Ìgbésẹ̀ márùn-ún rèé lórí bí o ṣe le è gbin ewébẹ̀ pẹ̀lú omi láì lo yèèpẹ̀

Àkọlé fídíò, Ìgbésẹ̀ márùn-ún rèé lórí bí o ṣe le è gbin ewébẹ̀ pẹ̀lú omi láì lo yèèpẹ̀
Ìgbésẹ̀ márùn-ún rèé lórí bí o ṣe le è gbin ewébẹ̀ pẹ̀lú omi láì lo yèèpẹ̀

Ewebẹ jẹ ohun to n se ara loore eyi ti ẹda kankan ko gbọdọ fi sere rara.

Amọ fun ọpọ eeyan kan, awọn ewebẹ bii ẹfọ, ewedu, efinrin, gbure ati ugwu ni owo wọn ti gbẹnu soke kọja agbara wọn.

Idi ree ti BBC Yoruba fi se akojọpọ iroyin akọnilẹkọ yii lori igbesẹ kọọkan ti o le gbe lati maa gbin àwọn ewebẹ yii funra rẹ ninu ile.

Koda, o ko nilo erupẹ lati gbin awọn ewebẹ naa, omi lasan ni o le fi gbin wọn, ti wọn yoo si dagba fun iwulo rẹ.

Ilana lilo omi lati fi gbin ewebẹ ni wọn n pe ni Hydroponics.

Lara awọn ẹfọ ti o le gbin pẹlu omi lasan ni efinrin, Gbure ati Ugwu.

Ẹfọ gbure

Oríṣun àwòrán, Twitter

Igbesẹ kọọkan lati gbin eso ati ewebẹ pẹlu omi lai lo yeepẹ

  • Mọ iru ewebẹ tabi eso ti o fẹ gbin, o le gbin Efinrin, Ugwu ati Gbure nitori wọn fẹran omi pupọ
  • Ge irugbin lati isalẹ pẹlu imọtoto, ge irugbin ewebẹ naa to to iwọn mẹrin si mẹfa
  • Fi irugbin naa sinu omi, lo igo tabi agolo to mọ lati gbe omi naa si
  • Gbongbo ewebẹ naa ni wa fi sinu omi, kii se ewe rẹ
  • Maa paarọ omi naa ni ẹẹmeji si ẹẹmẹta laarin ọsẹ kan.

Lobatan, o ti gbin ewebẹ rẹ laarin isẹju kan pere.