'Mo gé ọwọ́ Hafsot pamọ́ láti fi ṣe aájò owó'

Abdulrahman atawọn afurasi yooku pẹlu aworan Hafsot Lawal

Oríṣun àwòrán, BBC/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lonii ni igbẹjọ Abdurahman Bello ati awọn mẹrin mii ti wọn n jẹjọ lori iku Hasfot Yetunde Lawal tun tẹsiwaju ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara.

Nnkan bii aago mẹsan-an owuro ni igbẹjọ naa eyi ti Adajọ Christiana Ajayi dari rẹ.

Lẹyin tawọn agbẹjọro ṣe ifarahan tan ni ẹlẹrii akọkọ, Isipẹtọ ọlọpaa, Ayodele Azeez lati ẹka ọtẹlẹmuyẹ ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara sọ pe lọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2025 ni wọn gbe ẹjọ ipaniyan ati ifipabanilopo ti wọn fi kan Abdulrahman Bello wa si ọfiisi awọn lati agọ ọlọpaa Ọja Ọba ilu Ilọrin.

O ni lara awọn ẹri ti wọn gbe siwaju awọn ni ọwọ meji, tabili, ada, aake, ẹrọ ibanisọrọ meji, ike ọda ati rọba ti wọn rọ ẹjẹ si.

Azeez sọ fun ile-ẹjọ pe, CP Abu Idris, SP Dansi Ẹniola ati ASP Dada Segun ni wọn gbe iṣe iwadii naa fun.

'Mo gé ọwọ́ Hafsot pamọ́ láti fi ṣe aájò owó'

O ṣalaye pe lasiko ti iwadii naa n lọ lọwọ ni oun mu Abdurahman Bello wọ yara iwadii ti oun si beere lọwọ rẹ pe ede wo lo gbọ daadaa to si ni ede oyinbo ni.

Lẹyin naa ni awọn wa agbẹjọro fun-un to si kọ gbogbo awọn akọsilẹ rẹ eyi to buwọlu funra rẹ lẹyin to ba agbẹjọro naa sọrọ.

Ẹlẹrii naa sọ fun ile-ẹjọ pe gbogbo ohun ti Abdurahman Bello sọ laagọ ọlọpaa ni awọn ka silẹ gẹgẹ bii ẹri.

O sọ pe lọjọ kejidinlogun, oṣu Keji, ni ikọ oluwadii lọ sile Abdurahman Bello ti wọn si ba yẹti to jẹ ti Hasfot Yetunde Lawal, bata, iwe oogun, pẹlu ẹrọ ibanisọrọ Hasfot Yetunde Lawal.

Inspector Azeez ṣagbekalẹ fọnran ọrọ ti wọn gba lẹnu Abdurahman Bello lasiko iwadii ti agbẹjọro ijọba to tun jẹ Kọmisanna feto idajọ, Senior Ibrahim rọ adajọ lati gba fọnran naa wọle gẹgẹ bi ẹri, adajọ si gba a wọle.

Lẹyin naa ni wọn ṣafihan fọnran ti wọn fi gba ohun ati aworan Abdurahman Bello kalẹ fun ile ẹjọ.

Ninu fọnran naa ti wọn ṣafihan nile ẹjọ, Abdurahman Bello sọ pe oun ati Hasfot Lawal pade lori ẹrọ ayelujara, tawọn si jọ n sọrọ lati fẹra awọn.

Àwọn èèyàn tó wà nínú ilé ẹjọ́
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"O ti pẹ ti Hasfot ti maa n ṣeleri fun mi pe oun maa wa ki mi nile.

O ni lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, Hasfot wa si ile oun, to si sọ pe ebi n pa oun bo ṣe de ti oun si lọ ra ounjẹ fun-un.

O sọ pe lẹyin to jẹun tan ni awọn lajọsepọ amọ to daku lẹyin ibalopọ naa.

"Nitori pe mi o le da oku rẹ gbe jade ni mo fi kun oku rẹ wẹlẹwẹlẹ, mo si ge ọwọ rẹ mejeeji lati fi ṣe aajo owo."

Azeez tun sọ fun ile-ẹjọ pe idi ti awọn ọlọpaa fi mu awọn mẹrin to ku ti wọn jọ n jẹjọ ni pe iwadii fi han pe wọn ni ibaṣepọ pẹlu Abdurahman ati pe awọn lo n pe e julọ lori ẹrọ ibanisọrọ.

Bakan naa lo ni awọn ko ba ohun to mu ifura dani nigba ti awọn de ile olujẹjọ keji nigba ti awọn lọ si ile rẹ.

Ẹlẹrii keji ni Hammed Ọlatayọ lati ileeṣẹ to n ri sọrọ iyanju aawọ ni ipinle Kwara.

Olatayo sọ fun ile-ẹjọ pe lọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2025 ni ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara pe oun si olu ile-iṣẹ wọn ni Ilọrin lati wa jẹ agbẹjọro fun Abdurahman Bello.

O ni oun buwọlu ọrọ ti Abdurahman kọ silẹ funra rẹ ti wọn si ṣagbekalẹ fọnran ibi to ti n buwọlu ọrọ naa ti Adajọ si gba a wọle gẹgẹ bi ẹri.

Ẹlẹrii kẹta ni Arabinrin Arẹmu Serah Kosemani to jẹ olukọ ni ile-ẹkọ Memorial College ni ilu Ilọrin. O ni olukọ ede Yoruba ni oun.

O ni lọjọ kẹfa, osu Karun-un, ni ileeṣẹ ọlọpaa pe oun lati wa tu ọrọ ti Abdurahman Bello sọ lede Gẹẹsi si Yoruba ti oun si tu u.

Agbẹjọro olujẹjọ sọ fun ile-ẹjọ pe ede Yoruba ni Arabinrin Arẹmu gbọ daadaa, pe o ṣeeṣe ko ṣe aṣiṣe lasiko to n tu ọrọ naa si Yoruba.

Lẹyin gbogbo atotonu naa ni adajọ sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa, ọdun 2025 fun itẹsiwaju igbẹjọ naa.