Báwo ni èsì àtúnṣe ìdánwò UTME tí JAMB ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde ṣe rí sí ti tẹ́lẹ̀ tí wọ́n gbé jáde?

Aworan awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, JAMB/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ko din ni akẹkọọ 200,00 to gba maaki to le ni 200 ninu esi atunṣe idanwo UTME ti ajọ JAMB gbe jade lopin ọsẹ.

Ajọ JAMB sọ lẹyin to kede esi idanwo naa lana ọjọ Aiku ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Karun un yii pe akẹkọọ 1,365,479 ninu 1.9m to ṣe idanwo naa ni ko gba maaki to 200.

Eyi tumọ si pe ida aadọrin gbogbo awọn to ṣe idanwo ọhun ni ko gba to 200 tii ṣe idaji gbogbo maaki idanwo naa.

Ninu esi ti ajọ JAMB kọkọ gbe sita lọjọ kẹsan an oṣu Karun un yii, miliọnu kan abọ akẹkọọ ninu 1.9m to ṣe idanwo naa ni ko gba to 200, eyi to kọ ọpọ eeyan lominu ni Naijiria.

Lẹyin awuyewuye to tẹle esi ti JAMB gbe jade naa ni ajọ ọhun ṣe iwadii ti wọn si sọ pe aṣiṣe wa ninu esi idanwọ tawọn gbe jade.

Eyi lo jẹ ki JAMB kede wi pe atunṣe idanwo naa yoo waye nipinlẹ Eko ati lawọn ibikan lẹkun ila oorun guusu Naijiria.

Akẹ́kọ̀ọ́ 200,00 gba máàkì tó lé ní 200 nínú èsì JAMB tuntun

Lẹyin o rẹyin, akẹkọọ 379,000 ni JAMB kede pe wọn yoo tun idanwo UTME wọn ṣe nipinlẹ Eko ati atawọn ipinlẹ ẹya Igbo.

Amọ, nigba ti JAMB gbe esi atunṣe idanwo ọhun sita lana, ọpọ awọn akẹkọọ ti maaki ti wọn gba ninu idanwo akọkọ ko to 200 lo gba ju bẹẹ lọ ninu esi tuntun ti JAMB gbe jade.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi JAMB ṣe sọ, esi idanwo tuntun yii fi han pe awọn akẹkọọ ṣe daadaa ju bi wọn ṣe ṣe lọ ninu idanwọ ti wọn ti ṣe sẹyin lati igba ti wọn ti n ṣe idanwo naa lori ẹrọ kọmputa eyi ti wọn n pe ni CBT.

Akọsilẹ JAMB fi han pe akẹkọọ 1,931,467 ni ajọ naa gbe esi idanwo wọn jade lọdun 2025, eyi ti tumọ si pe gbogbo wọn lo jokoo ṣe idanwo ati wọle si ile ẹkọ giga fasiti atawọn ile ẹkọ giga mii ni Naijiria.

Eyi ju iye awọn akẹkọọ to ṣe idanwo UTME lọdun 2024 lọ ti wọn jẹ 1,842,364.

Ohun ti eleyii tumọ si ni pe iye awọn to ṣe idanwo UTME lọdun 2025 pọju iye awọn to jokoo ṣe idanwo naa lawọn ọdun to lọ sẹyin.

Awọn akẹkọọ 117,373 lo gba maaki to to 250 tabi ju bẹẹ lọ ninu esi idanwo UTME ọdun 2025 yii.

Eyi ju iye awọn to gba maaki to to 250 tabi ju bẹẹ lọ lọdun 2024 ti wọn jẹ 77,070 ati 56,736 ninu idanwo ọdun 2023.

Bo tilẹ jẹ pe esi idanwo UTME ọdun 2025 gbe pẹẹli ju ti ọdun 2024 lọ, ọpọ akẹkọọ to ṣe idanwo naa ni ko gba to maaki 200 eyi to jẹ bii ida aadọrin.

JAMB gbé èsì àtúnṣe ìdánwò UTME jáde

Lana ọjọ Aiku ni ajo JAMB to n ṣakoso idanwo ati wọle si ile ẹkọ giga fasiti ati awọn ile ẹkọ giga ni Naijiria kede esi atunṣe idanwo UTME to waye lọsẹ to kọja.

Agbẹnusọ ajọ naa, Fabian Benjamin lo kede eyi ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Aiku, Ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Karun un ọdun 2025 yii.

Ajọ JAMB ni awọn fi esi naa sita lẹyin ti Ọjọgbọn onimọ nipa eto ẹkọ, Boniface Nworgu boju wo o, to si yanana rẹ.

Atunṣe idanwo naa lo wa fun akẹkọọ 379,997 ti kudiẹkudiẹ to waye lati ọwọ ajọ Jamb ṣakoba fun nipinlẹ Eko ati ni awọn ibi kan lẹkun ila oorun guusu orilẹede Naijiria.

"Gbogbo esi idanwo ni a ti fi sita yatọ si ti awọn akẹkọọ ti wọn sẹ si ofin," atẹjade naa ṣalaye.

Awọn akẹkọọ ti wọn ko ni anfani lati jokoo fun atunṣe idanwo ati eyi ti wọn ṣe saaju ni ajọ Jamb ti ni wọn yoo tun ni anfani miiran lati jokoo fun idanwo naa.

"Bo ti lẹ jẹ pe akọsilẹ wa ni ida mẹtalelaadọrun ni awọn akẹkọọ to jokoo fun idanwo yii, aye si wa fun awọn akẹkọọ ti wọn ko ni anfani lati jokoo fun idanwo naa nitori idi kan tabi omiran," atẹjade naa ṣalaye.

Bawo lo ṣe le wo esi idanwo UTME rẹ?

Ṣaaju ni awọn akẹkọọ ti fi nọmba ẹrọ ibaraẹnisọrọ wọn sinu akọsilẹ Jamb.

Ohun ti wọn nilo ko ju pe ki wọn tẹ atẹjisẹ lati ẹrọ ibaraẹnisọrọ si nọmba yii.

Tẹ "RESULT" si 55019 tabi 66019 pẹlu nọmba to fi forukọsilẹ pẹlu Jamb, lẹsẹkẹsẹ lo maa gba atẹjisẹ esi idanwo rẹ.

Awọn akẹkọọ ko nilo lati lọ si ibudo ayelujara lati yẹ esi idanwo wọn wo.

Awọn esi idanwo ti iwadii ba n lọ lori rẹ ko ni jade

Eyi ni awọn ọrọ ti yoo gbe wa :

Verification Investigation

Under Investigation (A)

Under Investigation (B)

Alleged Infraction