Èyí ni ṣọ́ọ̀ṣì àkọ́kọ́ ní Naijiria- tí aláwo, olóríṣà àti àwọn ẹ̀sìn mìí n rí gẹ́gẹ́ bí ilé ìjọsìn wọn
Yoruba bọ, wọn ni ti ọmọde ko b aba itan, yoo ba arọba. Arọba si re e , oun ni baba itan.
Kii ṣe aṣiri mọ, pe awọn oyinbo alawọ funfun lo mu ẹsin igbagbọ wọ Naijiria ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
Igbesẹ naa si lo ṣe atọkun bi kikọ awọn ile ijọsin ṣe bẹrẹ.
Ile ijọsin akọkọ niluu Abeokuta, iyẹn Ijọ Cathedral ti Peteru mimọ, Ake, ni ṣọọṣi awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria.
Ijọ yii bẹrẹ ni ọdun 1844, lẹyin ti awọn oyinbo alawọ funfun kọkọ wa lọdun 1843.
Ọdun 1843 ni wọn kọkọ de ilẹ Ẹgba, paapaa ni ọjọ kẹrin oṣu ni ọdun 1843.
Alufaa Henry Townsend ati Andrew Williams ni wọn wa, ti Sodẹkẹ to jẹ Balogun Ẹgba lasiko naa si tẹwọ gba wọn ni igba yẹn.
Ṣugbọn ọdun 1844 ni wọn kọkọ kọ ijọ akọkọ yii ni ilẹ Ẹgba.

Ẹni to jẹ Alufaa ijọ St. Peters Cathedral ni Ake, Alufaa Samuel Omideji, sọ fun BBC lasiko ti a ṣe abẹwo si ile ijọsin naa pe, ile gogoro ti wọn n pe ni Tower, to wa ninu ọgba ile ijọsin naa ti wa nibẹ lati ọpọ ọdun sẹyin, to si jẹ pe aago to wa lori rẹ ni awọn araalu Abeokuta fi n ka wakati ni igba atijọ.
O ni, ko si ibi ti wọn o ti ki n ri tabi gbọ iro aago naa niluu Abeokuta.
"Wakati-wakati ni aago naa ma n dun, ohun ni o jẹ aago to n fi akoko han ni igba yẹn."


Abẹwo awọn akọroyin BBC Yoruba sinu gbọngan akọkọ ninu ile ijọsin naa ni wọn ti ri ibi ti wọn n sin oku awọn ajihinrere to ku sẹnu iṣẹ Oluwa, si
Gẹgẹ bi Alufaa ṣe sọ, gbogbo ọmọ Ẹgba lo ṣọọṣi akọkọ naa gẹgẹ bi ile ijọsin wọn, lai fi ti ẹsin wọn ṣe – alawo, eleegun, abọriṣa ati igbagbọ.
"Lootọ ni ile ogboni wa ni ibi aafin, ti o si jinna si ile ijọsin nibi, ko tiẹ ni ṣe rara pẹlu ijọ Ọlọrun, wọn o di wa lọwọ, tawọn oloriṣa gan an, tan ba n lọ, tan ba fẹ de ibi ile ijọsin wa, wọn ma pa ilu wọn, o si di igba ti wọn ba kọja tan, ki wọn to o tẹsiwaju ninu nnkan ti wọn n sẹ."

Amọ o, wahala ti waye ri laarin awọn ẹlẹsin ibilẹ ati awọn ara ile ijọsin yii ri.
Alufaa sọ pe ile ijọsin akọkọ ti wọn kọ ni ọdun 1844, ni awọn oloriṣa dana sun nitori ibẹru pe gbogbo awọn eeyan wọn yoo di Kristiẹni.
"Nigba ti awọn ẹlẹsin ibilẹ, awọn oloriṣa ati bẹbẹlọ, ro pe ti awọn ko ba tete wa nnkan ṣe ko ma dabi n pe wọn maa bẹrẹ si n ko awọn eeyan wọn lọ, nitori lara wọn ti n darapọ mọ ẹsin Kristẹni, ni wọn wa dana sun ile ijọsin.
"Wọn sun ile ijọsin yẹn patapata, ni igba tan sun ile ijọsin yẹn, wọn wa wo wi pe kini ṣiṣe, wọn bẹrẹ ile ijọsin miiran, pe kan tun imi kọ, wọn bẹrẹ iyẹn ni ọdun 1846.
"Eyi ti wọn kọ ni 1846 yẹn ni wọn pe ni ile ijọsin 'Exceta'. Ni igba ti ibi yẹn o wa fẹ gba wọn mọ, wọn ni lati tun wa kọ ile ijọsin miiran, iyẹn ni wọn bẹrẹ ni 1898, wọn pari ẹ lọdun 1900.
Ile ijọsin ti wọn pada kọ lo di St. Peters, Cathedral, Ake.