Squash: Dele Oladejo ní eré ìdáráyá náà yóò pèsè iṣẹ́ àti owó fáráàlú

Ni orilẹede Naijiria, ọpọ eeyan ni ko mọ nipa ere idaraya miran mọ yatọ si ere bọọlu, eyi to lokiki yika aye.
Ọpọ eeyan ni ko si mọ pe ere idaraya ẹlẹyin ti wọn n gba mọ iganna, "Squash", jẹ ọkan gboogi lara awọn ọna ti awọn orilẹede to ti goke agba l'agbaye fi n se agbega eto ilera ati ọrọ aje wọn.
Bo tilẹ jẹ wi pe ere idaraya naa ko ti i fi bẹẹ wọ pọ ni orilẹede Naijiria, amọ awọn akọṣẹmọṣẹ nipa ere idaraya Squash kan ti ṣe alaye fun BBC Yoruba wi pe, orisun ọrọ ati ilera pipe ni ere idaraya naa, ti a ba le kọ ibi ara si i.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àlàyé rèé lórí ikú tó pa ọmọ Ronke Oshodi Oke
- Òjò owó ń rọ̀ fún abilékọ ẹlẹ́sẹ̀ kan tó n ta pure water lójú pópó
- Ẹ wo ìdí tí omije fi bọ́ lójú Pasuma níbi ìgbéyàwó ọmọ rẹ̀ obìnrin
- Ikọ̀ aláàbò Ebube Agu bẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ Igbo, tó túmọ̀ sí Amotekun
- Agbára ahọ́n ta fi n pe ara wa ní olóríire ló jẹ́ ká gba ẹ̀bùn ilé - Olorì Aláàfin méjì
- Ẹ̀tanú ní kó jẹ kí wọ́n gbé ipò ààrẹ fún MKO Abiola - Obasanjo
- Alaafin kọ́lé tuntun fún ọ̀kan lára Olorì rẹ̀ ní Ibadan, ariwo sọ
- Davido, Pasuma àti Yinka Ayefele dábírà lópin ọ̀sẹ̀, aráyé múgbe bọnu
- Yorùbá sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Arewa lórí bó ṣe fẹ́ àtúntò Nàíjíríà àmọ́ tó tako pínpín ipò ààrẹ
Agba ọjẹ ninu ere idaraya naa, Dokita Oludele Oladejo ṣe alaye wi pe ijọba gbọdọ wa ọna lati gbe ere idaraya naa larugẹ nitori pe o le ṣe anfani to pọ fun ọrọ aje aladani ati fun orilẹede l'apapọ.

Dele Ọladejo si lo se agbatẹru idije Squash nilu Ibadan laipẹ yii fawọn ọjẹ wẹwẹ elere idaraya naa ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹtala si mẹtadinlogun.
Dokita onisegun oyinbo naa ni, "Ere idaraya Squash jẹ eto ọrọ aje lọna tiẹ nitori pe fun awọn to n gba a, iṣẹ aṣejere ati aṣelowo ni.
Awọn ti yoo ma a mojuto akoso ere idaraya naa, iṣẹ lo jẹ fun awọn yẹn pẹlu.
Ijọba gan yoo maa gba owo ori lọwọ awọn oṣiṣẹ tabi lọwọ awọn to n gba Squash, to ba di ere idaraya nla".

Oladejo ni ere bọọlu ti wọn n gba mọ iganna yii, iyẹn "Squash" ki i ṣe ere idaraya lasan nitori ojulowo iṣẹ oojọ to n fun ni lokun, to si tun le mu ọpọlọpọ owo wọle ni.
O parọwa si awọn obi ati ijọba lati fun awọn ọmọ lanfani kikopa ninu ere idaraya naa nitori pupọ ọmọde ni yoo fakọyọ, ti wọn ba fun wọn ni anfani lati se ere idaraya naa.
O fi kun ọrọ rẹ pe "ijọba ni lati wa ọna to fi jẹ pe gbogbo awọn ere idaraya wọnyii ni yoo jẹ gboogi ohun ti wọn n na owo le.

Bakan naa ni ki wọn fi anfani silẹ fun awọn akọṣẹmọṣẹ to n kọ ọmọ nipa awọn ere yii lati lọ kọọ nibi ti o yẹ, nitori pe ere ti o wa nibẹ kọja nnkan ti a ro".
Lẹyin idije ere idaraya Squash to waye ni ibudo igbafẹ Recreation Club nilu Ibadan naa ni wọn ti pin oniruuru ẹbun fawọn ọmọ to fakọyọ lọkunrin ati lobinrin, ninu idije naa.
Bakan naa ni ọmọkunrin meji, ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa gba ẹbun ẹkọ ọfẹ titi de ile ẹkọ giga fasiti eyi ti apapọ awọn elere idaraya Squash to wa nibudo igbafẹ Recreation Club nilu Ibadan se agbatẹru rẹ.













