Ronke Oshodi Oke: Ronke Oshodi Oke ṣe ìdárò ọmọ rẹ̀ tó di olóògbé

Kíló pa ọmọ Ronke Oshodi Oke?

Oríṣun àwòrán, Ronke oshodioke

"Ọmọ mi ọ̀wọ́n, àkọ́bi mi, ọ̀rẹ́ mi àti gbogbo ǹkan ti mo ni, Oluwabunmi Akinleye ọdun kẹwàá rèé tí o ti fi mi sílẹ̀"

Èyí ni ọ̀rọ̀ idaro ti gbajúgbajà òṣèré tiata, Ronke Ojo tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Ronke Oshodi Oke kọ nipa ọmọ rẹ̀ tó di olóògbé.

Ronke Ojo ló gbé fótò ọmọ rẹ̀ síta pé, ó ti le ni ọdún mẹ́wàá tí ikú ti wọle mú àkọ́bí òun lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Láti àsìkò yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn olọ́lùfẹ́ Ronke Ojo ti fọ́n sórí ayélujára láti ba kẹ́dun ikú ọmọ rẹ̀ tó d'olóògbé.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ronke Oshodi Oke kò sọ ǹkan tó ṣokùnfa ikú ọmọ náà, sùgbọ́n ìwé ìròyìn kan sọ pé àìsàn jẹjẹrẹ inu egungun ló paá.

Nollywood: Kíló pa ọmọ Ronke Oshodi Oke?

Oríṣun àwòrán, Ronald Grant

Ẹni kan tó fẹ́ ká forúkọ bo òun láṣírí sọ pé, ẹni ọdún mọ́kàdínlọ́gbọ̀n ni Bunmi lásìkò tó papò dà, tó si máa n ṣe bi amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fún Ronke Ojo lásìkò náà.

Ìròyìn náà fi kun pé, tí ènìyàn bá ri bi ọmọbinrin náà ṣe sún mọ́ òṣèré náà tó, ọ̀pọ̀ ni yóò rò pé, ọmọ tàbi àbúrò rẹ̀ ni lóòtọ́.

Wọn ni ní ǹkan bi ọdún mọ́kànlá sẹ́yìn ni Bunmi ni ààrun jẹjẹrẹ inú egungun, èyí sì ló mú kí ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré tíátà lásìkò náà bẹ̀rẹ̀ ìpolongo láti kówó jọ fún, kí wọn le gba ẹ̀mí rẹ̀ là.

Olubunmi ati Ronke Oshodi Oke

Oríṣun àwòrán, ronkeoshodioke/Instagram

Àṣẹ̀yìn wá àṣẹ̀yìn bọ̀, Bunmi ko rí ìjà náà jà lájàyè, tó sì gbé ẹ̀mí mì lọjọ kọ̀kanlá oṣù kẹrin ọdún 2011 ni ilé ìwòsàn UCH Ibadan, níbi tó ti ń gba ìtọ́jú.

Ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ Ronke Ojo ló n ṣeléde lẹ́yìn ọmọ náà, díẹ̀ lára ìkíni wọn rèé.

Kíló pa ọmọ Ronke Oshodi Oke?

Oríṣun àwòrán, Ronke oshodi

Kíló pa ọmọ Ronke Oshodi Oke?

Oríṣun àwòrán, Ronke Oshodi oke

Kíló pa ọmọ Ronke Oshodi Oke?

Oríṣun àwòrán, Ronke Oshodi oke