Àwọn aláṣẹ KWASU kéde òfin tuntun lórí bí agbébọn ṣe n ja akẹ́kọ̀ọ́ lólè, fipá bá wọ́n lòpọ̀

Aworan abẹwo ileeṣẹ ọlọpaa Kwara si ile ẹkọ giga fasiti Kwasu

Oríṣun àwòrán, Kwara Police

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, CP Adekimi Ojo sọ pe oun ti ṣabẹwo si ilẹ ẹkọ giga fasiti Kwara State University (KWASU) Malete to wa niluu Ilorin lati fi ọkan awọn alaṣẹ ati akẹkọọ balẹ lẹyin ti awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa ke gbajare sita nipa bi awọn adigunjale ṣe n da wọn laamu.

Abẹwo ọhun lo da lori bi alaafia yoo ṣe jọba agbegbe ibi ti awọn akẹkọọ n gbe, ati bi iwa ibajẹ ati ọdaran yoo ṣe dikun ni agbegbe naa.

Ọjọ Iṣẹgun ni BBC Yoruba gbe iroyin sita nipa bi awọn adigunjale ati awọn afipabanilopo ṣe n yọ wọn lẹnu ni awọn ilegbe e wọn.

Ikọ BBC Yoruba sabẹwo si ile-ẹkọ naa , o si ba awọn akẹkọọ ti ọrọ kan sọrọ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Kwara Police

Ninu atẹjade kan, Ọga agba fun fasiti ọhun, Ọjọgbọn Shaykh Luqman Alade Jimoh, nigba to gba kọmisana ni alejo ni inu oun dun pupọ bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe tete gbe igbesẹ lori awọn adigunjale to n da awọn akẹkọọ lamu ni agbegbe ile ẹkọ naa.

Ọjọgbọn Jimoh ni iṣẹlẹ idigunjale yii n ṣe akoba nla fun awọn akẹkọọ, ti ile ẹkọ si ti pinnu lati gbe igbesẹ lati fi kune to aabo ni agbegbe ile ẹkọ naa.

Ki ni awọn igbesẹ ti ile ẹkọ KWASU n gbe?

  • Awọn onile gbọdọ pese ẹsọ alaabo fun ile ti wọn ba gbe kalẹ fun gbigba awọn akẹkọọ si. Akẹkọọ kọ gbọdọ gba ile ti ko ba ni ẹsọ alaabo.
  • ‎Fifofin de ọkada gigun lẹyin ago mẹwaa alẹ. Ẹni ti wọn ba ka to n gun ọkada lẹyin ago mẹwaa ni yoo ri ijiya ofin.
  • ‎Gbogbo ile itaja to wa ọgba ile-ẹkọ gbọdọ ti palẹmọ saaju agọ mọkanla alẹ.
  • ‎Akẹkọọ kankan ko gbọdọ tan ẹrọ amunawa wọ ago mejila oru, lati le mu adikun ba ariwo lasiko naa.

Nigba to n fesi, Kọmisana Adekimi Ojo kan sara si awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa fun igbesẹ akin ti wọn gbe lati tako idigunjale.

O fi da wọn loju pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo ṣa gbogbo agbara lati ṣe atilẹyin fun wọn ati ri pe gbogbo ofin ti wọn gbe kalẹ ni o jẹ mimuṣẹ.

Ẹ gbà wa o! Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ KWASU ké gbàjarè lórí bí agbébọn ṣe n jà wọ́n lólè, fipá bá tọkùnrin-tobìnrin lópọ̀

Aworan awon akẹkọọ

Awọn akẹkọọ ile-ẹko giga ipinlẹ Kwara, tiise, Kwara State University (KWASU) Malete ti rawọ ẹbẹ si ijọba ati awọn alẹnulọrọ lawujọ ki wọn gba awọn lọwọ awọn adigunjale ati awọn afipabanilopo ti wọn n yọ wọn lẹnu lasiko yii.

Laipẹ yii ni iroyin kan gba ori ayelujara lori bi awọn afurasi adigunjale ati awọn afipabanilopọ ṣe n sọsẹ ni ilu Malete, paapaa julọ ni agbegbe ibi ti awọn akẹkọọ n gbe.

Eyi lo mu ki BBC Yoruba sabẹwo si ile-ẹkọ naa ni ọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun osu Kẹfa, lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ.

Ni bi abẹwo naa lati ri wi pe, ọpọ akẹkọọ wa ni awọn yara ikawe wọn, nitori idanwo ranpẹ (test) ti wọn n se lọwọ.

Ẹni tí kò bá ní fóònù gidi, tí kò sì lówó lọ́wọ́, yóò jẹ wábi wọ́ sí ìyà - Akẹ́kọ̀ọ́

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Diẹ lara awọn akẹkọọ ti akọroyin BBC ba sọrọ, salaye ohun ti oju wọn n ri lẹnu ọjọ mẹta yii.

