Ṣé ẹ̀gbọ́n ọmọdékùnrin tí àṣìta ìbọn ṣekúpa ní Ibadan pàpà rí ìdánwò WAEC rẹ̀ ṣe?

Awọn aworan igba ti rogbodiyan to gba ẹmi Kehinde n waye lọwọ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Nigba ti aṣita ibọn ọlọpaa ba ọmọdekunrin kan, Kehinde Alade, ninu ọkọ ayọkẹlẹ baba rẹ nibẹrẹ ọsẹ yii, ohun ti gbogbo aye n wi ni pe ọmọ naa fẹẹ lọ ṣe idanwo oniwe mẹwaa ti a mọ si WAEC ni.

Iroyin to kari ni pe ki ọmọ naa ati awọn aburo rẹ ma baa pẹ ni baba wọn, Odunayo Alade, ṣe kọ lati duro fun awọn agbofinro to da ọkọ rẹ duro.

Ṣugbọn eyi ko ri bẹẹ.

Ninu ifọrọwerọ ti BBC ṣe fun Ọgbẹni Alade lo ti ni ki i ṣe Kehinde ti ibọn pa lo fẹẹ lọọ ṣedanwo oniwe mẹwaa, bi ko ṣe ẹgbọn rẹ toun naa wa ninu ọkọ pẹlu.

Ṣugbọn bi idaamu ba ba oju, o di dandan ko ba imu naa, baba ọmọ to doloogbe naa ṣalaye pe iku Kehinde ko jẹ ki ẹgbọn rẹ le ṣe idanwo ọhun mọ lọjọ naa.

Gẹgẹ bo ṣe wi: '' Awọn ibeji pẹlu ẹgbọn wọn to fẹẹ ṣedanwo WAEC la jọ wa ninu mọto lọjọ naa ti awọn agbofinro fi da wa duro.

''Ki i ṣe Kehinde ti ibọn ba lo fẹẹ ṣe idanwo, oun ati Taye rẹ pẹlu ẹgbọn wọn la kan jọ n lọ ni.

''Mi o tiẹ mọ pe ibọn ti ba Kehinde nigba ti wọn n pariwo Dadi, Dadi, mo ni ki wọn dakẹ, pe awọn agbofinro yẹn ti pada lẹyin wa.

''Igba ti Taye rẹ waa sọ pe wọn ti yinbọn ba Kehinde ni mo da ọkọ duro ti mo si gbe e jade.

''Idaamu ọjọ naa ko jẹ ki ẹgbọn rẹ to fẹẹ ṣedanwo gan-an ṣe e mọ. Mo padanu Kehinde, ọmọ mi to tun fẹẹ ṣe idanwo WAEC ko ri i ṣe.''

Oṣù Kọkànla ni Kehinde kò bá pe ọmọ ọdun mẹrinla, o sọ fun mi lọsẹ to kọja pe iṣẹ agbẹjọro loun yoo ṣe boun ba dagba

Ninu alaye baba to padanu ọkan ninu awọn ibeji rẹ yii, o ni oṣu Kọkanla ọdun yii ni Kehinde to ku ko ba pe ọmọ ọdun mẹrinla.

Ọgbẹni Alade tẹsiwaju pe ọsẹ to kọja yii ni ọmọ naa n sọ foun pe iṣẹ agbẹjọro loun yoo ṣe boun ba dagba.

O ni o bani lọkan jẹ gidi pe ọṣe to tẹle e ni iku da ẹmi rẹ legbodo latọwọ awọn agbofinro to n da ọkọ oun duro.

O fi kun un pe awọn agbofinro naa yoo fi tiwọn da oun duro boun ba da wọn lohun, ọmọ to si fẹẹ lọọ ṣedanwo laaarọ ọjọ naa yoo pẹ loun ko ṣe duro.

Ṣugbọn nigbẹyin naa, oun padanu Kehinde, ẹgbọn rẹ ko si tun ri idanwo ṣe.

''Ọdun keje ree ti mo ti n da awọn ọmọ yẹn tọ, iya wọn ti da wọn silẹ fun mi''

Ogbeni Alade Odunayo, Baba Oloogbe Kehinde Alade ti aṣita ibọn ọlọpaa pa n'Ibadan
Àkọlé àwòrán, Ogbeni Alade Odunayo, Baba Oloogbe Kehinde Alade ti aṣita ibọn ọlọpaa pa n'Ibadan
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, Baba Kehinde ṣalaye fun BBC pe iya to bi awọn ọmọ naa fun oun ti da wọn silẹ lati ọdun keje sẹyin.

Odunayo sọ pe latigba ti awọn ọmọ naa ṣi kere bẹẹ ni iya wọn ti lọ.

Lilọ rẹ ko ni koun fẹ iyawo miran gẹgẹ bo ṣe wi.

''Ohun ti mo maa n sọ ni pe ko si ọmọ ti obinrin kankan fẹẹ bi fun mi mọ ti yoo to awọn ti mo ti bi yii.

''Mo ni mi o le fẹyawo mi-in bayii, mo fẹẹ maa tọju awọn ọmọ mi ki obinrin mi-in ma baa fiya jẹ wọn.

''Ti mo ba fẹ ọja ọla rere fun wọn, iyawo kọ lo kan lọrọ mi.

''Lati ọdun keje ti iya wọn ti lọ, emi ni mo n tọju wọn funra mi. Mi o fẹyawo mi-in.''

Ki ni yoo waa ṣẹlẹ bayii ti ọkan ti ku lara awọn ọmọ naa, ati pe ki lohun to n fẹ lori iṣẹlẹ iku Kehinde.

Odunayo fesi pe iwadii ti yoo tanna si bawọn agbofinro ṣe yinbọn to si pa Kehinde loun fẹ.

O ni bi wọn ba ridii ọrọ naa, yoo gbegidina iru rẹ fun ẹlomi-in.

''Temi lo de ti a ri yii, a o mọ ti ẹni to n bọ lọla.

''Ti mo ba sọ pe mo fẹẹ gba ohunkohun, ko da ọmọ to ku pada. Ṣugbọn ki wọn ṣe iwadii to le dena iru eyi lọla, fun idajọ ododo''

Bẹẹ ni baba ọmọ to di oloogbe naa wi.

Tẹ o ba gbagbe, owurọ ọjọ Iṣẹgun, ogunjọ oṣu Karun-un ọdun 2025 yii ni iṣẹlẹ to gba ẹmi Kehinde Alade, waye niluu Ibadan.

Lasiko ti baba rẹ kọ lati duro fun awọn oṣiṣẹ OYRTMA to n ri si igbokegbodo ọkọ ni ọrọ bẹyin yọ.

Ọlọpaa kan yinbọn si taya ọkọ naa, eyi to gba ẹyin wọnu ọkọ to si pa Kehinde Alade lojuu Taye rẹ, ẹgbọn wọn agba ati baba wọn to n wa ọkọ ayọkẹlẹ to n gbe wọn lọ sileewe naa.