Wo ewu tó wà nínú wíwọ bàtà inú wọlé

Aworan ẹsẹ to n wọ bata wọle

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Imọtoto ṣe pataki pupọ fun ilera ẹda, ko si si ohun kan to yẹ ki eeyan fi oju fo lati ni ilera pipe.

Ọkan pataki lara ọna ti idọti ati ẹgbin le gba wọle si eeyan lara ni bi eeyan ba n wọ inu ile rẹ pẹlu bata lẹsẹ.

Awọn onimọ ilera sọ pe kokoro aifojuri to pọ to si lewu ni bata maa n ko sabẹ, bi eeyan ba si ṣe bẹẹ gbe e wọ ibugbe rẹ, aisan lo ko wọle yẹn.

Bi a ba wo awọn ibi ti a n gbe bata wọ bii baluwẹ, oju u popo, ile iwosan ati bẹẹ bẹẹ lọ, yoo ye wa pe ọpọ idọti ni bata wa n ko.

Gẹgẹ bi iwadii kan ti wọn ṣe ni Yunifasiti Arizona, l'America ṣe wi, ida mẹrindinlọgọrun-un (96%) bata ti a n wọ lo n ko kokoro bacteria kan ti a mọ si coliform, inu itọ ni coliform yii si ti n wa.

Ida mẹtadinlọgbọn (27%) bata wa n ko bacteria ti wọn n pe ni E. coli, eyi to maa n fa arun to buru jai fun ẹda eniyan.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹya E. coli kan lo le ṣe ara wa ni jamba, ẹya kan wa ti a mọ si Shiga, eyi to n fa ki eeyan maa ṣe igbọnsẹ gbuuru pẹlu ẹjẹ.

Eyi le fa aisan kan ti awọn dokita n pe ni 'hemolytic uremic syndrome.'

Aisan yii ni wọn lo n fa ki kindinrin da iṣẹ silẹ, ti yoo si pada ja si iku fun ẹni to ba kọlu.

Ṣugbọn ṣaa, ki I ṣe kokoro E. coli bacteria nikan lo le wa ninu ile latari bata ti a ba wọ wọle.

Kororo arun ti a mọ si 'Clostridium bacteria'', to n fa igbọnsẹ gbuuru ati aarẹ to lagbara naa maa n tẹle bata wọle.

Àwọn ọjọ́ orí wo ló wà nínú ewu táwọn èèyàn bá ń wọ bàtà wọ inú ilé?

Bata ti ki i jade rara kan leyi, inu ile ni wọn ti n wọ ọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bi alaye awọn oluwadii, awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko to ọdun marun-un, ni wọn wa labẹ ewu to le ṣelẹ ju, bi wọn ba n wọ bata wọ inu ile.

Eyi ri bẹẹ latari awọn ṣọja aronilagbara ara wọn ti ko ti i dagba to.

Idi miran ni pe wọn maa n saba ki ọwọ wọn si ẹnu lẹyin ti wọn ba ti fi gbe idọti lati ara bata tabi ibikibi.

Awọn ọmọde mi-in jẹ ọmọ ìrìnsẹ̀, awọn kan ṣi n rakoro, bẹẹ lawọn mi-in n ṣere ninu ọgba kiri.

Gbogbo ibi ti wọn n lọ lo ti ṣee ṣe ki wọn fi ẹsẹ ko idọti to le pada fa aisan si ara bi wọn ba ko idọti naa wọle lati ibi bata wọn.

Bi agbalagba pẹlu ba n wọ bata wọnu ile, ewu n bẹ fun ilera rẹ gẹgẹ bi alaye awọn oluwadii.

Ewu náà kò mọ níbi kòkòrò nìkan

Ewu ilera to wa ninu ki eeyan maa wọ bata wọle ko pin sibi kokoro bacteria nikan, gẹgẹ bi awọn oluwadii ṣe ṣalaye.

Wọn ni bata ti a ti wọ kiri maa n ko awọn kẹmika oloro sinu pẹlu.

Kokoro kan ti wọn n pe ni Plumbi virus, to maa n pọ ninu yẹpẹ tabi eruku nigboro, jẹ kokoro to le fa aisan ti yoo ṣe akoba fun ọpọlọ omọde.

Yoo ṣe akoba fun idagbasoke ọpọlọ ọmọ naa, yoo si di iṣoro titi lae ti ọmọ ko ni i le ṣẹgun.

Yatọ si eyi, awọn eruku kan le fẹ wa lati inu awọn ododo, wọn le lẹ mọ bata lara, wọn yoo si fa aile mi daadaa tabi irira nigba ti eeyan ba wa ninu ile.

Ohun to tun yẹ ko jẹ wa logun lati mọ ni pe awọn kẹmika kan wa lojuu popo ti a n rin ti wọn le fa kansa, bata yoo si fara ko o.

Iwadii kan ti wọn ṣe l'America, fi han pe awọn kẹmika yii le wọle lati ara bata, ki wọn si ṣe bẹẹ di eruku sinu ile.

Má wọ bàtà wọlé fún àlááfìa rẹ

Bibọ bata lẹsẹ ki o too wọle, jẹ ọkan lara ohun to kere ju ti o le ṣe lati da aabo bo ara rẹ ati ẹbi rẹ.

Ko si ṣoro lati ṣe eyi rara, ṣaa ti fi ọkan si i pe o ko ni i wọ bata wọle.

Bi o ba ti n ri i ṣe, ilera rẹ yoo maa lekun, gẹgẹ bi alaye awọn oluwadii.