Prince Philip: Ìsìn ìrántí wáyé fún Duke ti Edinburgh níjọ Canterbury Cathedral

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ayẹyẹ ìsìn ìrántí wáyé lónìí fún Duke ti Edinburgh ní ilé ìjọsin Canterbury Cathedral, bi ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì ṣe wà nínú ọ̀fọ̀ ikú ọmọọba Philip.
Bísọ́ọ̀bù Canterbury Justin Welby, ni wọn ni ó ṣeeṣe ko ṣètò ìsìnkú lọ́jọ́ sátide tó n bọ̀.
Aṣojú ìjọba ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì nígbà kán rí Sir John Mayor, tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Duke ní òun ni ìgbágbọ́ pé àwọn ènìyàn yóò gba ọbabinrin láàyè láti ṣọ̀fọ̀.
- Ọlọ́lajùlọ Duke ti Edinburgh papòdà
- Ẹ wo àwòrán bí wọ́n ṣe yìbọn sókè káàkiri Ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì láti ṣẹ̀yẹ Duke ti Edinburgh
- Prince Philip: Irú ènìyàn tó jẹ́, àwọn nkan tó gbé ayé ṣe àti ìdí tó fi ṣe pàtàkì
- Wo ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn Ààrẹ́ Buhari àtàwọn èèkàn ọmọ Nàìjíríà míì sí Ọbabìnrin Elizabeth fún ìpapòdà ọkọ rẹ
- “Ọnku Phillip wa tòótọ́” Gbogbo àgbáyé ránṣẹ́ ìbánikẹ́dùn
- Ìgbé ayé Ọmọba Phillip nínú àwòrán
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú Andrew Marr , ó sàlàyé pé jíjẹ́ olórí ìlú jẹ́ ipo àdáwà fúnra rẹ̀, Duke tó tún jẹ́ aláfọ̀rọ̀lọ̀ rẹ̀ ló tún wá lọ yìí.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Prince Philip ti lọ síbẹ̀, ọbabinrin kò le gbàgbé rẹ̀ yóò túbọ̀ dàbí pé wọ́n jọ jòkó sẹ́gbẹ́ ará wọn.
Sir John yìí bákan náà ni alábojútó Duke ti Cambridge ati ti Sussex lẹ́yìn ti ìyá wọ́n kú, ó ni òun ni ìgbàgbọ́ pé, àwọn arákùnrin rẹ̀ tókù yóò lo àsìkò yìí, láti fi pari gbogbo aáwọ̀ tó wà láàrín wọn.

Bí ètò ìsìnkú yóò ṣe lọ ní Ọjọ̀ Satide, April 17

Oríṣun àwòrán, PA Media
Ile ọba ni Ilẹ Gẹẹsi ti fi alakalẹ lede bi etò ìsìnkú ọmọọba Philip tó jẹ́ ọkọ Ọbabirin Elizabeth ẹlẹ́ẹ̀kejì yoo ṣe lọ ni Ọjọ kẹtadinlogun, Osu Kẹrin, ọdun 2021
Ẹni ọdún mọ́kàndílọ́gọ́rùn ní Duke ti Edinburgh, Philip to dagbere fun aye ni Ọjọ kẹsan, Osu Kẹrin, ọdun 2021.
Gbogbo bí ètò òkú yóò ṣe lọ ni wọn ti sọ di mímọ̀ pẹ̀lú ayẹyẹ ránpẹ́ , yàtọ̀ sí irú àyẹyẹ ńla tí wọ́n máa ń ṣe tí ọbá bá kú.
Awọn ẹbi nikan yoo wa ni ibi ayẹyẹ isinku naa, nitori isinku ile ọba ni, kii ṣe ti Ilẹ Gẹẹsi.
Aado mẹta(15:00 BST) ni isinku naa yoo bẹrẹ ti wọn yoo si ṣe afihan rẹ jakejado agbaye ni ori ẹrọ amohunmaworan.
Awọn ẹbi ati ara ni isinku naa yoo safihan akikanju ọkunrin ti ọmọọbakunrin naa jẹ nigba aye rẹ.
Bakan naa ni Ọbabinrin Elizabeth ti buwolu eto isinku naa.
Bi eto isinku naa yoo ṣe lọ niyii;
- Awọn ẹbi ọba ni yoo tẹlẹ posi ọku ọba naa pẹlu ọmọọbakunrin Wales, ti yoo rin lẹyin posi Duke ti Edinburgh naa
- Eto isinku naa yoo waye ninu ijọ George ni Afin Windsor,
- Ọbabinrin Elizabeth yoo wa ninu ọkọ ti yoo gbe e lọ si ile ijọsin ti eto isinku naa yoo ti waye,
- Iṣẹju mẹjọ ni irin yoo gba pẹlu awọn agboku mẹjọ ti yoo gbe posi naa lọ si ẹnu ọna ile ijọsin naa,
- Dean ti Windsor ati Archbishop ti Canterburty ni yoo gba oku naa wọle si ile ijọsin eto isinku naa,
- Awọn agboku ati Dean pẹlu Archbishop ko si lara awọn eniyan ọgbọn ti yoo peju pese si ibi isinku naa,
- Ọmọọbakunrin, Duke ti Sussex yoo wa ni ibi isinku naa, amọ iyawo rẹ, Meghan ko ni le e lọ nitori ipo iloyun to wa,
- Gbogbo orilẹede naa yoo palọlọ ni aago mẹta ọsan,ki isin isinku naa to bẹrẹ,
- Itẹ igbokusi, Royal Vault ni wọn yoo sin Duke ti Edinburgh, Philip si lẹyin isin isinku rẹ.

