Ọmọ dàpọ̀ ní wọ́ọ̀dù! INEC kède ìgbésẹ̀ lórí ẹgbẹ́ òṣèlú méjì tí àdàpè wọn ń jẹ́ 'ADA'?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ti le ni ọgọrun-un kan ẹgbẹ oṣelu to ti fi orukọ ranṣẹ si ajọ eleto idibo, INEC, bayii, fun iforukọsilẹ, ṣaaju eto idibo ọdun 2027 ni Naijiria.
Ninu awọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn fi orukọ ranṣẹ si ajọ INEC ni eyi ti adape rẹ n jẹ ADA.
Ṣugbọn ẹgbẹ meji lo n ja du orukọ yii bayii, bo tilẹ jẹ pe itumọ ọtọọtọ ni apeja awọn orukọ meji ọhun.
Gẹgẹ bi INEC ṣe wi, ẹgbẹ ADA akọkọ pe apeja orukọ tiẹ ni 'All Democratic Alliance' (ADA), nigba ti ikeji jẹ ' Advanced Democratic Alliance' (ADA).
Fun ẹgbẹ ADA akọkọ, ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Oloye Akin Ricketts ni wọn lo n ṣe agbatẹru rẹ.
Ẹgbẹ All Democratic Alliance yii ni a gbọ pe o jẹ ti awọn alatako Aarẹ Bola Tinubu, ti wọn n mura lati gba ipo aarẹ lọdun 2027.
Awọn kan tilẹ sọ pe Atiku Abubakar, Mallam Nasir El-Rufai ati Rotimi Amaechi, lo wa lẹyin ẹgbẹ yii.
Fun ti ẹgbẹ ADA keji, iyẹn Advanced Democratic Alliance, Alhaji Ahmadu Suleiman ni wọn yan gẹgẹ bii alaga ti yoo ṣi maa dele na, nigba ti wọn yan Zipporah Pius Miracles bii akọwe.
Níbo ni ọfiisi awọn ẹgbẹ meji ti adape wọn n jẹ 'ADA' wà?
ADA to wa fun Oloye Ricketts ni ọfiisi tiẹ wa ni UAC Complex, Opopona Samuel Ademulegun, l'Abuja.
ADA keji mu ọfiisi tiẹ si Frandriance Close, off Aminu Kano Crescent, Wuse 2, niluu Abuja kan naa.
Loju iwe INEC ti wọn to orukọ awọn ẹgbẹ yii si, wọn to tẹle ara wọn ni.
Onka 109 ati 110 ni wọn wa loju iwe naa.
Iroyin sọ pe ẹgbẹ oṣelu kan to n ṣatilẹyin fun Peter Obi, ondupo aarẹ ninu ẹgbẹ Labour ninu idibo ọdun 2023, naa fi orukọ to jọra wọn silẹ fun INEC.
A gbọ pe eyi ri bẹẹ lati fi tako ẹgbẹ ti Atiku Abubakar n to pọ lati koju Aarẹ Tinubu ni.
Ṣugbọn pẹlu adapọ orukọ to le fa idarudapọ bi INEC ko ba tete gbe igbesẹ yii, ọpọ eeyan lo n sọ pe iṣẹ wa fun ajọ naa lati ṣe latari awọn ẹgbẹ to pọ biba yii.
Ti orukọ wọn si ti n papọ lai ti i rin jinna.
Kí ni INEC yóò wò mọ́ ẹgbẹ́ kan lára kó tóó gbà á wọlé bíi ẹgbẹ́ òṣèlú ní Naijiria?
Gẹgẹ bi INEC ṣe wi, titẹwọ gba iwe ipe lati fi orukọ awọn ẹgbẹ yii silẹ ko tumọ si pe gbogbo wọn naa ni oun yoo gba wọle bii ẹgbẹ oṣelu lorilẹede Naijiria.
