Benin Bronze sculptures: Ṣọ́ọ̀ṣì Church of England fẹ́ dá ère idẹ Benin méjì padà sí Nàìjíríà

Ere

Oríṣun àwòrán, Woolley and Wallis

Ara kii tan nile alara. Adifa fun ile ijọsin Church of England to fẹ da ere idẹ meji ilu Benin pada si Naijiria.

Ṣọọṣi naa ni ẹbun ni wọn fi awọn ere naa ṣe fawọn lorilẹede Naijiria ni bii ogoji ọdun sẹyin.

Church of England wa lara awọn ajọ to fẹ da awọn ere Naijiria ti ilẹ Gẹẹsi gbe lọ si Yuropu pada.

O ti le ni ọgọrun ọdun ọdun ti ilẹ Gẹẹsi fi tipa ko awọn ere yii lati Naijiria lọ si ilẹ Yuropu laye ijọba amunilẹru.

Koda wọn tun ta pupọ lara awọn ere naa sawọn ile iko nkan isẹnbaye si kaakiri ilẹ Yuropu.

Laipẹ yii lawọn alaṣẹ ile iko nkan isẹnbaye si niluu Berlin lorilẹede Germany pinnu lati da ọpọ ere ti gbe lati Naijiria pada.

Ijọba Benin wa lara awọn to gbogun to fija pẹta pẹlu awọn oyinbo akonilẹru nigba ti wọn fẹ ko orilẹede Naijiria lẹrin laye igba naa.

Babalawo lo le mo òun ti yóò gbẹyin ọ̀sándòru

Benin naa si ni ọpọlọpọ nkan isẹnbaye pọ si lati aye atijọ titi di asiko yii.

Ere ilu Benin kan tiẹ wa ti wọn ta ni owo to le ni miliọnu marun naira(5,215,984,000) tii ṣe £10m.

Àkọlé fídíò, Torí àti ṣe Kòkò irin, bí mo ṣe máa ǹ fara yá iná nìyìí - Amokoko Saki