Wo ọ̀nà tí o lè gbà jàǹfàní ẹ́bùn N5m látọ̀dọ̀ iléeṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Nàìjíríà lórí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó sá lọ l'Osun

Oríṣun àwòrán, NCoS
Ajọ to n mojuto akoso ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria, (NCoS) ti kede sita pe awọn ṣetan lati fun ẹnikẹni to ba le pese iroyin ati iranlọwọ ti yoo ṣokunfa mimu awọn ẹlẹwọn to ṣa kuro ni ọgba ẹwọn to wa niluu Ilesa nipinlẹ Osun.
Eyi jẹyọ ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ naa, Umar Abubakar fi lede fun awọn akọroyin. O ni iṣẹlẹ ọhun waye ni deede ago meji oru ni ọjọ Iṣẹgun lẹyin ojo nla to rọ mọjumọ, eleyi to ni o fa a bi Apa kan ogiri to yin Ọgba ẹwọn naa ṣe wo lulẹ.
Anfani yii ni awọn ẹlẹwọn naa lo lati ṣa kuro ni ọgba ẹwọn ọhun.
Ajọ NCoS ti wa kesi gbogbo araalu lati pese iranlọwọ lati le ṣawari awọn ẹlẹwọn naa, ti wọn si ṣeleri pe awọn yoo daabo bo irufẹ eeyan bẹ.
"Lati ṣe moriwu, Ajọ NCoS ṣetan lati fun ẹnikẹni to ba le pese iranlọwọ lori ẹlẹwọn yii ni milọnu marun un naira ," atẹjade naa ṣalaye.
Bakan naa ni ajọ fi awọn ẹrọ ibaraẹnisọrọ sita fun ẹnikẹni to ba fẹ pese iranlọwọ tabi iroyin nipa bi ti awọn ẹlẹwọn ọhun wa
Emails: [email protected], [email protected] (mailto:[email protected]).
Foonu nọmba: 07087086005, 09060004598, 08075050006
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
Ninu atẹjade ajọ ohun kọkọ fi lede ni wọn ti ṣalaye pe ojo to rọ naa fẹ atẹgun to lagbara.
Ni nnkan bii aago meji oru ti ojo ọhun n rọ lọwọ ni ogiri ọgba ẹwọn ọlọdun pipẹ naa wo lulẹ.
Eyi lo fun awọn ẹlẹwọn to juba ehoro ni anfaani lati ribi sa lọ gẹgẹ bi alaye awọn alabojuto ọgba ẹwọn Ilesa naa.