Ajọ naa ṣalaye, pe awọn kinni kan wa ti ẹgbẹ oṣelu gbọdọ ni ko too di itẹwọgba, ti wọn yoo si fi orukọ rẹ lede gẹgẹ bii ẹgbẹ gidi.
Agbẹnusọ INEC, Zainab Aminu, ṣalaye fun BBC pe ẹgbẹ gbọdọ ni orukọ ati ami idanimọ to yatọ, ti wọn yoo fi da a mọ yatọ si ẹgbẹ mi-in.
" Lafikun, ẹgbẹ gbọdọ ni awọn alatilẹyin to n tẹle e, wọn si gbọdọ ni ọfiisi niluu Abuja."
"A ko fẹ ẹgbẹ to pọ ju, awọn to ni afojusun ti wọn si mọ bi nnkan ṣe n lọ la n fẹ. Nitori bi ẹgbẹ ba pọju, o le fa ipenija."
Agbẹnusọ ẹgbẹ eleto idibo ilẹ Naijiria naa lo ṣalaye bẹẹ.
Ajọ naa waa rọ awọn eeyan to fẹẹ fi orukọ ẹgbẹ oṣelu silẹ lati kan si i fun alaye kikun.
Bakan naa, abala 225A ofin orilẹede yii, fi aaye gba INEC lati fagile iforukọsilẹ ẹgbẹ oṣelu, bi awọn nnkan wọnyi ba ṣẹlẹ:
*Bi ẹgbẹ kan ba kuna lati ni gbogbo alakalẹ iforukọsilẹ.
* Bi ẹgbẹ ko ba ni ibo ida mẹẹẹdọgbọn (25%) ninu ibo aarẹ, tabi ni ijọba ibilẹ kan ninu ibo gomina ti wọn di.
*Bi ẹgbẹ ba kuna lati ri ibo agbegbe kan, o kere ju ninu ibo alaga ijọba ibilẹ, bi wọn ko ba ri ipo kan mu ninu ibo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ tabi ti apapọ.
Tẹ o ba gbagbe, ni 2020, ajọ eleto idibo yọ awọn ẹgbẹ kan danu, wọn si din ẹgbẹ naa ku lati mejilelaadọrun-un (92) si mejidinlogun (18)
INEC ṣalaye nigba naa, pe oun gbe igbesẹ yii nigba toun wo bi awọn ẹgbẹ oṣelu naa ṣe ṣe ninu idibo to kọja.
Ajọ INEC funra ẹ fidi ẹ mulẹ, pe oun ti gba lẹta iforukosilẹ awọn ẹgbẹ oṣelu to to ọgọrun-un kan ati mẹwaa (110).
Alaga INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, ṣalaye l'Ọjọruu, pe awọn n ṣiṣẹ lori awọn ilana ati ofin to de gbigba orukọ ẹgbẹ wọle.
" Ni ọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa ọdun 2023 yii, ajọ INEC ti gba lẹta ẹgbẹ to fẹẹ fi orukọ silẹ ti ko din ni 110.
"A n ṣiṣẹ lori ẹ nilana iforukọsilẹ ti ofin la kalẹ, a si ti fun awọn ti wọn fiwe ranṣẹ naa labọ, pe lẹta wọn ti tẹ wa lọwọ. "Awọn mẹfa kan ti wọn ṣẹṣẹ fi tiwọn ranṣẹ nikan ni a ko ti i fun labọ, a si maa ṣe bẹẹ ki ọsẹ yii too pari".
Alaga INEC, Ọjọgbọn Yakubu, lo ṣalaye bẹẹ.
