Prince Phillip: Àwọn aṣíwájú lágbáyé ránṣẹ́ ìbánikẹ́dùn

Arẹmọ Philip wa ninu kẹẹkẹ pẹlu Ayaba Spain, Letizia ni London lọ̀dun 2017

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Arẹmọ Philip wa ninu kẹẹkẹ pẹlu Ayaba Spain, Letizia ni London lọ̀dun 2017

Awọn lọbalọba, olori orileede ati olotu ijọba gbogbo kariaye ni wọn ti n ranṣẹ ibanidaro lori iku Arẹmọ Phillip, Duke of Edinburgh ti ilẹ Gẹẹsi to jade layelẹni ọdun mọkandinlọgọrun.

Ọba orilẹede Spain ati aya rẹ tẹ iwe ranṣẹ si Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi ri wọn pe ni "Dear Aunt Lilibet" lori iku ọkọ rẹ ti wọn pe ni " Dear Uncle Phillip"

Yatọ si lọbalọba ilẹ Yuroopu to daro, awọn orilẹede ro wa labẹ igbimọ aṣepo Commonwealth naa kan sara si igbe aye ifaraẹnijin ti Arẹmọ Phillip gbe nigba aye rẹ loke erupẹ.

Igbe aye imurasi ojuṣeeni, ifọkansin ati ijolootọ si Ọbabinrin ilẹ gẹẹsi kun ara awọn ohun manigbagbe tawọn aṣiwaju orilẹede agbaye naa yombo lara Arẹmọ Phillip.

Ni ọjọ Ẹti ni aafin Buckingham kede ipapoda Arẹmọ Phillip ẹni to fi ọpọ igba ba Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi rinrinajo kaakiri agbaye.

Ọpọlọpọ awọn lọbalọba ilẹ Yuroopu lo ba Arẹmọ Phillip tan ni ọna kan tabi omiran bẹẹni pupọ wọn lo ti n fi ọrọ ibanikẹdun wọn ranṣẹ.

Atẹranṣẹ Ọba Felipe ati aya rẹ Letizia ti Spain da yatọ ninu eyi ti wọn ti kọ ọ wi pe " ifẹ ati idaro wa wa pẹlu Aunt Lilibet (eyi ni orukọ ifẹ ti Arẹmọ Phillip maa n pe aya rẹ Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi) ati Uncle Phillip wa tootọ.

Wọn so fun Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi ninu atẹranṣẹ wọn pe, "A ko le gbagbe awọn akoko ti a jọ wa pọ pẹlu rẹ pẹlu ogun isojuṣe ẹni ati ifaraẹnijin fun Ọba ati ilẹ Gẹẹsi nigba to wa pẹlu rẹ"

Ọba Carl.ti Sweden

Ọba Sweden, Carl Gustaf ati iyawo rẹ, Olori Silvia naa ranṣẹ ibanikẹdun

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ọba Sweden, Carl Gustaf ati iyawo rẹ, Olori Silvia naa ranṣẹ ibanikẹdun

Ọbalaye orilẹede Sweden, Carl Gustaf pẹlu ṣedaro ninu eyi to ti ni Arẹmọ Phillip jẹ "ọrẹ gidi fun ẹbi wa fun ọpọlọpọ ọdun, eleyi ti a ko ṣai mọ riri rẹ."

Agbẹnusọ fun ile Ọba orilẹede Sweden, Margareta Thorgren ṣalaye fun BBC pe ọba orilẹede Sweden ati Arẹmọ Phillip ti jumọ rinrinajo ojuomi ri ni ilẹ Gẹẹsi leyi to ni o jẹ ibẹrẹ jrinajo ọrẹ gidi laarin wọn"

Ile ọba orilẹede Holland ni awọn n ṣeranti Arẹmọ Phillip pẹlu ọwọ, pẹlu afikun pe : " O fi igbe aye rẹ jin fun sinsin awọn eeyan ilẹ Gẹẹsi ati ọpọlọpọ ojuse rẹ. O jẹ ọloyaya eeyan toi iṣe rẹ ni ipa lokan awọn to baa pade."

Ninu ọrọ tiwọn, Ọba Phillipe ti orilẹede Belgium ati olori rẹ, Mathilde ni awọn "yoo maa fi igba gbogbo ṣeranti awọn ajọṣepọ wọn pẹlu rẹ".

'Opomulero fun Ọbabinri ilẹ Gẹẹsi'

Philip ati Elisabẹti ni New Zealand, lọdun 1977.
Àkọlé àwòrán, Philip ati Elisabẹti ni New Zealand, lọdun 1977. Ọpọlọpọ awọn ibanikẹdun to munadoko wá lati inu ajọ Commonwealth

Awọn ọrọ ibanikẹdun wa lat'ọdọ awọn orilẹede mẹrinlelaadọta to wa labẹ ajọ Commonwealth pupọ ninu wọn to ti ni ipilẹ pẹlu ijọba ilẹ Gẹẹsi pẹlu awọn eeyan to le ni biliọnu meji.

