Ṣé lóòótọ́ ni wọ́n fòfin dé Kunle Afod láti má kópa nínú eré mọ́?

Kunle Afod

Oríṣun àwòrán, Kunle Afod/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà nnì, Kunle Afod ti sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn kan tó gbòde pé àwọn alágbàtà eré sinimá ti fòfin dè é láti má kópa nínú eré sinimá mọ́.

Láti bí i ọ̀sẹ̀ kan sẹ́yìn ni ìròyìn kan ti ń lọ lórí ayélujára níbi tí wọ́n ti fẹ̀sùn kan pé Kunle Afod sọ pé wọ́n fì òfin de òun láti kópa nínú eré mọ́.

Nínú ìròyìn náà ni wọ́n ti sọ pé Kunle Afod sọ pé ìdí táwọn èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ rí òun nínú sinimá mọ́ ni pé òun àtàwọn alágbàtà fíìmù ni àwọn jọ ní ìfaǹfà nítorí nǹkan tí òun ṣe fún wọn.

Kunle Afod sọ níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe láìpẹ́ yìí pé òun jẹ́ èèyàn kan tó máa ń ní ìwòye nípa ọjọ́ iwájú.

Ó sọ pé láyé ìgbà tí àwọn ṣì máa ń ká fíìmù sínú kásẹ̀tì láyé àtíjọ́, òun ti rí ìwòye pé lílo CD yóò padà wáyé, tí òun sì ta àwọn alágbàtà fíìmù lólobó lórí rẹ̀.

Ó fi kun pé nígbà tí DVD dé, àwọn bẹ̀rẹ̀ sí ní lò ó, léyìí tó tún dára ju CD lọ.

Àgbà òṣèré náà tún sọ̀rọ̀ pé nígbà tí ó di ayé gbígbé fíìmù sórí ayélujára, ọ̀pọ̀ àwọn alágbàtà fíìmù ni kò tètè mọ̀ nípa rẹ̀.

"A sọ fún àwọn kan nípa rẹ̀ àmọ́ wọn kò gbọ́, èyí lò sí mú wa bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé fíìmù sórí ayélujára fúnra wa.

"Kàkà kí àwọn alágbàtà fíìmù náà bèèrè nípa rẹ̀ lọ́wọ́ mi, wọ́n rí mi gẹ́gẹ́ bí ẹni tó fẹ́ ba ọjà wọn jẹ́. Èyí ló jẹ́ káwọn alágbàtà fíìmù náà fòfin dè mí nítorí ọ̀rọ̀ náà."

Kunle Afod fi kun pé àwọn èèyàn náà padà pé òun sí ìpàdé tí òun sì ṣàlàyé gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ fún wọn.

"Nígbà tí wọ́n ri pé mi ò ní èrò abúrú sí àwọn, mo sọ fún wọn pé kí wọ́n kéde pé àwọn ti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tí wọ́n fi dè mí àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀, mo sì yàgò fún wọn."

"Ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti kọjá ni mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, mò ń ṣeré dáadáa"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹ̀wẹ̀, Kunle Afod ti wá sọ àfọ̀mọ́ ọ̀rọ̀ lórí ìròyìn tó gba orí ayélujára náà.

Nínú fídíò kan tí Kunle Afod fi sórí ìkànnì ayélujára Instagram rẹ̀ sọ pé àwọn kan ló lọ ń gbé ìròyìn tí kìí ṣe òótọ́ nípa òun.

Ó ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ń pe òun láti bèèrè nǹkan tó ṣẹlẹ̀ èyí tó ṣokùnfà tí òun fi ń ṣe fídíò náà.

Ó sọ pé lóòótọ́ ni òun ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan láìpẹ́ yìí níbi tí òun ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti wáyé sẹ́yìn sí òun lágbo eré tíátà.

Kunle Afod ní ibi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà ni òun ti sọ̀rọ̀ nípa ìfaǹfà tó wáyé láàárín òun àti àwọn alágbàtà fíìmù ṣùgbọ́n táwọn èèyàn ń gbe kiri bí ẹni pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé.

"Ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti wáyé láti ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn tí mo sọ níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ni ẹ̀yin wá gé pé pè pé, tí ẹ kọ àkọ́ọ́lé lé lórí pé ìdí tí wọn kò fi pé Kunle Afod síṣẹ́ mọ́.

"Mò ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé fíìmù sórí ayélujára, ayé ìgbà tí wọ́n ṣì ń ta CD àti DVD, táwọn alágbàtà eré ń takò mí pé kí ló dé tí mò ń gbé fíìmù sórí ayélujára.

"Ọ̀rọ̀ ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn, ẹ wá gbe bí ìgbà pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣẹlẹ̀, ẹni tó bá máa ń wo fíìmù dáadáa mọ̀ wí pé mò ń ṣeré dáadáa títí di àsìkò yìí."

Àgbà òṣèré náà sọ pé ọ̀pọ̀ fíìmù òun ló wà lórí ayélujára àti pé àwọn èèyàn nílò láti dẹ́kun gbígbé àwọn ìròyìn tí kìí ṣe òótọ́ lórí ayélujára.

Ó ṣe ìkìlọ̀ pé ìjọba àpapọ̀ ti gbé òfin kalẹ̀ lòdì sí àwọn ìròyìn òfégè táwọn èèyàn ń gbé lórí ayélujára àti pé ìjìyà wà fún ẹni tí ọwọ́ òfin bá tẹ̀.

Ó kọminú lórí báwọn èèyàn ṣe máa ń gbé àwọn ìròyìn òfégè pàápàá lórí àwọn gbajúmọ̀ lórí ayélujára.

"Wọ́n máa gbé àwòrán àwọn èèyàn papọ̀, wọ́n le ní ẹnìkan ti fi ọkọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ tàbí kí wọ́n ní ẹlòmíràn ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, àwọn nǹkan tí kìí ṣe òótọ́, nítorí pé wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn máa tẹ̀lé àwọn lórí ayélujára."

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ìròyìn yóò jáde nípa òṣèré tàbí gbajúmọ̀ àwùjọ kan, tí wọ́n sì máa jáde láti jiyàn àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.

Ní bíi oṣù mélòó kan sẹ́yìn ni ìròyìn kan jẹ jáde lórí ayélujára nípa òṣèrébìnrin Adunniade táwọn kan sọ pé ó ní bí òun ṣe rẹwà tó òun kò lọ́kọ.

Lẹ́yìn tí ìròyìn náà gba orí ayélujára ni Adunniade jáde sọ̀rọ̀ pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà àti pé òun kò sọ ọ̀rọ̀ ọ̀hún níbikíbi.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ta ni Kunle Afod?

Kunle Afod

Oríṣun àwòrán, Kunle Afod/Instagram

Adekunle Afod jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré, adarí eré lágbolé eré fíìmù Yorùbá.

Ní ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Kẹwàá, ọdún 1973 ni wọ́n bí i tó sì ti pé ọdún mọ́kànléláàádọ́ta báyìí.

Ó ní ọdún 1986 ni òun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ fíìmù ṣíṣe.

Kunle Afod gbajúmọ̀ fún ipa tó kó lórí dídarí eré fíìmù "Ori Eiye".

Bákan náà ló gbajúmọ̀ fún ipa tó máa ń kó ní ìgbé ayé àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ pàápàá àwọn tó ti di àgbà ọ̀jẹ̀ nídìí eré tíátà.

Ó ní ìyàwó, Desola Afod, tó sì bímọ.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ti gba àmì ẹ̀yẹ lóríṣiríṣi lórí ipa rẹ̀ nídìí iṣẹ́ sinimá.