Mo pàdánù àkọ́bí mi nítorí àìrí owó ilé ìwòsàn - Ibrahim Chatta

Aworan Ibrahim Chatta

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Yoruba bọ wọn ni ẹni ti ko gba ti ẹlomiran lo maa ni toun pọ.

Ti ọpọ ba si sọ nipa oun ti wọn n la kọja tabi ti wọn ti la kọja niṣe ni eeyan maa ri pe ọpẹ lo yẹ oun.

Gbajugbaja oṣere tiata nni, Ibrahim Chatta ti ṣalaye bi o ṣe padanu ọmọ rẹ to kọkọ bi si ile iwosan kan nipinlẹ Eko nitori ko ri owo itọju san.

Chatta, tẹnubọ itan yii lasiko to n sọrọ ninu fọnran kan to lu sita lori ayelujara.

O ṣalaye pe oun sa gbogbo agbara oun lati wa owo fun itọju ọmọ to di oloogbe naa ṣugbọn pabo lo ja si.

O ni kireeti pako ẹlẹrindodo ni oun fi sin ọmọ ọhun lọdun naa.

"Malik kọ ni akọbi mi. Ọmọ obinrin ni akọbi mi. Mo padanu ọmọ naa nitori n ko ri owo ile iwosan san.

"A gbe lọ si ile iwosan ni agbegbe Iddo nipinlẹ Eko. Mo fẹ sẹ rin lati Ijora Badia lọ si Makoko, ti n ko si ri owo titi ọmọ naa fi jade laye. Kireti Coca-Cola ni a fi sin ọmọ naa."

'Aipẹ yii ni mo sọ itan fun mọlẹbi mi, ti gbogbo wọn si n sunkun'

Chatta ni oun ko ki n fi bẹ sọrọ ọmọ rẹ oloogbe, to si jẹ pe aipẹ yii gan ni oun sọ ọrọ naa fun awọn mọlẹbi rẹ lẹyin ti oun de lati irinajo lọ si orilẹede Qatar

"Ọjọ ti mo lọ si Dubai, ti mo si ra ẹbun nla wa fun ọmọ mi obinrin kankan soso ti mo bi, Hawawu, ni iya rẹ bẹrẹ si ni ma binu pe n ko ra ẹbun fun oun.

"Mo sọ fun lọjọ naa pe mo ti bi ọmọ obinrin kan ri, t imo si ṣalaye bi o ṣe jade laye. Gbogbo wọn bẹrẹ si ni ma sunkun nitori wọn ko gbọ nipa itan yii ri lati ẹnu mi."

Ta ni Ibrahim Chatta?

Gbajumọ osere tiata ni Ibrahim Tapa, ọmọ ilu Bacita nipinlẹ Kogi nii se, ẹya Tapa Lempe si lo jẹ.

Ọjọ Ktala osu Kẹwa ọdun 1970 ni wn bi gbajumọ osere naa, eyii tii se ọdun mejilelaadọta sẹyin.

Amọ Chatta ti pẹ nilẹ Yoruba, to si n ba wọn kopa ninu ere Yoruba lorisirisi.

Gbajumọ osere naa lo ni ẹbun pupọ nipa isẹ tiata, ko si si ipa ti ko le ko ninu sinima.

Bo ti n kopa bii ọdọ, lo lee se bii agbalagba, alakọwe, Babalawo ati janduku pẹlu.

Bakan naa ni Ibrahim Chatta ni ẹbun orin kikọ ati oriki ilẹ Yoruba pẹlu.

Lara awọn gbajumọ ere ti Chatta ti kopa ni Wehinwo, Alaaru, Police and Thief, Akirisore, Agboorun ati bẹẹ bẹẹ lọ.