Olotu ijọba orilẹede Australia sọ ninu atẹjade kan pe: " O duro fun iran kan ti a ko ni ri iru rẹ mọ."

O kan sara si Arẹmọ Phillip gẹgẹ bii baba isalẹ ọpọlọpọ ẹgbẹ ati lajọlajọ ni Australia.

Ọrọ lati ẹnu Olotu ijọba New Zealand, Jacinda Adern fara pẹẹ.

O ni " O ni ọpọlọpọ awọn ọdọ lo ti bori oniruru ipenija aye wọn" nipasẹ eto ami ẹyẹ Hillary Award ti Arẹmọ Phillip gbe kalẹ.

Justin Trudeau, olotu ijọba orilẹede Canada ni Arẹmọ Phillip" ko ipa to pọ ninu idagnoke awujọ lorilẹede wa- ati lagbaye".

O fi kun pe: " Arẹmọ Phillip jẹ ọkunrin takuntakun to ni ifọkansin ati afojusun to n se koriya fun un lati ṣiṣẹ sin awọn eeyan miran.

"A n ṣeranti rẹ gẹgẹ bi opomulero ninu aye Ọbabinrin wa."

Bakan naa ni Olotu ijọba orilẹede India, Narenda Modi kun awọn to yombo igbe aye ifaraẹnijin Arẹmọ Phillip fun " ọpọlọpọ iṣe isinlu"

Aarẹ Uhuru Kenyatta ti orilẹede Kenya sọ pe Arẹmọ Phillip jẹ " ami nla gagara fun idagnasoke idile ati iṣọkan awọn eeyan ilẹ Gẹẹsi ati gbogbo agbaye lapapọ" - ọkunrin to ṣiṣẹ fun "ibagbepọ alaafia laarin ọmọniyan".

Awọn ọrọ ibanikẹdun miran to run wa.lati ilẹ Afirika kan ti orilẹede Zimbabwe- to ni ọpọlọpọ edeaiyede pẹlu ilẹ Gẹẹsi, tiko si si lawujọ awọn orilẹede Commonwealth mọ- ati aarẹ orilẹede Tanzania to padanu olori rẹ, John Magufuli, laipẹ yii.

'A o ṣafẹri iranti rẹ'

Duke ilu Edinburgh pẹlu iya rẹ, Ọmọọbabinrin Alice ti Battenberg

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Duke ilu Edinburgh pẹlu iya rẹ, Ọmọọbabinrin Alice ti Battenberg

Awọn ọrọ ibanikẹdun miran tun wa lati ọdọ awọn orilẹede to ni Ajosepo to rinlẹ pẹlu Arẹmọ Phillip ati idile rẹ.

Olotu ijọba orilẹede Malta, Robert Abela ni: "ibanujẹ nlanla ni iku Arẹmọ Phillip, to fi orilẹede Malta ṣe ile to si maa n wa si ibẹ lọpọ igba. Awọn eeyan wa n ṣe afẹri iranti rẹ."

Odun meji ni Phillip ati Elizabeth lo ni orilẹede Malta gẹgẹ bi omoogun oju omi ki Ọba George karun to jade laye lọdun 1952.

Olotu ijọba orilẹede Israel, Benjamin Netanyahu ni Arẹmọ Phillip jẹ "oṣiṣẹ ilu to mu iṣẹ rẹ lọkunlundu , orilẹede Israel ati agbaye ni yoo si maa ṣe afẹri rẹ".

Ileejọsin Church of Mary Magdalene to wa ni ilu Jerusalemu ni wọn sin Arẹmọ Phillip, omoobabinrin Alice ti Battenberg to ku lọdun 1969

Arẹmọ Philip tẹle Ọbabinrin lọ si ọpọlọpọ irinajo.

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Arẹmọ Philip tẹle Ọbabinrin lọ si ọpọlọpọ irinajo. Wọn wa pẹlu George W Bush ati iyawo rẹ, Laura, ni Washington lọdun 2007

Ninu ibanidaro tirẹ, aarẹ Amẹrika nigbakanri, George W. Bush kan sara si iwa ọmọluabi rẹ, to si ni Arẹmọ Phillip gbe "igbe aye to to si fi ami lelẹ" to si ni "ifaraẹnijin fun awọn iṣẹ rere ati fun awọn eeyan miran".

Minisita ọrọ ilẹ okeere lorilẹede France, Jean-Yves Le Drian kasẹ ọrọ ikẹdun ati idaro gbogbo nilẹ- pẹlu pipe Arẹmọ Phillip ni okunrin "to ṣe ara ọtọ".

"Orilẹede France darapọ lati daro awọn ọrẹ rẹ ati lati yombo igbe aye ọkunrin kan to jẹ ẹlẹri si oniruru ipenija ati ireti fun ilẹ Yuroopu."