Awọn akẹkọọ yii ti a fi orukọ bo lasiri sọ pe, ile-ẹkọ naa ati agbegbe rẹ ti di ibi ewu bayii.

Wọn salaye pe nise ni awọn kan n yabo awọn ile awọn akẹkọọ, ti wọn si n ji dukia wọn lọ.

Yatọ si eyi, wọn tun n fi ipa ba awọn to jẹ obinrin ni ibalopọ.

Ẹnikan ninu wọn sọ wi pe, "lotitọ, Olorun o jẹ ki wọn ya ile ti wa, a mọ ibi ti wọn lọ lẹgbẹ ile wa, wọn fi ada ati awọn nnkan miran ja ilẹkun ati ferese.

"Wọn gba gbogbo owo ti wọn ba lọwọ awọn akẹkọọ to n gbe ibẹ, wọn si gba foonu ati komputa wọn.

"Awọn ti ko lowo lọwọ ni wọn fi ipa mu lati fi owo ranṣẹ lori foonu wọn, ko to wa di pe wọn fipa ba awọn obinrin ibẹ lopọ.

"Pa banbari ibẹ ni pe, ẹni ti ko ba ni foonu gidi, ti ko si lowo lọwọ, yoo jẹ wabi wọn si iya.

"Koda akẹkọọ-kunrin kan ti wọn o ka nkankan mọ lọwọ, yatọ si pe wọn luu, wọn fipa ba a lopọ, ni ibalopo ọlọkurin sọkunrin.

"Eyi to buru ju bayi ni bi wọn ṣe yabo ile awọn akẹkọọ kan, Ositẹli Hasbunallahu, wọn si wọ yara to le ni mẹtalelọgbọn lati ja wọn lole, laarin wakati kan pere.

"Wọn yi ni ohun ti oju wa n ri o, awọn akẹkọọ mii gan, ti salọ fun ile-ẹkọ lasiko yii, nitori ko si ẹni to mọ ile akẹkọọ to kan.

"A o mọ igbesẹ ti ile ẹkọ n gbe bayi lati ran wa lọwọ, tori yatọ si eto abo to mẹhẹ, nise ni gbogbo nkan gbowo lori, awọn olọkọda ati awọn oni mọto gan-an n saye le wa, gbogbo rẹ lo le koko bayii o, ki ijọba ati awọn pataki lawujọ gba wa o.

Wọ́n ń sá mi làdá ṣùgbọ́n Olorun kò jẹ́ kó wọlé - Olódẹ

BBC Yoruba kan si Ositẹli Hasbunallahu, ni ilu Malete, ile yii jina diẹ si ibi ti ile-ẹkọ wa, o si tun bọ si apa igbo bẹẹ si ni ọna ko dara rara.

Baba ọlọdẹ to wa nibẹ ni gbogbo ara rẹ le pọnran-pọran nitori ada ti wọn ṣa a, sugbọn ti ko wọle si lara.

Baba ọdẹ naa sọ pe awọn adigunjale naa de ni nnkan bi aago meji oru, wọn si to mẹẹdogun niye.

O ni oun o tete mọ bi wọn ṣe jẹ, afi igba ti wọn bẹrẹ si n sa oun ni gbogbo ara sugbọn ko ran oun.

O salaye pe igba ti oun rii pe wọn fẹ ri oun mu, ni oun ba fẹṣẹ fẹ, ki wọn ma ba yin oun lọrun nigba ti ada o ti wọle.

Tábìlì ìkàwé mi ni mo fi gba àdá, wọn ò bá fàdá fọ́mi lórí

Aworan Tabili

Ọkan lara olugbe ositẹli naa, ti ko fẹ orukọ rẹ lori ayelujara nitori abo ara rẹ, salaye bi ori ṣe ko o yọ, lọwọ awọn adigunjale naa,

"Gbogbo wọn to mẹẹdogun, wọn si pinrawọn si isọri-isọri, wọn si n wọ yara onikaluku ni ọkọọkan.

"Gbogbo yara to wa ni ositẹli yii to mẹtalelọgbọn, wọn fi ada ati ipa ja lẹkun ati ferese, igba ti wọn wọ yara mi, wọn de fila bẹntigọ, lati fi bo oju ara wọn, ede Hausa ati Gẹẹsi si ni mo gbọ ti wọn n sọ.

"Bi wọn ṣe ri mi ni wọn gbe ada soke lati sami lori, mi o mọ ohun to wọnu mi ni asiko naa, tabili onike ti mo fi n kawe ni mo sare gbe lati fi gba ada naa, lẹsẹkẹsi ni tabili naa ge si meji, mo ba bẹ sita, ori lo ko mi yọ nitori gbogbo ile naa ni wọn ti yi ka.

