Àwọn ẹ̀sùn tó wà nínú ìwé ẹjọ́ tí ìjọba àpapọ̀ pe Natasha Akpoti-Uduaghan

Natasha Akpoti-Uduaghan

Oríṣun àwòrán, Natasha Akpoti-Uduaghan

Àkọlé àwòrán, Ijọba apapọ sọ pe awọn ọrọ ti Sẹnetọ Akpoti-Uduaghan sọ, le tabuku ile aṣofin
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba apapọ ti pe sẹnetọ to n ṣoju aringbungbun ipinlẹ Kogi, Natasha Akpoti-Uduaghan lẹjọ, lori awọn ọrọ ibanilorukọjẹ kan ti wọn ni o sọ lori tẹlifiṣan.

Awọn ọrọ naa ni wọn lo sọ tako olori ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio ati gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, Yahaya Bello.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun un, ọdun 2025 ni ijọba pe ẹjọ naa ni ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja to si darukọ Natasha gẹgẹ bii olujẹjọ.

Ijọba sọ pe Natasha sọrọ to mọ pe o le ba orukọ eeyan jẹ eyii to lodi si abala 391ofin Naijiria ti ijiya rẹ wa ninu abala 392 ofin naa ti wọn gbe kalẹ lọdun 1990.

Awọn nnkan to wa ninu iwe ipẹjọ

Natasha Akpoti

Oríṣun àwòrán, Natasha Akpoti

Àkọlé àwòrán, Natasha Akpoti

Iwe ipẹjọ ọhun fi han pe lara awọn ti yoo jẹri ninu igbẹjọ naa ni olori ile igbimọ aṣofin, Naijiria, Godswil Akpabio ati gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, Yahaya Bello.

Lara nnkan to ṣokunfa ẹsun naa ni bi Akpoti-Uduaghan ṣe fẹsunkan Akpabio ati Yahaya Bello pe wọn fẹ gbẹmi oun.

Ijọba fẹsun kan obinrin ọhun pe o sọ lori ẹrọ amohunmoworan pe "O wa lara ọrọ ti wọn sọ nibi ipade naa, nibi ti Akpabio ati Yahaya Bello ti sọ lalẹ ọjọ naa pe o yẹ ki wọn pa mi".

Iwe ẹjọ Natasha

Oríṣun àwòrán, Ile ẹjọ giga Abuja

Àkọlé àwòrán, Iwe ẹjọ Natasha

"Ẹ jẹ ka bere lọwọ Aarẹ ile igbimọ aṣofin eredi to fi kọkọ yọ awọn ẹṣọ alaabo mi, ti kii ba ṣe pe o fẹ ki n wa lai si aabo kankan ki awọn kọlọrọsi le ri aye lati kọlu mi.

"Lẹyin naa lo ni ki wọn pa mi, amọ iku mi ọhun gbọdọ waye ni Kogi.

"Ohun to ṣe pataki si mi ni pe ki n wa laaye nitori ẹni to ku ko le ri aaye laati ma rojọ, ta ni yoo fun mi ni idajọ ododo?"

Ijọba apapọ sọ pe ọrọ naa ti Natasha sọ le ṣakoba, o si le ba orukọ olori ile igbimọ aṣofin jẹ ṣugbọn o tẹsiwaju lati sọ ọrọ naa.

Ninu ẹsun keji ti wọn fi kan Natasha, iwe ipẹjọ naa sọ pe "Iwọ aṣofin Natasha Akpoti-Uduaghan, lọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun 2025, lori ẹrọ tẹlefiṣọn Channels, sọ awọn ọrọ wọnyii tako gomina ana nipinlẹ Kogi tẹlẹ, Yahaya Adoza Bello pe."

Iwe ẹjọ Natasha

Oríṣun àwòrán, Ile ẹjọ giga Abuja

Àkọlé àwòrán, Iwe ẹjọ Natasha

"O wa lara ọrọ ti wọn sọ nibi ipade naa, nibi ti Akpabio ati Yahaya Bello ti sọ lalẹ ọjọ naa pe ki wọn pa mi. Nigba ti wọn pade, o sọ pe dandan ni ki wọn pa mi, amọ Kogi ni wọn ti gbọdọ pa mi.

"O mọ, o si gbagbọ pe awọn ọrọ naa le ba orukọ Yahaya Adoza Bello to jẹ gomina ana nipinlẹ Kogi, jẹ."

'Natasha sọ pe wọn lo ẹya ọmọbinrin kan ti wọn ji gbe fun iyawo Akpabio'

Ijọba apapọ tun fẹsun kan Natasha pe o fẹsun mii kan Akpabio ninu ifọrọwerọ ori foonu pẹlu obinrin kan, Sandra C. Duru, niluu Abuja nibi to ti sọ awọn ọrọ wọnyii.

"Ọmọ ti wọn pa yẹn, ki ni orukọ rẹ, uhhmm Imoren Iniobong, iyawo rẹ ni wọn lo ẹya ara ọdọbirin naa fun, nitori iyawo rẹ n ṣaisan… nigba ti wọn pa ọdọbinrin naa, iyawo rẹ ni wọn lo ẹya ara rẹ fun."

Iwe ẹjọ ọhun tẹsiwaju pe "O mọ, tun gbagbọ pe iru ọrọ yii le ṣakoba, o si le ba orukọ sẹnetọ Godswill Akpabio jẹ."

Wayi o, ile ẹjọ ko tii kede igba ti igbẹjọ naa yoo bẹrẹ ni pato.