke patapata wa si isalẹ nipele nipele, ni oun bẹrẹ si ni yi pẹlu gbogbo agbara oun kuro ni abẹ ile to n wo bọ naa.
Akọroyin BBC Yoruba ri pe ṣe ni gbogbo ara rẹ kun fun eruku lati oke de isalẹ amọ ori ti ko o yọ lọwọ ijamba na.
Amọ ohun ti ọpọ awọn ti ori ko yọ ninu iṣẹlẹ naa sọ ni pe awọn oṣiṣẹ pajawiri ko tete de sibi isẹlẹ naa lati doola ẹmi awọn eniyan.

Bá wo ní ilé alájà 21 ṣe wó ní Ikòyí? Ẹ ṣèwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní kíákíá - Sanwo-Olu yarí
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti paṣẹ iwadii ni kiakia lori bi ile alaja mọkanlelogun ṣe wo ni agbegbe Gerrard Road ni Ikoyi, nipinlẹ Eko.
Kọmiṣọnna fun ọrọ iroyin, Gbenga Omotoso lo fi eyi lede ninu atẹjade to fi ṣọwọ si awọn oniroyin.
Ile alaja mọkanlelogun naa lo wo le awọn eniyan lori amọ ti ko si ẹni to le e sọ pato iye awọn eniyan to wa ni inu ile alaja ti wọn ṣẹṣẹ nkọ naa ko to di pe o wo lulẹ.
Amọ, gomina Sanwo-Olu ni iwadii to ti bẹrẹ naa ni awọn yoo fi to awọn araalu leti lasiko to yẹ.
''A o ri pe awọn araalu mọ nipa iwadii iṣẹlẹ naa lasiko ti a ba pari rẹ.

Bakan naa ni wọn fikun pe igbakeji gomina nipinlẹ Eko, Obafemi Hamsat ṣe abẹwọ si ibi iṣẹlẹ naa lati ṣe moriya fun awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi.
Awọn ẹka ileeṣẹ pajawiri to fi mọ awọn oṣiṣẹ wọn lo peju pesẹ si ibi iṣẹlẹ naa lọna ati doola ẹmi awọn to wa ni abẹ ile to wo ọhun.
Ninu ọrọ rẹ, o ni eniyan mẹta ni wọn ti doola ẹmi wọn bi iṣẹ ṣe ti tẹsiwaju lati doola ẹmi awọn to wa nibẹ nigba ti ile naa wo.
Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu fi idi rẹ mulẹ pe wọn doola ẹmi eniyan mẹta, amọ o fikun pe awọn ti ri oku eniyan mẹrin gbe jade labẹ ile to wo naa.
Amọ ọkan lara awọn oṣiṣẹ alagbelebu pupa, Red Cross sọ fun akọroyin BBC Yoruba to wa nibi iṣẹlẹ naa pe oku eeyan marun un lawọn toi gbe jade.

Ẹyin oṣiṣẹ pajawiri, ẹ doola ẹmi awọn to wa labẹ ile to wọ ni kiakia - Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa ni aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti fi ikẹdun ranṣẹ si ẹbi ati ara awọn to padanu ẹmi wọn ninu ile alaja mẹ̀ọkanlelogun to wọ naa ni ipinlẹ Eko.
Ninu atẹjade ti olubadamọran pataki fun aarẹ, Femi Adesina gbe jade ni aarẹ ti ba ijọba ipinlẹ Eko ati mọlẹbi fun iṣẹlẹ ile to wo naa.
Aarẹ wa kesi awọn oṣiṣẹ pajawiri lati ri pe wọn doola ẹmi awọn to ha si abẹ ile naa ni waranṣesa.

Bakan naa lo paṣẹ fun awọn ileewosan lati ri pe wọn pese iranlọwọ to yẹ fun awọn ti wọn doola ẹmi wọn ni awọn ileewosan ti wọn ba gbe wọn lọ.
Aarẹ Buhari wa gbadura fun iranwọ Ọlọrun fun awọn eniyan ti wọn n gbiyanju lati doola ẹmi rẹ nibi iṣẹlẹ naa.
Titi di asiko yiii, ko tii si ẹni to le sọ pato nkan to mu ki ile alaja mọkanlelogun naa sadede wo lulẹ.
