Kíni ǹkan tó kù báyìí?
Ìjọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti kéde pé àsíá orílẹ̀-èdè náà yóò wá sílẹ̀ ni gbogbo àwọn ilé isẹ́ ìjọba jákèjádò láti aago mẹ́jọ lẹ́yin ọjọ́ keji ìsìnkú.

Oríṣun àwòrán, EPA
Láti buyì fún ọmọọba Philip, àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú méjì to gbajúgbajà jùlọ ni ilẹ̀ gẹ̀ẹ̀sí Scotland àti Wales ti dáwọ́ ìpolongo ìbò tí ó yẹ kó wáyé ni oṣù tó n bọ̀ duro.
Ilé aṣòfin yóò jòkó lọ́jọ́ Ajé láti ṣe ìkíní ìkẹyìn fún Duke ti Edinburgh.
Ètò gbèdékè tí wọ́n gbé lé ará ilú láti maa péjú síbi ti ọ̀pọ̀ ènìyàn to ti wa nilẹ ni wọ́n ti ṣe àwọn àtúnṣe sí ni àwọn ọjọ́ tó kù fẹ̀r kí ayẹyé ètò ìsìnkú wáyé àti ni àsìkò ayẹyẹ ìsìkú gan.
Wọ́n ti gba àwọn ará ìlú nímọ̀ràn láti má pejú síbi ayẹyé ìsìnkú náà gẹ́gẹ́ bi àjọ tó n mójú to ètò ààbò ṣe sọ.
Bákan náà ni ilé ọba ti rọ àwọn ará ìlú láti ma fi òdòdó kankan sí ilé ọba, bí kò ṣe ki wọ́n lọ má a fún àwọn ọmọ aláìní ni ẹ̀bùn lórúkọ Duke ti Edinburgh. Wọ́n fi kun pé wọ́n le fi ìwé ìkíni wọ́n ránṣe lórí iwé ìkíni to wa lórí ayélujára


Àwọn wo ni yóò péjú sí ibi ayẹyẹ ìsìnkú náà?
Gẹ́gẹ́ bi ètò ti ó yé kí ó wáyé lẹ́yìn ikú ọmọọba Duke èyí ti àpèjẹ́ rẹ̀ jẹ́ "Forth Bridge" ẹgbẹgbẹrun àwọn ènìyàn ló yé kí ó péjú sí London àti Winsdor, tí àwọn míràn pẹ̀lú yóò wá ọ̀ọ̀kán dúró sí kí wọ́n le ni ànfàni láti wo bí àwọn ológun yóò ṣe gbé òkú.
Ọgọ́rùn àwọn ọmọ ogun pẹ̀lú ni yoo tò sí òpópónà láti bu ọlá fún Duke.
Sùgbọ́n láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ ààrùn yìí ti bẹ̀rẹ̀, àwọn tó n ṣagbátẹrù ètò náà tí n ṣiṣẹ́ lórí ọ̀nà bi kò 'se ni sí èrò púpọ̀ níbi ayhẹyẹ òkú náà.
- Kíni ìdí tí BBC fi ma ń gbé ìròyìn nípa ikú àwọn kan nínú ẹbí Ọba ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́?
- Gbajúgbajà akọrin takasúfè nílẹ̀ America, DMX ti jáde l'áyé
- Ìlẹ̀kẹ̀ otútú ọgbọ̀n, Ìrọ́kẹ́, àwa ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ náà fẹ́ káwọn ọmọ wa máa wọ lọ sílé ìwé - Elebuibon
- Àwọn ọmọ ìjọ RCCG mẹ́jọ tó bọ sí ọwọ́ ajínigbé ní Kaduna ti gba òmìnira
- Àrà kengé! Ṣọ́ọ̀ṣì Church of England fẹ́ dá ère idẹ Benin méjì padà sí Nàìjíríà
Ní báyìí Ọbabinrin ń rọ bi àyípada yóò ṣe bá ètò ayẹyẹ ìsìnkú pàápàá jùlọ lórí ìkìlọ ìjọba àti ètò ìjìnà síra ẹni.
Ìgbàgbọ́ ni pé wọ́n yóò gbé òkú ọmọọba Philip sí ibusọ̀ kékeré lọ sí St George's Chapel fún ètò ìsìnkú lọ́jọ́ ìsìnkú.
















