Àṣìta ìbọn ọlọ́pàá tó gbẹ̀mí akẹ́kọ̀ọ́ nílùú Ibadan, ohun tí ìjọba, ọlọ́pàá àtàwọn fídíò kan fihàn rèé

Ọmọ ti ọlọpaa ṣekupa niluu Ibadan

Oríṣun àwòrán, OYRTMA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lẹyin ti aṣita ibọn ọlọpaa ṣekupa akẹkọọ girama kan niluu Ibadan lọjọ Isegun, ọpọ awuyewuye lo ti tẹlẹ iṣẹle naa.

Bi awọn araalu kan ṣe n bu ẹnu atẹ lu ọlọpaa to ṣina ibọn mọ ọmọ naa, lawọn araalu mii n bu ẹnu atẹ lu baba ọmọ ọhun fura rẹ.

Amọ oniruru iroyin lo ti gbode kan nipa ohun to ṣẹlẹ nipa ohun ṣẹlẹ patọ, awọn iroyin kan ni ori ọkada ni ọmọ naa wa nigba ti ibọn ọlọpaa to n le ọmọ Yahoo ba a, ṣe ootọ ni?

Ohun ti a mọ nipa iṣẹlẹ naa ree

Gẹgẹ bi fidio ti oṣiṣe ajọ OYRTMA ṣe ti a foju ri, ọkọ Honda dudu kan ti gilaasi rẹ tun dudu ni baba ọmọ naa n wa.

Fidio ọhun ṣafihan bi awọn oṣiṣẹ OYRTMA ṣe n le ọkunrin awakọ ọkọ naa, Odunayo Alade, ti oun naa si n gbiyanju lati salọ.

Awọn oṣiṣẹ naa n gbiyaju lati ṣi ilẹkun ọkọ rẹ amọ ọkunrin naa kọ lati duro.

Ninu igbiyanju rẹ lati salọ lo ti n fi ọkọ naa kọlu ọkọ ijọba niwaju ati lẹgbẹ rẹ ti awọn oṣiṣẹ OYRTMA si n pariwo pe "awọn ọmọde wa ninu mọto yi o."

Lẹyinorẹyin, ọkan lara awọn ọlọpaa to wa nibẹ ṣina ibọn fun ọkọ Honda ọhun, ti ibọn naa si ba ọkan ninu awọn ọmode to wa ninu rẹ.

Gẹgẹ bii fidio ti a ri, lẹyin eyii ni ọkunrin naa duro, to si di ṣokoto ọlọpaa to gbagbọ pe o yinbọn naa mu pe ko ni lọ.

Bo ṣe n ṣe eyii lọwọ lawọn eeyan to wa nibẹ n du ọmọ naa ko ma baa ku bo tilẹ jẹ pe o ti n padanu ẹjẹ.

Taya ni ọlọpaa fẹ yinbọn lu ko to lọ ba oloogbe - Ọlọpaa

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti kede pe awọn ti mu oṣiṣẹ awọn to yinbọn to ṣekupa oloogbe naa, Kehinde Alade.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Osifeso Adewale sọ ninu atẹjade kan pe oju ọna 'one way' ni baba oloogbe naa gba ti awọn si fẹ mu pe o ru ofin irinna oju popo amọ o gbiyanju lati salọ to si n kọlu oniruru ọkọ ninu igbiyanj u rẹ ọhun.

Ọlọpaa ni "Nibga ti a wo bi awakọ naa ṣe n ṣe, awọn ọlọpaa funra pe o le jẹ ọdaran to ji eeyan gbe, wọn bẹrẹ si ni le.

"Lọna ati da ọkọ naa duro, ọkan lara awọn ọlọpaa yinbọn si taya rẹ amọ o ṣeni laanu pe ibọn naa ba Kehinde Alade, to joko si aga to wa lẹyin awakọ naa."

