"Ariwo 'Daddy, Daddy lọmọ mi ń pa lẹ́yìn tí ìbọn bàá" Bàbá akẹ́kọ̀ọ́ tí ọlọ́pàá yìnbọn pa ní Ibadan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Aṣita ibọn lati ọwọ afurasi ọlọpa kan niluu Ibadan ni a gbọ pe o ti ṣeku pa paa odomokurin kan to jẹ akẹkọọ to n lọ ṣe idanwo aṣekagba ile ẹkọ girama, WAEC.
BBC Yoruba le fidi rẹ mulẹ wi pe iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Gbagi, wọn si gbe ọmọ naa losi ile iwosan WELFARE to wa ni agbegbe yii kan naa.
Baba ọmọdekunrin naa ti ọpọ ẹnu ti n kun lẹyin fidio kan to jade ti wa ba BBC sọrọ lori alaye ohun to ṣẹlẹ gan.









