Yinka Odumakin: Ẹbi akọwe iroyin ẹgbẹ Afenifere to di oloogbe kede eto isinku rẹ

Oríṣun àwòrán, Joe Odumakin
Ẹbi akọwe iroyin ẹgbẹ Afenifere to di oloogbe, Yinka Odumakin ti kede eto isinku rẹ.
Iyawo oloogbe naa, Ọmọwe Joe Okei-Odumakin lo kede eto isinku ọkọ rẹ ninu atẹjade kan to fi sita.
Ọmọwe Okei-Odumakin ni ọjọ mẹta ni eto isinku naa yoo fi waye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Á fojú Sunday Igboho balé ẹjọ́, á sì gba ₦500m owó ìtanràn fún Seriki - Ẹgbẹ́ Fulani
- Ọ̀rọ̀ agọ̀ ni Dambazau sọ bó ṣe fi OPC wé Boko Haram - Àgbààgbà Yorùbá
- Ọmọ yẹrí ẹ, èpè ń bọ̀! Kí ló dé tí Foluke Daramola bu èpè jólẹ̀ lórí ayélujára?
- Àlàyé rèé lórí ikú tó pa ọmọ Ronke Oshodi Oke
- Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú eré ìdárayá Squash fún àgbéga ìlera àti ọrọ̀ ajé rẹ
- Òjò owó ń rọ̀ fún abilékọ ẹlẹ́sẹ̀ kan tó n ta pure water lójú pópó
- Ẹ wo ìdí tí omije fi bọ́ lójú Pasuma níbi ìgbéyàwó ọmọ rẹ̀ obìnrin
- Ikọ̀ aláàbò Ebube Agu bẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ Igbo, tó túmọ̀ sí Amotekun
Aya oloogbe naa ṣalaye pe, Ọjọbọ ọjọ kejilelogun oṣu kẹrin ni eto orin imọyi fun oloogbe naa yoo waye ni ọgba ẹkọsẹ ọlọpaa, Police College, Ikeja, lati ago mọkanla aarọ si mẹrin irọlẹ.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹrin ni wọn yóò gbe oku oloogbe naa lọ si ilu abinibi rẹ ni Moro, ni ijọba ibilẹ Ariwa Ife, ipinlẹ Ọsun.
Aya oloogbe ni eto orin idagbere yoo fun oloogbe naa yoo waye ni ileewe girama ijọ Anglican ni Origbo ni ago marun un irọlẹ, pẹlu afikun pe eto titan abẹla lo kan lẹyin orin kikọ.
Ọjọ Abamẹta ọjọ kẹrinlelogun ni wọn yoo tẹ oku nitẹ ẹyẹ, ki awọn eeyan le ri i fun igba ikẹyin.
Ago mẹwaa aarọ Sátidé yii naa ni eto isin ikẹyin fun oloogbe Yinka Odumakin yóò waye, lẹyin naa ni iyoku ara rẹ yoo wọ kaa ilẹ lọ.

Àsọtẹ́lẹ̀ ikú Yinka Odumakin ti jáde sí wa tẹ́lẹ̀, ẹbí gbàdúrà, àmọ́...- Jacob Odumakin

Oríṣun àwòrán, Twitter/Omoyele Sowore
Iku ko da ọjọ, arun ko da oṣu, bẹẹ ni ko si ẹni to ri ti ọlọjọ ṣe bi o ba ti de.
Ọpọ eeyan to fi mọ awọn eekan lagbo oṣelu lo ti n ṣe idaro ajijagbara Yinka Odumakin to dagbere faye.
Ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ni Odumakin ki o to fi aye ẹṣẹ yii silẹ.
- Bí Joe àti Yinka Odumakin ṣe pàdé lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ti wọ́n sì fẹ́ra wọn láyé Abacha
- Dáa padà! Àwọn alátìlẹ́yìn Buhari fàdúrà jagun lòdì sáwọn tó ń fẹ̀hẹ́nùhàn lé e kúrò ní London
- Ojú wa rí, a ṣe IVF, oyún ìbeji bàjẹ́ kí á tó di ọlọ́mọ láyé- Adesua àti Banky W
- Àwọn òbìnrin tó ń ya fọ́tò ìhòhò ara wọn níwájú ilé kó sí gbaga ọlọ́pàá!
- Ìdí tí mo fi ṣe ìgbéyàwó ìdákọ́nkọ́ - Sotayo Gaga
Amọ, ẹgbọn oloogbe naa, Pasitọ Jacob Odumakin sọ fawọn akọroyin pe iran iku Yinka Odumakin ti jade tẹlẹ.
Pasitọ naa ṣalaye pe asọtẹlẹ to jade sọ pe kawọn gbadura ki igi tutu maa wo nigba ti igi gbigbẹ si duro.
Ẹgbọn oloogbe naa ṣalaye pe Yinka Odumakin ni igi tutu duro fun nigba ti baba rẹ to ti pe ọdun marundinlọgọfa si jẹ igi gbigbẹ.
O ni ẹbi ko bẹsu bẹgba lẹyin ti asọtẹlẹ yii jade lawọn bẹrẹ si ni gbadura.
Amọ pasitọ Jacob ni ẹlẹmi pada gba a nitori ko si ẹni to ti ti ọlọjọ ṣe.
O ni ibanujẹ nla ni iku Yinka jẹ fun idile awọn papaa julọ rẹ to di darugbo.
Arun coronavirus ni a gbọ pe o pada ṣeku pa Odumakin lẹyin ti ko le mi mọ daadaa.
Ẹgbọn oloogbe ọhun tun sọ pe ẹgbẹ Afenifere ti sọ pe awọn lawọn yoo ṣe oku Odamakin to jẹ akọwe ẹgbẹ Yoruba naa.

















