Àjọ JAMB gbé èsì àtúnṣe ìdánwò UTME jáde, bí o ṣe lè wo èsì ìdánwò rẹ rèé

Oríṣun àwòrán, JAMB
Ajo JAMB to n ṣakoso idanwo ati wọle si ile ẹkọ giga fasiti ati awọn ile ẹkọ giga ni Naijiria ti kede esi atunṣe idanwo UTME to waye lọsẹ to kọja.
Agbẹnusọ ajọ naa, Fabian Benjamin lo kede eyi ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Aiku, Ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Karun un ọdun 2025 yii.
Ajọ JAMB ni awọn fi esi naa sita lẹyin ti Ọjọgbọn onimọ nipa eto ẹkọ, Boniface Nworgu boju wo o, to si yanana rẹ.
Atunṣe idanwo naa lo wa fun akẹkọọ 379,997 ti kudiẹkudiẹ to waye lati ọwọ ajọ Jamb ṣakoba fun nipinlẹ Eko ati ni awọn ibi kan lẹkun ila oorun guusu orilẹede Naijiria.
"Gbogbo esi idanwo ni a ti fi sita yatọ si ti awọn akẹkọọ ti wọn sẹ si ofin," atẹjade naa ṣalaye.
Akẹkọọ 21,082 ti wọn ko tii ṣe atunṣe idanwo wọn yoo ni anfani miiran
Awọn akẹkọọ ti wọn ko ni anfani lati jokoo fun atunṣe idanwo ati eyi ti wọn ṣe saaju ni ajọ Jamb ti ni wọn yoo tun ni anfani miiran lati jokoo fun idanwo naa.
"Bo ti lẹ jẹ pe akọsilẹ wa ni ida mẹtalelaadọrun ni awọn akẹkọọ to jokoo fun idanwo yii, aye si wa fun awọn akẹkọọ ti wọn ko ni anfani lati jokoo fun idanwo naa nitori idi kan tabi omiran," atẹjade naa ṣalaye.
Bawo lo ṣe le wo esi idanwo UTME rẹ?
Ṣaaju ni awọn akẹkọọ ti fi nọmba ẹrọ ibaraẹnisọrọ wọn sinu akọsilẹ Jamb.
Ohun ti wọn nilo ko ju pe ki wọn tẹ atẹjisẹ lati ẹrọ ibaraẹnisọrọ si nọmba yii.
Tẹ "RESULT" si 55019 tabi 66019 pẹlu nọmba to fi forukọsilẹ pẹlu Jamb, lẹsẹkẹsẹ lo maa gba atẹjisẹ esi idanwo rẹ.
Awọn akẹkọọ ko nilo lati lọ si ibudo ayelujara lati yẹ esi idanwo wọn wo.
Awọn esi idanwo ti iwadii ba n lọ lori rẹ ko ni jade
Eyi ni awọn ọrọ ti yoo gbe wa :
- Verification Investigation
- Under Investigation (A)
- Under Investigation (B)
- Alleged Infraction
Èèyàn 20 bọ́ sọ́wọ́ DSS, ọlọ́pàá, fún ẹ̀sùn títọwọ́ bọ ojú òpó èsì ìdánwò UTME

Oríṣun àwòrán, Others
Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ ogun eeyan fun titọwọ bọ eto idanwo imọẹrọ ti JAMB loju.
Awọn afurasi yii ni igbagbọ wa pe wọn wa lara ọgọrun un awọn eeyan kan ti wọn sisẹ titọwọbọ imọ ẹrọ kọmputa ti wọn fi ṣe aayan awọn ajọ idanwo ajọ idanwo igbaniwọle si ileẹkọ giga JAMB ati ti aṣekagba girama ni Naijiria, NECO.
Gẹgẹ bii awọn agbofinro ṣe ṣalaye, awọn afurasi yii ti jẹwọ ẹsẹ wọn pe lootọ lawọn tọwọ bọ esi idanwo Jamb naa, eyi to mu ki ọpọ akẹkọọ ma gba idanwo ori kọputa gbọ mọ fun ojọ iwaju.
Iṣẹ awọn afurasi yii ni ki wọn bu maaki nla fun awọn akẹkọọ kan, to san owo toto ₦700,000 ati milọnu meji naira.
Iwadii awọn agbofinro fidi rẹ mulẹ pe ọpọ awọn ile ẹkọ aladani pa ọpọlọpọ owo pẹlu bi wọn ṣe siṣẹ pọ pẹlu awọn afurasi naa.
Bẹẹ ba gbagbe, ajọ Jamb sọ pe aṣiṣe wa ninu esi idanwo UTME tọdun 2025 yii to ṣẹṣẹ jade eleyi to fa ọpọ awuyewuye.
Ọga agba ajọ Jamb, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede, bu sẹkun gbaragada nigba to fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akọroyin lọjọ diẹ sẹyin niluu Abuja.
Ọjọgbọn Oloyede ni "nnkan to yẹ ko jẹ ayọ ti di ibanujẹ nitori aṣiṣe to waye."
Akọwe agba Jamb naa kede pe bii 379,997 awọn akẹkọọ to ṣe idanwo naa ni yoo tun idanwo ọhun ṣe bayii.
Eyi ko ṣẹyin awọn kudiẹ kudiẹ to waye to ṣokunfa bi ọpọ akẹkọọ ṣe fidirẹmi ninu idanwo naa.
Ajọ JAMB fidi rẹ mulẹ loju opo X rẹ pe mẹtadinlọgọjọ (157) ninu aadọrun-un le lẹẹgbẹrin din mẹta (887) ibi ti idanwọ ọhun ti waye ni aṣiṣe ti waye.
Ajọ naa sọ pe eyi gan lo ṣokunfa bi maaki ọpọ akẹkọọ ti ṣe idanwo lawọn ibikan ṣe lọọlẹ gan an.
NI bayii, gbogbo awọn akẹkọọ tọrọ kan ni ajọ JAMB yoo kan si lati tun idanwo naa ṣe laipẹ.
Lọjọ Aje to kọja ọjọ kejila oṣu Karun un yii ni ajọ JAMB kede pe awọn yoo ṣe agbeyẹwo esi idanwo UTME ọdún 2025 t'awọn gbe sita.