Wọ̀nyí ni àwọn ẹgbẹ́ 110 náà bí INEC ṣe gbé e jáde
1. Key of Freedom Party (KFP)
2. Absolute Congress (ABC)
3. All Grassroots Party (AGP)
4. Congress Action Party (CAP)
5. United Social Democrats (USDP)
6. National Action Congress Party (NACP)
7. Great Alliance Party (GAP)
8. New Nigeria Congress (NNC)
9. United Peoples Victory Party (UPVP)
10. Allied Conservative Congress (ACC)
11. Peoples Freedom Party (PFP)
12. All Nigerians' Party (AND)
13. Abundant Social Party (ASP)
14. Citizens Party of Nigeria (CPN)
15. National Freedom Party (NFP)
16. Patriots Party (PP)
17. Movement of the People (MOP)
18. Peoples National Congress (PNC)
19. African Union Congress (AUC)
20. Alliance of Patriots (AOP)
Àwọn míràn ni
21. Socialist Equality Party (SEP)
22. About Nigeria Party (ABNP)
23. African Reformation Party (ARP)
24. Accelerated African Development Association (AADA)
25. Obidient Peoples Party (OPP)
26. Zonal Rescue Movement (ZRM)
27. Zuma Reform (ZR)
28. Party for Socialist Transformation (PST)
29. Liberation People's Party (LPP)
30. Progressive Obedients Party (POP)
31. Great Nigeria Party (GNP)
32. National Youth Alliance (NYA)
33. National Reform Party (NRP)
34. Patriotic Congress Party (PCP)
35. Community Alliance Party (CAP)
36. Grassroot Alliance Party (GAP)
37. Advance Nigeria Congress (ANC)
38. All Nigerians Alliance (ANA)
39. Team New Nigeria (TNN)
40. All Labour's Party (ALP)
Àwọn kan tún rèé
41. New Green Generation Coalition Party (NGOCP)
42. New Green Congress (NGC)
43. New Green Coalition Party (NGCP)
44. About All (Nigerian)
45. Nigerian Liberty Movement
46. National Democratic Party
47. Citizen United Congress
48. All Gender Party
49. Polling Unit Ambassadors of Nigeria
50. Village Intelligence Party
51. Great Transformation Party
52. Alliance Social Party
53. Nigeria Democratic Alliance
54. New National Democratic Party
55. Obedients Peoples Party (Not Provided)
56. Nourish Democratic People's Congress
57. All Youth Reclaim Party
58. LA RIBA Multipurpose Cooperative Society
59. Alliance Youth Party of Nigeria
60. The True Democrats
61. Democratic Peoples Congress
62. National Democratic Movement
63. Economic Liberation Party
64. Grassroot Ambassador's Party
65. All For All Congress
66. People Democratic Alliance
67. United National Youths Party of Nigeria
68. Peoples Liberation Party
69. Democratic Union for Progress
70. Citizen Democratic Alliance
Ẹgbẹ́ ń tẹ̀síwájú
71. African Action Group
72. Patriots Alliance Network
73. Democratic Leadership Party
74. Pink Political Party
75. Young Motivation & Awareness for Development Forum
76. Access Party
77. Youth Progressive Empowerment Initiative
78. Grassroot Ambassadors' Party
79. Republican Party of Nigeria
80. Sceptre Influence Party
81. Young Democratic Congress
82. Patriotic Nigerians Party
83. Far-Right Party
84. Democratic People's Party
85. United Citizens Congress
86. Reset Nigeria
87. New Nigeria Democratic Party
88. Save Nigeria People Party
89. Above All
90. Alliance for Youth and Women Party
91. Rebuild Nigeria Group
92. Citizen Progressive Party
93. Good Guardian Party
94. Abiding Greatness Party
95. Patriotic Peoples' Party
96. Development & Freedom Party
97. Peace, Unity & Prosperity Culture
98. The Populist Party
99. New Nigeria Leadership Party
100. All Allies Alliance
101. National Action Network
102. Coalition for Nigerian Democrats
103. Republican Party of Nigeria
104. Abundance Africa Alliance
105. Freewill Humanitarian Party
106. Peoples Emancipation Party
107. Peoples Liberation Congress Party
108. Peoples Democratic Congress
109. All Democratic Alliance
110. Advanced Democratic Alliance (ADA)














