Wọ́n fipá bá mi lò pọ̀ nígbà tí mo wá látìmọ́lé - Ajàfẹ́tọ̀ọ́

Aworan Agather Atuhaire

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajafẹtọọ, ọmọ orilẹede Uganda ti wọn fi si ahamọ fun ọpọ ọjọ lorilẹede Tanzania ti ba BBC sọrọ lori ohun to la kọja lasiko to wa ni ahamọ.

Agather Atuhaire ni awọn eeyan ti won wọ aṣọ funfun fi aṣọ bo oun loju, ti wọn si ja oun si ihoho, ko to di pe wọn fipa ba oun lopọ.

Atuhaire ni ibi ti wọn gbe oun si ni orilẹede Tanzania jẹ ibi ti oun ko mọ, ti wọn si mu oun pẹlu ajafẹtọọ mii lati orilẹede Kenya, Boniface Mwangi, ti wọn ri lẹnu ibode.

Awọn alaṣẹ ijọba Tanzania ko ti sọrọ nipa ẹsun yii.

"Inira naa pọ ju," Atuhaire fi apa han BBC, nibi ti wọn ti de e lọwọ.

O fikun un pe "bi mo ṣe n pariwo, ni wọn n fi ọwọ bo mi lẹnu".

O ni oun n gbọ ariwo lati ọdọ Mwangi, ti awọn eeyan si n dunkoko mọ ọn pe awọn yoo ki nnkan bọ inu nnkan ọmọ ọkunrin rẹ.

Awọn mejeeji yii ni wọn maa n lọ si Tanzania lati ṣe atilẹyin fun olori ẹgbẹ alatako Tundu Lissu, to farahan ni ile ẹjọ ni ọjọ Aje to kọja lẹyin ti wọn fẹsun iditẹmọjọba kan an.

Mwangi naa ṣalaye ohun ti oju rẹ ri loju opo ayelujara X: "Wọn fiya jẹ wa, wọn ni ka ja ara wa si ihoho, ka lọ wẹ.

A ko le rin, wọn ni ka ma ra kiri pẹlu ẹjẹ."

Pẹlu bi wọn ṣe gba wọn laaye lati kuro ni orilẹede wọn, Mwangi ati Atuhaire ni wọn ti fofin de awọn pe awọn ko gbọdọ wa sibi igbẹjọ naa mọ.

Lọjọ Aje to kọja ni Aarẹ Samia Suluhu Hassan ṣekilọ pe oun ko ni faye gba awọn ajafẹtọọ lati orilẹede miiran lati wa da si iṣẹlẹ to n lọ ni orilẹede Tanzania.

Wọn ṣawari Atuhaire nibi ti wọn gbe e ju si ni ẹnu ibode l'Ọjọbọ lẹyin ti wọn ju si ahamọ lọjọ Aje.

Aṣoju Uganda ni Tanzania, Fred Mwesigye, sọ pe alaafia ni Atuhaire, ti awọn mọlẹbi si ti tẹwọgba a.