Antonio Oladeinde Fernandez: Ìtàn ìgbé ayé ọmọ Naijiria to ni ọkọ̀ òfúrufú mẹ́fà àti owó ní báǹkì láwọn orílẹ̀-ède méje

Oríṣun àwòrán, @solotufe
Oloye Antonio Oladeinde Fernandez jẹ ọkan pataki ninu awọn baba olowo orilẹ-ede Naijiria ati ọkan lara awọn eyan to lowo julọ nilẹ adulawọ nigbaa aye rẹ.
O ni owo to bẹẹ gẹ, to fi ni ọkọ ofurufu mẹfa funra rẹ, o ra ile awodamiẹnu kan lorilẹ-ede France ti Napoleon Bonaparte ti gbe ri, koda, to ba fẹ jẹun nile ounjẹ, niṣe ni wọn maa n ni ki gbogbo awọn to ba wa nibẹ jade fun un.
- Wọ́n ti kéde òkú ọdọ̀kùnrin tí wọ́n rí nínú adágún omi ní UK gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàìjíríà
- Owó àti dúkìá Dongote, Adenuga àti Rabiu tún yarọ síi pẹ̀lú $5.7bn- Forbes
- Ẹni ọdún 21 di ọ̀dọ́mọ́dé tó lówó jùlọ lágbàáyé
- Ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé níbi ìsìnkú Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó tó kú lẹ́ni ọdún 36
- Àwọn olówó Naijiria 5 tí owó wọn ju owó ìsúnná Naijiria lọ!
- Ǹjẹ́ o ti gbọ́ nípa Da Rocha? Olówó yalumọ àkọ́kọ́ nílẹ̀ Yorùbá
- Kí ló lè ṣekúpa olùkọ́ fásitì Adekunle Ajasin tẹ́lẹ̀ tó dákẹ́ sínú mọ́tò rẹ̀ yìí?
Ibẹrẹ pẹpẹ rẹ ati bo ṣe di olowo
Wọn bi Fernandez bi ọjọ kejila, oṣu Kẹjọ, ọdun 1929 niluu Eko sinu idile tọkọ-taya Julia Fernandex ati Canut Fernandez.
Orukọ Fernandenz wa lati iran awọn ẹru ti wọn gba ominira lọwọ orilẹ-ede Brazil, Portuguese si ni ede wọn.
Gẹgẹ bi itan aye rẹ ṣe lọ, awọn obi rẹ ko lowo lọwọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ṣagbe jẹun, eyii lo mu ko gbiyanju lati ni owo lọwọ.
O kawe lawọn ile ẹkọ kan niluu Eko bii CMS Grammar School, Saint Gregory ati Holy Cross.

Oríṣun àwòrán, @DeleMomodu
Nigba to wa ni ọmọ ọdun mejidinlogun lo gba ilu Amẹrika lọ, ilẹ naa san an lẹyin to bẹrẹ iṣẹ epo rọbi, larin ọdun meji pere lo di olowo gọbọi.
Iroyin ni Fernadez bẹrẹ si n pa biliọnu lẹyin to ra ida aadọta ileeṣẹ Petor Inett to n wa epo ni eti okun orilẹ-ede Angola.
Bo tilẹ jẹ pe kii ṣaba bẹ Naijiria wo, Fernandez ni awọn ile niluu Kano, awọn ile alaja pupọ niluu Eko, atawọn ile miran lawọn orilẹ-ede bii Scotland, France, Belgium ati ilẹ Gẹẹsi.
Bẹẹ lo tun ni obitibiti owo nile ifowopamọ lawọn ilu bii Cayman Islands, France, Switzerland, Irealand, Hong Kong, Scotland ati ile Amẹrika.
Fernandez ati oṣelu
Nigaba to di ọdun 1982 ni Fernandez darapọ mọ oṣelu, o si ṣiṣẹ pẹlu ijọba orilẹ-ede Angola gẹgẹ bii olubadamọrann pataki fun ijọba ilẹ naa.
Ni ọdun 1984, wọn yan an gẹgẹ bii aṣoju ajọ iṣokan agbaye, UN, lati orilẹ-ede Mozambique.
Ọdun 1992 ni wọn yan an gẹgẹ bii olubadamọran pataki si Aarẹ Mozabique, o si di ipo naa mu fun ọdun meji gbako ko to tun ti di aṣoju ijọba Dahomey Republic lọdun naa lọhun.

Oríṣun àwòrán, @DeleMomodu
Idile rẹ
Orukọ iyawo akọfẹ rẹ ni Barbara to jẹ ọmọ bibi ilẹ Amẹrika, wọn si jọ gbe papọ gẹgẹ bii tọkọtaya fun ọdun marunlelogun.
Lẹyin naa lo gbe ọmọ ọba Abiola Dosumu, ti ilu Eko niyawo, ṣugbọn igbeyawo naa tuka, o si kan an nipa fun obinrin naa lati dẹkun ati maa lo orikọ idile oun lawujọ.
Iyawo rẹ kẹta ni Duke Fernandez ṣugbọn aarin wọn daru lọdun 2003.
Lẹyin ti igbeyawo ọhun fori sọgi ni ile ẹjọ kan an nipa fun Fernandez lati maa san ẹgbẹrun marundinlọgọrin pọun fun obinrin ọhun loṣoṣu.
Iyawo to fẹ kẹyin ni ọmọ Ọba Halima Maude lati ipinlẹ Kano, oun ni wọn si jọ wa gẹgẹ bii tọkọ-taya titi di akoko to papoda.
Ẹsin abalaye
Gẹgẹ bii awọn onkọtan nipa igbeaye rẹ sẹ sọ, ẹsin ibilẹ ni Oloye Antonio Deinde Fernandez ṣe ko to fi aye silẹ, koda agba ọjẹ ni ninu ẹgbẹ Ogboni.
Awọn eeyan kan ri gẹgẹ bii ẹni iyi nilẹ Yoruba, gbolohun ọrọ ti wọn si mọọ si ni "agutan meji kii mu omi ninu koto kan naa."

Oríṣun àwòrán, inlandtown
Ẹkọ
Lara awọn ẹkọ ti awọn ọdọ aye ode oni le ri kọ ninu igbeaye Fernandez ni pe ko ni ṣe iru ipo ti eeyan ba wa nile aye, o si le yi kadara rẹ pada si rere.
Bakan naa ni igbe aye rẹ ṣafihan pe ẹnikẹni to ba mura siṣẹ rẹ le la bopẹ boya.
Fernandez ni owo to bẹẹ to fi ọpọ dukia silẹ fun awọn ọmọ to fi silẹ saye lọ.
Ọjọ kinni, oṣu Kẹsan an, ọdun 2015 ni Fernandez dagbere faye niluu Brussels, lorilẹ-ede Belgium.














