Chelsea vs West Brom: Èèmọ̀! West Brom fi omi àbùkù wẹ̀ fún Chelsea lọ́sàn án gangan nílé wọn

Chelsea vs West Brom

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajẹkun iya ni ikọ agbabọọlu Chelsea jẹ lọwọ West Brom lọsan ọjọ Abamẹta.

Ami ayo marun un si meji ni West Brom fi ṣagba fun Chelsea ninu ifẹwọnsẹ idije Premier League naa to waye ni papa iṣere Stamford Bridge.

Ni ṣe lo da bi ẹni pe Chelsea yoo rọwọ mu ṣaaju nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun kọkọ bẹrẹ lẹyin ti Christian Pulisic sọ goolu sinu awọn West Brom.

Ṣugbọn nigba to ku diẹ ki abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa wa sopin ni Fellipe Matheus Pereira da pada lera lera, lai fọta pe.

Ninu abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa ni Callum Robinson ti ṣe bii ọmọkunrin, toun naa tun sọ goolu kan sinu awọn Chelsea.

Chelsea vs West Brom

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iṣeju marun un si asiko naa ni Mbaye Diagne naa tun fi ẹyọ kan le.

Bo tilẹ jẹ pe Mason Mount gbiyanju lati da ami ayo kan pada, lati fun Chelasea ni ami ayo meji ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, goolu ti Callum Robinson tun sọ wọle nigba to ku iṣẹju aaya diẹ ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari lo fi ọba le.

Lẹyinorẹyin, Chelsea fi agbọn ru goolu marun lọle nigba ti wọn da meji pere pada fun West Brom.