Richard Okorogheye death: Bí wọ́n ṣe rí òkú rẹ̀ nínú adágún omi ní UK lọ́sàán gangan

Oríṣun àwòrán, MET Police
Iya to bi Richard Okorogheye ti sọ̀rọ̀ lẹyin ti awọn ọlọpaa ri oku rẹ he ninu adagun odo igbo kijikiji kan ti ọlọpaa si fi aridaju han pe ọmọ wọn ni.
Iya rẹ, Evidence Joel ni iroyin itufọ rẹ sọ oun di "polonfo patapata". Ọ sọ fun Sky News Uk pe "ni asiko yii, mo kan ṣaa fẹ mọ bi ọmọ mi ṣe ku ni. Mo nilo alaye kikun gidi gan".
Ọgbẹni Richard Okorogheye di awati lẹyin to jade ni ile mọlẹbi rẹ to wa ni Ladbroke Grove, West London nirọlẹ ọjọ kejilelogun oṣu kẹta.
Iya rẹ ni "mo fẹ gba a mu, mo fẹ gba a mu tori oun nikan ni mo ni, kii fa wahala torinaa ọlọpaa o le mọ ọ".

Oríṣun àwòrán, Sky News
- Ṣé àwọn Ọlọ́pàá ṣẹ àwọn ayé ni tí wọ́n tún kọlu Àgọ́ Ọlọ́pàá míì? Wọ́n jí Ọlọ́pàá kan gbé
- Kí ló lè ṣekúpa olùkọ́ fásitì Adekunle Ajasin tẹ́lẹ̀ tó dákẹ́ sínú mọ́tò rẹ̀ yìí?
- Ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ikú tó pa olùkọ́ fásitì Adekunle Ajasin tó kú sínú mọ́tò - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ondo
- Bí Oladeinde Fernandez tí bàbá rẹ̀ kò gbajúmọ̀ ṣe rìn ín tó ń wọ́ ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ owó lókè òkun
Lẹyin ti esi ayẹwo oku ti wọn ṣe jade ni l'Ọjọbọ ni ọlọpaa sọ pe orukọ oku ti awọn ri ni Ọgbẹni Richard Okorogheye.
Awọn ọlọpaa ni ọna ti awọn n gba ṣe iwadii iṣẹlẹ yii wa labẹ "isọri eyi ti ko tii ni alaye" awọn ọlọpaa si maa n gbagbọ ni iru ipele yii pe ko lee si ọwọ eeyan kankan ninu iṣẹlẹ naa.
Tori idi eyi, ohun to ṣokunfa iku rẹ ko tii han sita ati pe awọn ọlọpaa ko ri ẹri kankan to sọ pe o la iṣoro ara rẹ kọja tabi pe eeyan kan dunkoko mọ ọ lati pa a.
Ikọ awọn akọṣẹmọṣẹ ṣi waninu igbo Epping ti iṣẹlẹ ọhun ti waye lati tẹsiwaju ninu iwadii.
Ọga Ọlọpaa Danny Gosling ni "eyi kii ṣe ohun ti ẹnikẹni wa lero torinaa, a o rii daju pe idile rẹ to n ṣọfọ ri atilẹyin to peye latọdọ ọlọpaa akọṣẹmọṣẹ.
Lọjọ Aje ni wọn ti kede oku naa gẹgẹ bi akẹkọọ ọmọ Naijiria ẹni ọdun mọkandinlogun ti wọn ti n wa, Richard Okoroghoye.
"Ọkan ibanikẹdun wa lọ si ọdọ mọlẹbi Richard lasiko to nira yii", ileeṣẹ ọlọpaa ilu London, Metropolitan UK kọ ọ sita loju opo ayelujara Twiter eyi to fihan pe lootọ ni o ṣẹlẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa UK ni wọn yoo maa ri atilẹyin awọn akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa.
Ninu adagun odo kan ni Epping Forest ni wọn ti ri oku rẹ lọsan gangan ọjọ Aje iyẹn si ni ọjọ kejila lẹyin ọjọ ti wọn ti kede pe wọn n wa Okorogheye to jẹ akẹkọọ ni Oxford Brookes.
Lati irọlẹ ọjọ kejilelogun oṣu kẹta ni Richard ti jade kuro nile wọn to wa ni Ladbroke Grove, West London ti wọn si kede rẹ kiakia fun ọlọpaa lẹyin ọjọ meji ti wọn o ri i nile.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Iwadii fihan pe o wọ ọkọ taxi lọ si Loughton ti ko ju iwọn kilomita mejilelogun si ibi ti o n gbe.
Ko to di pe wọn o ri i mọ, Okorogheye ti n ba aisan foniku fọla dide ti oloyinbo n pe ni sickle cell disease gbe to si ti n fi pamọ eyi to tumọ si pe ko yẹ ko kuro nile o si yẹ ko din bi o ṣe n ri awọn eeyan soju ku tori ilera rẹ.
Ọkunrin to ga to dudu, to sin gbọnlẹ
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ileeṣẹ iroyin channels Television pẹlu baba oloogbe naa, Christian ṣapejuwe ọmọ rẹ gẹgẹ bi kunrin to ga to si ni okun, amugbalẹgbẹ ọdọ ni to fẹran lati maa ba awọn ọrẹ rẹ sọrọ.
Baba rẹ da ẹbi bo ṣe di awati ru iporuru ọkan to n la kọja latari ofin konile ogbele ati jijoko sinu ile fun ọjọ gbọọrọ.
"Ọkunrin giga ni to si ni okun ati agbara; o fẹran lati maa ba awọn ọrẹ rẹ sọrọ".
O ni o to asiko kan ti o ya ara rẹ kuro lọdọ awọn ọrẹ koda to ni awọn kan ti ko ni igbagbọ ninu wọn patapata. Omii ni pe ti ẹ ba gbe eeyan pamọ sile fun odidi oṣu kan o le pẹlu gbogbo nkan to n ṣẹlẹ si i, mo ro o pe gbogbo ẹ ti su u ni".
















