Àǹfààní ìlera mẹ́wàá tí o lè rí lára èso Beetroot

Aworan eso beetroot

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan eso beetroot
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Eso ti a mọ si Beetroot ko wọpọ nilẹ yii, ṣugbọn eyi ko tumọ si pe ko si lọja kaakiri Naijiria.

Awọ pupa bii ti anamọ ti inu rẹ funfun ni eso beetroot saba maa n jẹ.

A le fi w eewebẹ, nitori ewe rẹ ṣee jẹ, bakan naa si ni eso rẹ ṣee jẹ pẹlu.

Ewe beetroot koro, eso rẹ dun.

Beetroot ni ẹya ọtọọtọ, funfun wa, pupa alawọ ofeefe wa, (yellow). Ṣugbọn alawọ pupa rẹ nikan lo ni eroja to n pa jẹjẹrẹ ninu, eyi ti a mọ si Betacyanin.

Wọ̀nyí ni àwọn àǹfààní tó wà lára beetroot, bí àwọn onímọ̀ ṣe ṣàlàyé

Aworan ẹni to n da omi eso beetroot sinu ife

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bi alaye awọn onimọ nipa eso , beetroot ni eroja ti a mọ si nitrates ninu.

Eyi le ṣiṣẹ fun ki ọpa to n gbe ẹjẹ lọ sara fẹ si i, ki aaye si wa fun ẹjẹ lati rin geere ninu ara.

Iwadii kan sọ pe ẹjẹ ẹni to ba n jẹ eso yii deede ko ni i maa ru.

Wọn ni o le dena aisan rọparọsẹ ati aisan ọkan ni ida mẹwaa.

Ọjọgbọn Andy Jones lati Yunifasiti Exeter, ṣalaye bi eroja nitrates to wa ninu beetroot ṣe n jẹ ki ẹjẹ lọ si ìhà ati awọn iṣan ara eeyan, ti yoo si ran afẹfẹ ti a n mi simu, oxygen, lọwọ pẹlu.

  • Beetroot kun fun eroja to n da aabo bo ara.
  • Awọn ohun to n gbogun ti jẹjẹrẹ wa ninu rẹ bii ferric acid, ruin ati kaempferol.
  • O ni eroja to n gbogun ti ara riro ati inira inu iṣan.
  • Beetroot maa n fun ara lokun, o si maa n jẹ ki eeyan le ṣere idaraya fun igba pipẹ
  • Beetroot le ran bi ounjẹ ṣe n da ninu eeyan lọwọ. Eyi ri bẹẹ nitori eroja fibre to wa ninu rẹ. O daa fun inu, yoo si mu igbọnsẹ ṣiṣe rọrun.
  • O le ran ọpọlọ eeyan lọwọ lati ronu kia, ki eeyan ma si maa gbagbe nnkan.
  • Beetroot daa fun awọn obinrin ti wọn ko ṣe nnkan oṣu mọ.
  • Iwadii fi han pe o ṣee ṣe ki aisan ọkan tabi ẹjẹ riru maa yọ awọn obinrin kan lẹnu lẹyin ti nnkan oṣu wọn ba duro. Ṣugbọn pẹlu eroja nitrate to wa ninu beetroot, opo ẹjẹ to wa fun ọkan yoo maa lagbara si i bi wọn ba n jẹ eso yii.
  • Beetroot maa n ran pajapaja ọwọ ati ẹsẹ lọwọ.

Mẹ́lòó ló yẹ kí èèyan máa jẹ?

Ọjọgbọn Jones gba awọn eeyan nimọran lati maa jẹ meji si mẹta beetroot lojumọ. O ni awọn ti ko tobi ti ko si kere ju, to mọ niwọn lo daa lati jẹ.

O gba wọn nimọran lati ri i daju pe wọn n fun ara ni odiwọn nitrates to yẹ lojumọ, bẹẹ ni ki wọn maa ṣe lọsọọsẹ pẹlu, ki wọn le ri iṣẹ rẹ lara.

Awọn oluwadii lati ile ẹkọ London School of Medicine and Dentistry, ṣalaye pe bi eeyan ba n mu omi eso beetroot, o le jẹ ki ifunpa lọ silẹ.

Ṣugbọn awọn oluwadii kan kilọ pe iṣẹ ṣi ku to yẹ ko waye lori iwadii ohun ti beetroot n ṣe nipa mimu ifunpa walẹ.

Wọn si kilọ pe mimu omi eso beetroot le mu ayipada airotẹlẹ wa, wọn ni o le sọ itọ eeyan di alawọ pupa (pink).

Ìkìlọ̀

Bo tilẹ jẹ pe awọn iwadii yii dara lati gbọ, awọn onimọ kilọ pe iwadii ṣi ku to yẹ ko waye lori iwulo beetroot.

Wọn fi kun un pe eeyan gbọdọ kan si dokita rẹ to ba fẹẹ fi ounjẹ kan kun eyi to n jẹ tẹlẹ, tabi to ba fẹẹ paarọ iru ounjẹ to n jẹ, paapaa bi ẹni naa ba ni ailera kan to n yọ ọ lẹnu.