Atẹjade naa fikun pe ọlọpaa to yinbọn ọhun atawọn ti wọn jọjọ wa papọ ti wa ni ahamọ fun iwadii kikun lori iṣẹlẹ ọhun.

Iwadii to peye yoo waye, idajọ ododo yoo si tẹle – ijọba ipinlẹ Oyo

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ ti sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ eyii to gba omi loju ẹni.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ijọba Oyo, Sulaimon Olanrewaju, fi lede, o ni ko yẹ ki iṣẹlẹ ọhun waye rara.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọrọ naa bẹrẹ pẹlu riru ofin irinna oju popo ko to di ohun ti ẹmi akẹkọọ n lọ si.

Olanrewaju ni ijọba Oyo yoo fọwọsowọpọ pẹlu ọlọpaa fun iwadii kikun ki gbogbo awọn to ba jẹbi ọrọ naa le foju wina ofin.

Ijọba Oyo fikun pe iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin to ni ọmọ Yahoo ni ọlọpaa n le ko to yinbọ lu ọmọ ilẹ ẹkọ to jade laye.

Olanrewaju pari ọrọ rẹ pẹlu ileri pe iwadii kikun yoo waye lori iṣẹlẹ naa.

O fikun pe ki gbogbo araalu lọ fi ọkan wọn balẹ ki wọn si maa reti esi iwadii ọhun.

Àṣìta ìbọn 'ọlọ́pàá' ṣekú pa akẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣèdánwò WAEC n'Ibadan, àwọn olùfẹ̀hónúhàn gbé òkú rẹ̀ lọ ọ́fíìsì Makinde

Aworan ọmọ ti aṣita ibọn pa n'Ibadan

Aṣita ibọn lati ọwọ afurasi ọlọpa kan niluu Ibadan ni a gbọ pe o ti ṣeku pa paa odomokurin kan to jẹ akẹkọọ to n lọ ṣe idanwo aṣekagba ile ẹkọ girama, WAEC, lonii ogunjọ oṣu Karun un ọdun yii'

Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, nigba ti awọn ọlọpaa n le awọn ọdaran kan lọ ni wọn yinbon ti ọta ibọn naa si ba ọmọdekunrin yii nibi to ti n lọ fun idanwo rẹ.

BBC Yoruba le fidi rẹ mulẹ wi pe iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Gbagi, wọn si gbe ọmọ naa losi ile iwosan WELFARE to wa ni agbegbe yii kan naa.

Amọ awọn dokita ile iwosan ọhun lo fidi rẹ mulẹ wi pe omo naa ti jade laye.

Ọmọkunrin ni a gbọ pe o lọ wa ninu ọkọ ayọkele Honda EOD pẹlu baba rẹ ati ikeji rẹ ko to o sagbako iku ojiji yii.

Iṣẹlẹ yii lo bi awọn ọdọ agbegbe naa ninu ti wọn si gbe oku ọmọ naa lọ si ile iṣe ijọba ipinlẹ Oyo to wa ni Agodi niluu Ibadan ti wọn si n fi ehonu wọn han latari iṣẹlẹ naa .

Iṣẹlẹ naa ni o bi awọn eniyan ninu ti wọn si n rọ gomina Ipinlẹ Oyo Seyi Makinde lati tu iṣu de isalẹ koko lori ọrọ naa ki oṣiṣẹ ile iṣe ọlọpa to yinbọn naa si fi oju baa ile ẹjọ.

Lara awọn to sọrọ lori iṣẹlẹ naa sọ pe awọn oṣiṣẹ ile iṣe ọlọpaa to yinbọn naa ko ni ibẹru Ọlọrun.

Bakan naa ni wọn rọ ọga agba ile iṣe ọlọpaa lati ṣewadii iṣẹlẹ ọhun.

Ile iṣe ọlọpaa Ipinlẹ Oyo ko tii sọrọ lori iṣẹlẹ yii titi di asiko ti a ko iroyin yii jọ.