Kí ló dé tí ẹnu ń kun Adunni Ade lórí ayélujára?

Aworan Adunni Ade

Oríṣun àwòrán, Instagram/iamAdunniade

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja oṣere tiata, Adunni Adewale ti ọpọ mọ si Adunni Ade, ni ẹnu bẹrẹ si kun ni owurọ ọjọ Aje loju opo ayelujara X.

Ọrọ kan ti wọn sọ nipa gbajumọ osere naa lo sokunfa bi ẹnu se n kun naa.

Bo ti lẹ jẹ pe BBC ko ri idi ọrọ naa fi mulẹ ṣugbọn ọpọ awọn ileesẹ iroyin ayelujara lo gbe iroyin naa sita pe Adunni sọ pe "bi oun ṣe lẹwa to, oun ko ri ọkunrin lati fẹ oun gẹgẹ bii iyawo."

Iroyin naa ni Adunni sọ ninu iroyin kan pe "Mo jẹ obinrin to ni ẹwa pupọ eyi to n silẹkun ọpọ anfaani fun mi, ti ọpọ si nifẹ mi.

Ṣugbọn bayii n kọ? Mi o ti ni ade ori."

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Irọ to jina si otitọ ni iroyin yii, ti wọn ko ba wọgile iroyin ọhun, maa gbe wọn lọ si ile ẹjọ - Adunni Ade

Ọrọ yii ni ọpọ gba sori, ti wọn si bẹrẹ si ni maa beere ọpọ ibeere lori ọrọ naa.

Ṣugbọn, ṣe lootọ ni Adunni Ade sọrọ yii sita.?

BBC ṣe iwadii lori ọrọ yii ṣugbọn a ko ri idi ọrọ fi mulẹ.

Adunni Ade fun ara rẹ naa ti wa jade sita pe irọ to jina si otitọ ni ọrọ naa.

Adunni jẹ ko di mimọ fun awọn ileeṣẹ iroyin to gbe iroyin naa sita pe ti wọn ko ba wọgile iroyin ọhun, oun yoo gbe wọn lọ si ile ẹjọ.

O ni oun fun wọn ni wakati mẹrinlelogun lati wọgile iroyin naa.

"Mo n rọ yin pe kẹ gbe iroyin naa walẹ, ki awọn agbẹjọro mi to kan si yin.

"N ko nifẹẹ si lilo orukọ mi pẹlu iroyin ofege ti ẹ ko fidi rẹ mulẹ, ki ẹ to gbe sita."

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Ta ni Adunni Ade?

Adunni Adewale, ti ọpọ eeyan mọ si Aduuni Ade ni wọn bi silu New York lorilẹede Amẹrika.

Ọmọbibi Ireland ni iya rẹ nigba ti baba rẹ jẹ alawọ dudu lati ilẹ Yoruba.

Ọmọ ọdun meji lo ti pada wa si Naijiria pẹlu awọn obi rẹ lati wa se ayẹy oku baba baba rẹ, ilu Eko si lo gbe dagba to fi di ọmọge.

Amọ o tun pada sorilẹede Amẹrika lati lọ sile ẹkọ fasiti nibẹ.

Gbajumọ osere tiata ni ni ede oyinbo ati Yoruba ni orilẹede Naijiria ni Adunni Ade, to si tun maa n sisẹ asaraloge pẹlu.