Wo àwọn èso tó lè ṣàkóbá fún àgọ́ ara tàbí fa ikú òjijì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Abdalla Seif Dzungu
- Role, BBC Swahili
- Reporting from, Nairobi Kenya
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Eso igi jẹ ohun jijẹ fun ọpọ eeyan ati ẹranko, to si maa n dun lẹnu pupọ.
Ni ọpọ igba, ki i ṣe adun nikan ni awọn eso yii wa fun, ọpọ ninu wọn lo dara fun itọju ara pẹlu.
Ṣugbọn n jẹ o mọ pe awọn eso kan wa to le ṣe ijamba fun eeyan tabi ẹranko to ba jẹ wọn.
Koda irufẹ awon eso yii le fa iku ojiji tabi ijamba miiran fun eeyan.
Wọnyi ni awọn eso ti iwadii ni o ṣe akoba fun eeyan to ba jẹ
1. Eso Manchineel appu – Aṣekupani

Oríṣun àwòrán, Thinkstock
Eso afarajọ Apple yii ni wọn n pe ni "coast apple" tabi "death apple," eso yii rẹwa loju pupọ ṣugbọn o kun fun majele.
Nigba kugba ti ẹ ba ri eso yii, o rẹwa pupọ, to si fi ara jọ Apple gan to ba de ẹnu.
Ohun iyalẹnu lo jẹ pe ti eeyan ti gbiyanju lati tọ ọ wo lasan, lẹsẹkẹsẹ ni ẹni naa ko ni le mi daadaa mọ.
Eso yii le fa ki ara eeyan maa gbona, to si tun le fa inu riro pẹlu.
Koda, o le jasi iku ojiji nigba miiran.
Irufẹ eso yii ni ẹ le ri ni Caribbean, Mexico, South America, ati awọn apa guusu Florida.
Gẹgẹ bii East Fruit magazine ṣe ṣalaye, awọn eeyan to n gbin eso yii maa n lo o fun ohun ija.
Itan fi balẹ pe majele yii lo ṣekupa Juan Ponce de León in ọdun 1521.
2. Eso Ackee (Blighia sapida)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eso yii kere pupọ, to si n ṣe anfani fun ara, fun ọpọ ọdun, awọn ara Jamaican nifẹ eso yii, ti wọn si maa n sọ ọ di ounjẹ.
Eso yii ni ijamba ti eeyan ba jẹ ẹ lai tii la nitori o ni eronja hypolycin ninu, eyi to maa n fa aisan eebi, igbẹ gbuuru, to si tun le sọ eeyan si ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun, to si tun le pada jasi iku.
Pẹlu eyi, awọn eeyan Jamaica ri ounje yii gẹgẹ bii ounjẹ pataki, to si wọpọ laarin awọn araalu.
Wọn ri eso gẹgẹ bii eyi ti awọn babanla wọn fi silẹ fun wọn.
Eso yii ni anfani ati ijamba lara, ti wọn ṣapejuwe gẹgẹ agbara Ọlọrun.
3. Cherry

Oríṣun àwòrán, PA Media
N jẹ o mọ pe o ni awọn eso igi kan to o ni lati jẹ eso inu wọn?
Gbiyanju ko yago fun eyi to ba n jẹ eso Cherry.
Awọn eso to wa ninu wọn ni agbara lati ṣekupa eeyan.
Iwadii ti wọn gbe sita ninu journal ResearchGate ṣafihan pe awọn eso yii ni eroja majele hydrogen cyanide ninu.
Ti eeyan ba jẹ ẹyọkan tabi meji eso yii, o lewu pupọ fun ilera eeyan, ti eeyan ba wa jẹ ẹ pupọ, o le fa iku ojiji ati awọn aisan mii.
4. Eso Irawọ

Oríṣun àwòrán, iStock
Eso yii wa kaakiri agbaye. O dun lẹnu pupọ, to si jọ irawọ oju sanmọ, ti ọpọ si fẹran rẹ pupọ.
Ẹwẹ eroja oloro wa ninu eso yii.
Iwadii ni eso yii le fa ki okuta di aaya eeyan, to si tun le fa aisan kidinrin
5. Jatropha

Oríṣun àwòrán, iStock
Jatropha jẹ eso ti ẹ le ri ni awọn orilẹede ti igbo ti pọ. Eso yii naa dun lẹnu pupọ ṣugbọn o ni eroja majele ricin to le fa eebi, igbẹ guuru, inu rirun ati ọna ọfun didun.
Ọpọ awọn ọmọde lo jẹ eso yii, to si ti ṣe ijamba fun wọn.
Iwadii fihan pe lati ọdun 2004 si 2013, o le ni ẹgbẹrun ọmọde to dero ile iwosan nitori wọn jẹ eso yii.















