Bayern vs PSG: Haaland báwo? Mbappe ló dáná sun Bayern Munich ráúráú nílé wọn

Kylian Mbappe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi ọmọ ẹni ba dara, ẹ jẹ ka wi nitori a o ni fi ṣe aya.

Orukọ Kylian Mbappe lo gbẹnu awọn ololufẹ ere bọọlu lalẹ Ọjọru lẹyin to gbarada ninu ifẹsẹwọnsẹ UEFA Champions League ti Paris St-Germain gba pẹlu Bayern Munich.

Goolu meji ọtọtọ ni Mbappe gba sawọn ninu ere bọọlu ti PSG ti da ṣeria fun Bayern pẹlu ami ayo mẹta si meji nile wọn.

Ifẹsẹwọnsẹ naa jẹ bi ẹsan fun PSG nitori awọn ni Bayern lu ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije Champions League ti saa to lọ ti wọn fi gba ife ẹfẹ naa.

Lẹyin iṣẹju mẹta pere ti wọn bẹrẹ ere bọọlu ọhun ni Mbappe gbayo akọkọ sawọn.

Balogun ẹgbẹ agbabọọlu PSG, Marquinhos lo gba goolu keji wọle fun ikọ naa.

Amọ, ẹgbẹ agbabọọlu Bayern ja rabu rabu, Eric Maxim Choupo-Moting ati Thomas Mueller da goolu mejeeji pada.

Kylian Mbappe gba goolu sawọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣugbọn Mbappe kan Bayern ni eyi ọọkan lẹyin to gba goolu mi sawọn nigba ti ere bọọlu ọhun ku iṣẹju mejilelogun ko pari.

Ipele keji ifẹsẹwọnsẹ yii yoo waye nile PSG laipẹ yoi lati mọ ẹni ti yoo pegede fun ipele to kangun si aṣekagba.

Ti ẹ o ba gbagbe, Mbappe gba goolu mẹta sawọn nigba ti PSG koju Barcelona ni ipele ti wọn gba sẹyin.

Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea naa fiya jẹ FC Port o mọ ile wọn ninu ere bọọlu UEFA Champions League keji to waye lalẹ Ọjọru.

Mason Mount ati Ben Chilwell lo gbayo mejeeji sawọn ninu eyi ti Chelsea ti fihan gbangba pe awọn kii ṣẹgbẹ Porto.