Ebube Agu: Àwọn gómìnà Igbo ṣàgbékalẹ̀ ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ aláàbò tuntun

Amin idamọ ikọ alaabo Ebube Agu

Oríṣun àwòrán, Ft. Dj Benkraft

Awọn gomina ni Guusu ila oorun Naijiria ti korajọ lati ṣagbekalẹ ikọ alabo kan ti wọn pe orukọ rẹ ni "Ebube Agu" lọna ati gbogun ti iwa ọdaran to n peleke sii lagbegbe naa.

Alaga ẹgbẹ awọn gomina ọhun, Dave Umahi lo kede agbekalẹ ikọ naa lẹyin ipade kan ti oun atawọn akẹgbẹ rẹ ṣe niluu Imo.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, olu ọọfisi ikọ naa yoo wa ni ipinlẹ Enugu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu atẹjade to fi lede lẹyin ipade naa, Umahi sọ pe ikọ ọhun yoo tun maa dari iṣẹ awọn fijilante agbegbe naa.

O ni "lẹyin ipade pẹlu awọn gimina atawọn ti ọrọ kan nipa ti eto abo ni iha Guusu ila oorun Naijiria, a ti fẹnuko lati gbogun ti iwa ọdaran ati iwa iṣẹrubalu ni Naijiria, paapaa lagbegbe wa."

"Bẹẹni a tun bu ẹnu atẹ lu bi awọn ọdaran kan ṣe n dana sun agọ awọn ọlọpaa ati ọgba ẹwọn, ti wọn si n tu awọn ẹlẹwọn silẹ."

Awọn gomina ilẹ Igbo

Umahi fi kun pe digbi ni gbogbo ipinlẹ marun to wa ni iha Guusu ila oorun Naijiria wa lẹyin ijọba apapọ lori eto abo, ati pe gbogbo igbesẹ ti ijọba apapọ ba fẹ gbe lati kọju ija si awọn ọdaran lawọn yoo tẹle.

O ṣalaye pe gbogbo awọn oloṣelu nilẹ igbo ti fẹnuko lati fi imọ ṣọkan lori awọn aṣẹrubalu, wọn si ti pinnu lati kọju ija si awọn eeyan naa labẹ asia kan naa.

Awọn gomina ọhun tun ke si ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa lati gba awọn kọmiṣọna ọlọpaa laaye lati maa ṣiṣẹ wọn bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ dipo ko maa ran awọn eeyan kan wa lati Abuja lati maa bẹ iṣẹ wọn wo.

Àkọlé fídíò, Female Car Painter: Èmi ní obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò máa ṣiṣẹ́ akunmọ́tò ní Ibadan

Wọn tun fẹnuko pe awọn ti gbẹsẹle bi awọn daradaran ṣe maa n da ẹran kaakiri aarin ilu.

Atẹjade naa pari pe ki ibaṣepọ to dan mọran wa laarin awọn agbẹ atawọn to n si maalu.

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori ikede ikọ ẹṣọ alabo tuntun naa.