Trump yarí lórí ìròyìn tó ní ìkọlu America sí Iran kò tu irun kankan

Oríṣun àwòrán, Maxar/Getty Images
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DIA to n maa n ṣe iwadii fun ileeṣẹ ologun Amẹrika ti sọ pe, kii ṣe gbogbo ibudo ti Iran n ko nnkan ija oloro si ni Amẹrika bajẹ lopin ọsẹ to kọja.
Amọ, Aarẹ Donald Trump ti yari wi pe ọrọ ko ri bẹẹ rara.
Trump sọ pe gbogbo nnkan ija oloro to wa ni ibudo iko nnkan si Iran lawọn ọmọ ogun Amẹrika bajẹ patapata.
Abọ iwadii lori ipa ti ikọlu Amẹrika ṣe si ibudo naa, eyi to lu sita fidi rẹ mulẹ pe, akoba diẹ ni ikọlu Amẹrika ṣe fun eto kikọ ibudo nnkan ija oloro ti Iran n kọ.
Ajọ DIA ni, ifasẹyin bi oṣu meloo kan ni ikọlu ti Amẹrika ṣe le jẹ fun Iran.
Awọn eeyan kan to sun mọ ajọ DIA sọ pe ko si nnkan to jọ wi pe ileeṣẹ ologun Amẹrika ba ibudo iko nnkan ogun oloro ti Iran fi ''Uranium'' kọ jẹ patapata.
Awọn eeyan naa sọ pe, nnkan ija oloro to wa lori ilẹ lasan ni Amẹrika bajẹ, wọn ni ko si nnkan to ṣe awọn ija oloro mii ti Iran ko jọ.
Ṣugbọn ijọba Amẹrika ti sọ pe irọ ni abọ iwadii ajọ DIA.
Ijọba Amẹrika ni, ẹnikan to jẹ ọdalẹ lara awọn ọtẹlẹmuyẹ lo gbe iroyin ọhun jade.
Amọ, Aarẹ Trump duro lori ipinnu rẹ pe gbogbo ibudo mẹta iko nnkan ija oloro si Iran ni Amẹrika bajẹ patapata.
Trump ni iroyin ti awọn ileeṣẹ iroyin Amẹrika kan n gbe kiri tabuku awọn ọmọ ogun to ṣe ikọlu si ibudo iko nnkan ija oloro si Iran.
Bawo ni adehun jogun-o-mi laarin Israel ati Iran ṣe n lọ?
Lẹyin ọjọ kan ti Aarẹ Trump sọ pe orilẹede Israel ati Iran gbọdọ tọwọ bọwe adehun jogun o mi, igbẹse naa ti bẹrẹ lori adehun naa.
Ko pẹ ti Trump kede adehun naa tan ni ọfiisi Olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu, fẹsun kan Iran wi pe o ju ado oloro si ẹkun Israel lẹyin ti adehun jogun-o-mi ti bẹrẹ.
Amọ, Iran ti sọ pe ko si nnkan to jọ bẹẹ rara.
Awọn minisita Israel naa ti sọ pe awọn yoo gbẹsan nnkan ti Iran ṣe.
Ọrọ naa bi Trump ninu debi wi pe o fẹsun kan orilẹede mejeeji pe wọn n tapa si ọna ti alaafia le fi jọba.
Trump ati Olootu ijọba Israel pada jọ sọrọ lori ọrọ naa lẹyin to ti tutọ soke foju gba a tan.
Ọfiisi Olootu ijọba Israel ni, orilẹede naa ti dẹkun ikọlu si Iran lẹyin ti Trump bẹrẹ adehun jogun- o-mi laarin awọn orilẹede mejeeji.
Bo tilẹ jẹ pe ko si idaniloju wi pe ọrọ ko ni bẹyin yọ, ko tii si iroyin to sọ nipa ikọlu tuntun lati ọdọ Israel tabi Iran bayii.















