Yinka Odumakin kò parẹ́ :Lẹyìn oṣù kẹfà tó dágbére fáyé ìyàwó rẹ bí ìbejì

Aworan Joe iyawo Yinka Odumakin

Oríṣun àwòrán, @DrJoeOdumakin

Iroyin ayọ leleyi fawọn ara ọrẹ ati alabaṣe mọlẹbi agbẹnusọ ẹgbẹ Afenifere to jade laye,Yinka Odumakin.

Iyawo rẹ, Joe Odumakin la gbọ pe o ti bi ibeji lantilanti ni Amẹrika.

Joe, ẹni ọdun marunlelaadọta la gbọ pe o bi awọn ọmọ yi lẹyin oṣu mẹfa ti ọkọ rẹ jadelaye.

Loju opo rẹ ni Facebook to fi ikede yi si, o ṣalaye pe alaafia ni iya awọn ikoko yi ati awọn ikẹ mejeeji naa wa.

Joe sọ pe iṣẹ iyanu ni bibi awọn ọmọ yi jẹ nitori Yinka Odumakin ti n gbẹ oungbẹ pe ki awọn bi ọmọ mi ti wọn yoo sọ ni orukọ rẹ.

Ni ọdun mejidinlogun sẹyin lawọn tọkọtaya yi bi ọmọ kẹyin ti dide awọn ibeji ọkunrin ati obinrin yi si jẹ ayọ abaratintin fun mọlẹbi wọn.

Atẹjade to fi sita ṣalaye pe ''Iroyin ayọ ni pe Joe finu ṣoyun amọ ko ribi feti gbọ iro idunnu yi nitori pe iku yọ ọwọ rẹ lawo''

''Ṣugbọn o ti sọ aṣọtẹlẹ nipa iru orukọ awọn ọmọ yi ati bi a o ti ṣe wo wọn dagba''

Ni ọjọ Kẹta oṣu Kẹrin ni Yinka Odumakin dagbere faye.