"Gbogbo foonu wa ati komputa wa ni wọn gbe lọ, gbogbo yaara ni wọn si wọ kari lẹyin yara kan ti awọn ọkunrin pọ gan-an nibẹ.

"Bi wọn ṣe ja ilẹkun wọn, ṣe ni awọn ọkunrin yaara naa pe sẹyin ilẹkun ti wọn si n ti pada bi wọn ṣe n si, bi wọn ṣe n tii mọrawọn lọwọ niyẹn, eyi to mu ki wọn o kuro nibẹ.

"O to wakati kan gbako ti wọn fi ṣe ohun ti wọn se, sugbọn kosi iranlọwọ kan titi wọn fi lọ fun ra wọn.

Ko da ọkada meji pere ni wọn gbe wa, ẹsẹ ni ọpọ yooku fi rin.

Ilé-ẹ̀kọ, àti àwọn agbófinró ń gbìyànjú, ṣùgbọ́n omi pọ̀ jọkálọ - Ààrẹ akẹ́kọ̀ọ́

Aworan aarẹ awọn akẹkọọ Lasu

BBC tun kan si arẹ gbogbo akẹkọọ KWASU, (SUG President), Abdulfeez Babatunde, lati mọ igbesẹ ti awọn akẹkọọ fẹ gbe lati ri pe, awọn isẹlẹ laabi wọn yii di afisẹyin ti eegun n fisọ.

Abdulfeez Babatunde, sọ pe awọn ti fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti, o salaye pe wọn gbiyanju agbara wọn sugbọn omi pọ jọkalọ.

O ni ilu Malete n dagba, o si n tobi sii lojojumọ, bẹẹ si ni awọn akẹkọọ ti ile-ẹkọ n gba wọle bayi ti ju ti tẹlẹ lọ.

O ni eyi lo fa a ti ipa awọn agbofinro perete to ko fi le kawọn.

Aarẹ naa sọ pe oun o ro pe awọn ọlọpaa to wa ni ilu naa ju ọgbọn lọ, bẹẹ si ni ositẹli akẹkọọ to wa ni ita ile-ẹkọ le ni ẹgbẹrun meji.

O fi kun-un pe awọn ti ṣe ipade pẹlu awọn alasẹ ile-ẹkọ to fi mọ awọn agbofinro ati alaga ijọba ibilẹ Moro, awọn si ti fẹnuko lori awọn ilana ati gbendeke lati rii pe awọn isẹlẹ laabi yii dopin.

Ki ni ipinnu ile-ẹkọ?

Aworan ile ẹkọ fasiti KWASU

Ọmọwe Saeedat Aliyu, to jẹ agbẹnusọ Fasiti KWASU, sọ pe ninu ipade ti awọn ṣẹsẹ pari pẹlu awọn alasẹ ile-ẹkọ, asoju akẹkọọ, awọn agbofinro ati awọn mii, awọn ti gbe awọn gbendeke kan kalẹ lati ri pe opin de ba isẹlẹ laabi ninu ọgba ile-ẹkọ ati agbegbe rẹ.

Awọn gbedeke naa ni pe, ọkada o gbọdọ sisẹ kọja ago mẹwaa alẹ, gbogbo ẹrọ amunawa gbudọ ti di pipa ni o pẹ tan, ago mejila oru, sise agbekalẹ awọn ẹsọ alaabo apaapọ, ki ositẹli kọọkan si tun gba fijilante lati ran awọn ọlọpaa lọwọ.

Alága ìjọba ìbílẹ̀ Moro sàlàyé ìpinnu rẹ̀ láti ṣètò àbò tó ní pọn fún akẹ́kọ̀ọ́

Saaju ni BBC Yoruba ti fọrọ wa alaga ijọba ibile Moro, ti KWASU kalẹ si lẹnu wo. Arabinrin Mariam Abdulwasiu Omotayo sọ pe, ijọba ibilẹ naa yo sagbekalẹ ofin ti yoo de gbogbo awọn ohun ti wọn fẹnukosi nibi ipade ti wọn se.

O ni oun ti gba fijilante mẹwaa kun awọn to wa nilẹ ti wọn si ti bẹrẹ isẹ pẹlu ohun ija to peye.

Awọn mẹta ninu awọn fijilante yii ni alaga naa ti ni ko lọ si ositẹli ti isẹlẹ ti ṣẹ yii, lati daabo bo awọn akẹkọọ.

Arabinrin Omotayo ni oun o fun ilu Malete ni ẹrọ transformer ki ina mọna mọna wọn baale duro re, oun si tun ti kede millionu kan naira fun awọn akẹkọọ ti wọn ji nnkan wọn lọ.

O salaye pe ilu ifayabalẹ ni ilu Malete, oun o si sa gbogbo ipa oun lati ri pe oun daabo bo awọn akẹkọọ.