Ronke Ojo àti Toyin Lawani: Ó dára kí obìnrin níṣẹ́ lọ́wọ́

Àkọlé fídíò, Ó dára kí obìnrin níṣẹ́ lọ́wọ́ - Toyin Lawani

Ronke Ojo, ti ọpọ eeyan mọ si Ronke Oshodi Oke ati Toyin Lawani ba BBC sọrọ lori ipa to yẹ ki obinrin maa ko ninu ile.

Awọn mejeeji fẹnuko pe o dara ki obinrin niṣẹ lọwọ ko ma ba a jẹ ajaga fun ọkọ rẹ.

Ronkẹ ni oun gbagbọ pe okunrin to lee ṣe awọn ojuṣe ti awọn ọkunrin maa n ṣe laye atijọ ṣọwọn laye ode oni.

Bẹẹ na lo tun gba awọn okunrin ni imọran lati maa ni suuru fun awọn iyawo wọn ti iṣẹ wọn gbomi mu.

Ni ti Toyin Lawani, o ni ohun to dara ni ki okunrin ṣe atilẹyin fun iyawo rẹ ninu iṣẹ to ba n ṣe nitori ọjọ iwaju.

Bẹẹ naa lo tun sọ pe kii ṣe ohun to bojumu ki ọkunrin jẹ alapa ma ṣiṣẹ ti yoo maa reti ki iyawo rẹ maa bọ ọ.

Ẹkunrẹrẹ ohun ti awọn mejeji sọ wa ninu fidio yii.